Revised Common Lectionary (Complementary)
23 “Ǹjẹ́ Ọlọ́run tòsí nìkan ni Èmi bí?”
ni Olúwa wí,
“kì í sì í ṣe Ọlọ́run ọ̀nà jíjìn.
24 Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni lè sápamọ́ sí ibi kọ́lọ́fín kan,
kí èmi má ba a rí?”
ni Olúwa wí.
“Ǹjẹ́ èmi kò ha a kún ọ̀run àti ayé bí?”
ni Olúwa wí.
25 “Mo ti gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn wòlíì èké tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ mi ń sọ. Wọ́n sọ wí pé, ‘Mo lá àlá! Mo lá àlá!’ 26 Títí di ìgbà wo ni èyí yóò fi máa tẹ̀síwájú ni ọkàn àwọn wòlíì èké wọ̀nyí tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìtànjẹ ọkàn wọn? 27 Wọ́n rò wí pé àlá tí wọ́n ń sọ fún ara wọn yóò mú kí àwọn ènìyàn mi gbàgbé orúkọ mi, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ṣe gbàgbé orúkọ mi nípa sí sin òrìṣà Baali. 28 Jẹ́ kí wòlíì tí ó bá lá àlá sọ àlá rẹ̀, ṣùgbọ́n jẹ́ kí ẹni tí ó ní ọ̀rọ̀ mí sọ ọ́ ní òtítọ́. Kí ni koríko gbígbẹ ní í ṣe nínú ọkà?” ni Olúwa wí. 29 “Ọ̀rọ̀ mi kò ha a dàbí iná?” ni Olúwa wí, “àti bí òòlù irin tí ń fọ́ àpáta túútúú?
Saamu ti Asafu.
82 Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá,
ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn “ọlọ́run òrìṣà”.
2 “Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa gbèjà àwọn aláìṣòdodo
kí ó sì ṣe ojú ìṣáájú sí àwọn ènìyàn búburú?
3 Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba;
ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára.
4 Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní;
gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú.
5 “Wọn kò mọ̀ ohun kankan,
wọn kò lóye ohun kankan.
Wọn ń rìn kiri nínú òkùnkùn;
à si mí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé.
6 (A)“Mo wí pé, ‘Ẹyin ní “Ọlọ́run òrìṣà”;
ẹ̀yin ní gbogbo ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ.’
7 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ó kú bí ènìyàn lásán;
ẹ̀yin ó ṣubú bí ọ̀kan nínú ọmọ-aládé.”
8 Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ayé,
nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè ni ìní rẹ.
29 (A)Nípa ìgbàgbọ́ ni wọn la Òkun pupa kọjá bi ẹni pé ni ìyàngbẹ ilẹ̀: ti àwọn ara Ejibiti dánwò, tí wọ́n sì ri.
30 (B)Nípa ìgbàgbọ́ ni àwọn odi Jeriko wo lulẹ̀, lẹ́yìn ìgbà tí a yí wọn ká ni ọjọ́ méje.
31 (C)Nípa ìgbàgbọ́ ni Rahabu panṣágà kò ṣègbé pẹ̀lú àwọn tí kò gbọ́rọ̀ nígbà tí o tẹ́wọ́gbà àwọn ààmì ní àlàáfíà.
32 (D)Èwo ni èmi o sì tún máa wí sí i? Nítorí pé ìgbà yóò kùnà fún mi láti sọ ti Gideoni, àti Baraki, àti Samsoni, àti Jefta; àti Dafidi, àti Samuẹli, àti ti àwọn wòlíì: 33 (E)Àwọn ẹni nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ tiwọn ṣẹ́gun ilẹ̀ ọba, tí wọn ṣiṣẹ́ òdodo, tiwọn gba ìlérí, tiwọn dí àwọn kìnnìún lénu, 34 (F)Tí wọ́n pa agbára iná, tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ojú idà, tí a sọ di alágbára nínú àìlera, tí wọ́n dí akọni nínú ìjà, wọ́n lé ogun àwọn àjèjì sá. 35 (G)Àwọn obìnrin ri òkú wọn gbà nípa àjíǹde: a sì da àwọn ẹlòmíràn lóró, wọ́n kọ̀ láti gba ìdásílẹ̀; kí wọn ba lè rí àjíǹde tí o dára jù gbà; 36 Àwọn ẹlòmíràn sì rí ìjìyà ẹ̀sín, àti nínà, àti ju bẹ́ẹ̀ lọ, ti ìdè àti ti túbú: 37 A sọ wọ́n ni òkúta, a fi ayùn rẹ́ wọn sì méjì, a dán wọn wò a fi idà pa wọn: wọ́n rìn káàkiri nínú awọ àgùntàn àti nínú awọ ewúrẹ́; wọn di aláìní, olùpọ́njú, ẹni tí a ń da lóró; 38 Àwọn ẹni tí ayé ko yẹ fún: Wọ́n ń kiri nínú aṣálẹ̀, àti lórí òkè, àti nínú ihò àti nínú abẹ́ ilẹ̀.
39 Gbogbo àwọn wọ̀nyí tí a jẹ́rìí rere sí nípa ìgbàgbọ́, wọn kò sì rí ìlérí náà gbà: 40 Nítorí Ọlọ́run ti pèsè ohun tí ó dára jù sílẹ̀ fún wa, pé láìsí wa, kí a má ṣe wọn pé.
Ìbáwí àwọn ọmọ Ọlọ́run
12 Nítorí náà bí a ti fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ tí o kún fún àwọn ẹlẹ́rìí tó báyìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tì sí apá kan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí o rọrùn láti di mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa, 2 (H)Kí a máa wo Jesu Olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa; ẹni nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ, tí o faradà àgbélébùú láìka ìtìjú sí, tí ó sì jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.
Àlàáfíà kọ́ ṣùgbọ́n ìyapa
49 (A)“Iná ni èmi wá láti sọ sí ayé; kín ni èmi sì ń fẹ́ bí kò ṣe kí iná náà ti jo! 50 (B)Ṣùgbọ́n èmi ní bamitiisi kan tí a ó fi bamitiisi mi; ara ti ń ni mí tó títí yóò fi parí! 51 (C)Ẹ̀yin ṣe bí àlàáfíà ni èmi fi sí ayé? Mo wí fún yín, bẹ́ẹ̀ kọ́; ṣùgbọ́n bí kò ṣe ìyapa. 52 Nítorí láti ìsinsin yìí lọ, ènìyàn márùn-ún yóò wà ní ilé kan náà tí a ó yà ní ipa, mẹ́ta sí méjì, àti méjì sí mẹ́ta. 53 A ó ya baba nípa sí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, àti ọmọ ọkùnrin sí baba; ìyá sí ọmọbìnrin, àti ọmọbìnrin sí ìyá rẹ̀, ìyá ọkọ sí ìyàwó ọmọ, àti ìyàwó ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀.”
Ògbufọ̀ àwọn àkókò
54 (D)Ó sì wí fún ìjọ ènìyàn pẹ̀lú pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá rí àwọsánmọ̀ tí ó ṣú ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, lọ́gán ni ẹ̀yin yóò sọ pé, ‘Ọ̀wààrà òjò ń bọ̀,’ a sì rí bẹ́ẹ̀. 55 Nígbà tí afẹ́fẹ́ gúúsù bá ń fẹ́, ẹ̀yin á ní, ‘Oòrùn yóò mú,’ yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀. 56 Ẹ̀yin àgàbàgebè! Ẹ̀yin le mòye ojú ọ̀run àti ti ayé. Èéha ti ṣe tí ẹ̀yin kò mọ àkókò yìí?
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.