Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 73

ÌWÉ KẸTA

Saamu 73–89

Saamu ti Asafu.

73 Nítòótọ́ Ọlọ́run dára fún Israẹli,
    fún àwọn ọlọ́kàn funfun.

Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi, ẹsẹ̀ mi ti yẹ̀ tán;
    ìrìn mi fẹ́rẹ̀ yọ̀ tán.
Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣe féfé
    nígbà tí mo bá rí àlàáfíà àwọn ènìyàn búburú.

Wọn kò ṣe wàhálà;
    ara wọn mókun wọn sì lágbára.
Wọn kò ní ìpín nínú àjàgà tó ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn;
    a kò pọ́n wọn lójú nípa ẹlòmíràn.
Ìgbéraga ni ọ̀ṣọ́ ọrùn wọn;
    ìwà ipá bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí aṣọ.
Láti inú ọkàn àrékérekè ni àìṣòdodo ti wá;
    ẹ̀rí ọkàn búburú wọn kò ní òdínwọ̀n
Wọn ń ṣẹ̀sín, wọn sì ń sọ̀rọ̀-òdì ní ti
    ìnilára, wọ́n ń sọ̀rọ̀ láti ibi gíga.
Wọ́n ń gbé ẹ̀mí wọn lé ọ̀run
    ahọ́n wọn gba ipò ayé.
10 Nítorí náà àwọn ènìyàn wọn yípadà sí wọn
    wọ́n sì mu omi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
11 Wọ́n wí pé, “Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe mọ̀?
    Ọ̀gá-ògo ha ní ìmọ̀ bí?”

12 Bí àwọn ènìyàn búburú ṣe rí nìyí
    ènìyàn asán, wọ́n ń pọ̀ ní ọrọ̀.

13 Nítòótọ́ nínú asán ni mo pa ọkàn mi mọ́;
    nínú asán ni mo wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀.
14 Ní gbogbo ọjọ́ ni a ń yọ mí lẹ́nu;
    a sì ń jẹ mí ní yà ní gbogbo òwúrọ̀.

15 Bí mo bá wí pé, “Èmi ó wí báyìí,”
    Èmi ó ṣẹ̀ sí ìran àwọn ọmọ rẹ̀.
16 Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí,
    Ó jẹ́ ìnilára fún mi.
17 Títí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run;
    Nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi.

18 Lóòtítọ́ ìwọ gbé wọn lórí ilẹ̀ yíyọ́
    ìwọ jù wọ́n sílẹ̀ sínú ìparun.
19 Báwo ní a ti mú wọn lọ sínú ìdahoro yìí
    bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan!
Ìbẹ̀rù ni a fi ń run wọ́n pátápátá!
20 Bí àlá nígbà tí ènìyàn bá jí,
    bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí ìwọ bá dìde, Olúwa,
    ìwọ yóò ṣe àbùkù àwòrán wọn.

21 Nígbà tí inú mi bàjẹ́
    àti ọkàn mi ṣì korò,
22 Mo jẹ́ aṣiwèrè àti aláìlóye;
    mo jẹ́ ẹranko ní iwájú rẹ.

23 Síbẹ̀ mo wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo;
    ìwọ di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.
24 Ìwọ fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi
    ní ìkẹyìn ìwọ ó mú mi lọ sí inú ògo
25 Ta ni mo ní ní ọ̀run, bí kò ṣe ìwọ?
    Àti ní ayé kò sí ohun tí mo fẹ́ lẹ́yìn rẹ.
26 Ara mi àti ọkàn mi le è kùnà
    ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni agbára ẹ̀mí mi
    àti ìpín mi títí láé.

27 Àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóò ṣègbé
    ìwọ ti pa gbogbo wọn run;
tí ń ṣe àgbèrè kiri kúrò lọ́dọ̀ rẹ
28 Ṣùgbọ́n ní ti èmi, ó dára láti súnmọ́ Ọlọ́run
    Èmi ti fi Olúwa Olódùmarè ṣe ààbò mi;
    Kí èmi ó lè máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ.

