Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Nígbà ti wòlíì Natani tọ wá, lẹ́yìn tí Dafidi dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè rẹ̀ pẹ̀lú Batṣeba.
51 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí
ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ̀,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀
kí o sì pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ́.
2 Wẹ gbogbo àìṣedéédéé mi nù kúrò
kí o sì wẹ̀ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi!
3 Nítorí mo mọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi,
nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi wà níwájú mi.
4 (A)Sí ọ, ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí
ni mo sì ṣe búburú níwájú rẹ̀,
kí a lè dá ọ láre nígbà tí ìwọ bá ń sọ̀rọ̀,
kí o sì le wà láìlẹ́bi, nígbà tí ìwọ bá ń ṣe ìdájọ́.
5 Nítòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi,
nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi.
6 Nítòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú;
ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀kọ̀.
7 Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé hísópù, èmi yóò sì mọ́;
fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju yìnyín lọ.
8 Jẹ́ kí n gbọ́ ayọ̀ àti inú dídùn;
jẹ́ kí gbogbo egungun tí ìwọ ti run kí ó máa yọ̀.
9 Pa ojú rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi
kí o sì pa gbogbo àwọn àìṣedéédéé mi rẹ́.
10 Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run,
kí o sì tún ẹ̀mí dídúró ṣinṣin ṣe sínú mi.
Ìkún omi
6 (A)Nígbà tí ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ní pọ̀ si ní orí ilẹ̀, wọ́n sí bí àwọn ọmọbìnrin. 2 Àwọn ọmọ Ọlọ́run rí i wí pé àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lẹ́wà, wọ́n sì fẹ́ èyíkéyìí tí ó wù wọ́n ṣe aya. 3 Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Èémí ìyè tí mo mí sínú ènìyàn kò ní máa gbé inú ènìyàn títí láé, nítorí ẹran-ara sá à ni òun, ọgọ́fà ọdún ni ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́.”
4 (B)Àwọn òmíràn wà láyé ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àti lẹ́yìn ìgbà náà; nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run lọ bá àwọn ọmọbìnrin ènìyàn lòpọ̀ tí wọ́n sì bímọ fún wọn. Àwọn náà ni ó di akọni àti olókìkí ìgbà náà.
5 Olúwa sì rí bí ìwà búburú ènìyàn ti ń gbilẹ̀ si, àti pé gbogbo èrò inú rẹ̀ kìkì ibi ni, ní ìgbà gbogbo. 6 Inú Olúwa sì bàjẹ́ gidigidi nítorí pé ó dá ènìyàn sí ayé, ọkàn rẹ̀ sì gbọgbẹ́.
1 Paulu, aposteli Kristi Jesu gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Ọlọ́run Olùgbàlà wa, àti Jesu Kristi ìrètí wa.
2 Sí Timotiu ọmọ mi nínú ìgbàgbọ́:
Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Jesu Kristi Olúwa wa.
Ìkìlọ̀ lòdì sí olùkọ́ni èké ti òfin
3 Bí mo ṣe rọ̀ yìn nígbà tí mò ń lọ sí Makedonia, ẹ dúró ní Efesu, kí ẹ lè dá àwọn ènìyàn kan lẹ́kun láti má ṣe kọ́ ni ní ẹ̀kọ́ èké mọ́ 4 kí wọ́n má sì ṣe fiyèsí àwọn ìtàn asán, àti ìtàn ìran aláìlópin. Irú èyí máa ń mú iyàn jíjà wá dípò iṣẹ́ ìríjú Ọlọ́run èyí tí í ṣe ti ìgbàgbọ́. 5 Ète àṣẹ náà ni ìfẹ́ ti ń jáde wá láti inú ọkàn mímọ́ àti ẹ̀rí ọkàn rere àti ìgbàgbọ́ àìṣẹ̀tàn. 6 Àwọn ẹlòmíràn ti yapa kúrò tí wọ́n sì yà sápá kan sí ọ̀rọ̀ asán. 7 Wọ́n ń fẹ́ ṣe olùkọ́ òfin; òye ohun tí wọ́n ń wí kò yé wọn tàbí ti ohun tí wọ́n ń fi ìgboyà tẹnumọ́.
8 Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé òfin dára, bí ènìyàn bá lò ó dáradára. 9 Bí a ti mọ̀ pé, a kò ṣe òfin fún olódodo, bí kò ṣe fún àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, fún àwọn aláìmọ́ àti àwọn ẹlẹ́gàn, fún àwọn tí ń pa baba àti àwọn tí ń pa ìyá wọn àti àwọn apànìyàn, 10 fún àwọn àgbèrè, fún àwọn aláyídà, fún àwọn onísòwò-ẹrú, fún àwọn èké, fún àwọn abúra èké, àti bí ohun mìíràn bá wà tí ó lòdì sí ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro. 11 Gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere ti ògo Ọlọ́run olùbùkún, tí a fi sí ìtọ́jú mi.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.