Jona 3

Jona lọ si Ninefe

Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jona wá nígbà kejì wí pé: “Dìde lọ sí Ninefe, ìlú ńlá a nì, kí o sì kéde sí i, ìkéde tí mo sọ fún ọ.”

Jona sì dìde ó lọ sí Ninefe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa. Ninefe jẹ́ ìlú títóbi gidigidi, ó tó ìrìn ọjọ́ mẹ́ta. Jona sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ ìlú náà lọ ní ìrìn ọjọ́ kan, ó sì ń kéde, ó sì wí pé, “Níwọ́n ogójì ọjọ́ sí i, a ó bi Ninefe wó.” Àwọn ènìyàn Ninefe sì gba Ọlọ́run gbọ́. Wọ́n sì kéde àwẹ̀, gbogbo wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, bẹ̀rẹ̀ láti orí ọmọdé títí dé orí àgbà wọn.

Ọ̀rọ̀ náà sì dé ọ̀dọ̀ ọba Ninefe, ó sì dìde kúrò lórí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì bọ́ aṣọ ìgúnwà rẹ̀ kúrò lára rẹ̀, ó sì da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, ó sì jókòó nínú eérú. Nígbà náà ní ó kéde rẹ̀ ni Ninefe pé:

“Kí a la Ninefe já nípa àṣẹ ọba, àti àwọn àgbàgbà rẹ̀ pé:

“Má ṣe jẹ́ kí ènìyàn, tàbí ẹranko, ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo ẹran, tọ́ ohunkóhun wò: má jẹ́ kí wọn jẹ tàbí mu omi. Ṣùgbọ́n jẹ́ kí ènìyàn àti ẹranko da aṣọ ọ̀fọ̀ bo ara, kí wọn sì kígbe kíkan sí Ọlọ́run, sì jẹ́ kí wọn yípadà, olúkúlùkù kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀ àti kúrò ní ìwà ìpa tí ó wà lọ́wọ́ wọn. (A)Ta ni ó lè mọ̀ bí Ọlọ́run yóò yípadà kí ó sì ronúpìwàdà, kí ó sì yípadà kúrò ní ìbínú gbígbóná rẹ̀, kí àwa má ṣègbé?”

10 Ọlọ́run sì rí ìṣe wọn pé wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀nà ibi wọn: Ọlọ́run sì ronúpìwàdà ibi tí òun ti wí pé òun yóò ṣe sí wọn, òun kò sì ṣe e mọ́.

2 Peteru 3:8-13

(A)Ṣùgbọ́n, olùfẹ́, ẹ má ṣe gbàgbé ohun kan yìí, pé ọjọ́ kan lọ́dọ̀ Olúwa bí ẹgbẹ̀rún ọdún ni ó rí, àti ẹgbẹ̀rún ọdún bí ọjọ́ kan. Olúwa kò fi ìlérí rẹ̀ jáfara, bí àwọn ẹlòmíràn ti ka ìjáfara sí; ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣègbé, bí kò ṣe kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.

10 Ṣùgbọ́n ọjọ́ Olúwa ń bọ̀ wá bí olè ní òru; nínú èyí tí àwọn ọ̀run yóò kọjá lọ pẹ̀lú ariwo ńlá, àti àwọn ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run yóò sì ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́, ayé àti àwọn iṣẹ́ tí ó wà nínú rẹ̀ yóò sì jóná túútúú.

11 Ǹjẹ́ bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti yọ́ bẹ́ẹ̀, irú ènìyàn wo ni ẹ̀yin ìbá jẹ́ nínú ìwà mímọ́ gbogbo àti ìwà-bí-Ọlọ́run. 12 (B)Kí ẹ máa retí, kí ẹ sì máa múra gírí de dídé ọjọ́ Ọlọ́run, nítorí èyí tí àwọn ọ̀run yóò gbiná, tí wọn yóò di yíyọ́, tí àwọn ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ yóò sì ti inú ooru gbígbóná gidigidi di yíyọ́. 13 (C)Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀, àwa ń retí àwọn ọ̀run tuntun àti ayé títún nínú èyí tí òdodo ń gbé.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.