Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 82

Saamu ti Asafu.

82 Ọlọ́run ń ṣàkóso nínú ìpéjọpọ̀ ńlá,
    ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn “ọlọ́run òrìṣà”.

“Yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa gbèjà àwọn aláìṣòdodo
    kí ó sì ṣe ojú ìṣáájú sí àwọn ènìyàn búburú?
Gbèjà àwọn aláìlágbára àti aláìní baba;
    ṣe ìtọ́jú ẹ̀tọ́ àwọn aláìní àti ẹni ìnilára.
Gba àwọn aláìlágbára àti aláìní;
    gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú.

“Wọn kò mọ̀ ohun kankan,
    wọn kò lóye ohun kankan.
Wọn ń rìn kiri nínú òkùnkùn;
    à si mí gbogbo ìpìlẹ̀ ayé.

(A)“Mo wí pé, ‘Ẹyin ní “Ọlọ́run òrìṣà”;
    ẹ̀yin ní gbogbo ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ.’
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ó kú bí ènìyàn lásán;
    ẹ̀yin ó ṣubú bí ọ̀kan nínú ọmọ-aládé.”

Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ayé,
    nítorí gbogbo orílẹ̀-èdè ni ìní rẹ.

Joṣua 7:1

Ẹ̀ṣẹ̀ Akani

Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàsọ́tọ̀, Akani ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera, ẹ̀yà Juda, mú nínú wọn. Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú Olúwa ru sí àwọn ará Israẹli.

Joṣua 7:10-26

10 Olúwa sì sọ fún Joṣua pé, “Dìde! Kín ni ìwọ ń ṣe tí ó fi dojúbolẹ̀? 11 Israẹli ti ṣẹ̀; Wọ́n sì ti ba májẹ̀mú mi jẹ́, èyí tí mo pàṣẹ fún wọn pé kí wọn pamọ́. Wọ́n ti mú nínú ohun ìyàsọ́tọ̀, wọ́n ti jí, wọ́n pa irọ́, Wọ́n ti fi wọ́n sí ara ohun ìní wọn. 12 Ìdí nì èyí tí àwọn ará Israẹli kò fi lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá wọn; wọ́n yí ẹ̀yìn wọn padà, wọ́n sì sálọ níwájú ọ̀tá a wọn nítorí pé àwọn gan an ti di ẹni ìparun. Èmi kì yóò wà pẹ̀lú u yín mọ́, bí kò ṣe pé ẹ̀yin pa ohun ìyàsọ́tọ̀ run kúrò ní àárín yín.

13 “Lọ, ya àwọn ènìyàn náà sí mímọ́. Sọ fún wọn pé, ‘Ẹ ya ara yín sí mímọ́ fún ọ̀la, nítorí báyìí ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli wí: Ohun ìyàsọ́tọ̀ kan ń bẹ ní àárín yín, Israẹli. Ẹ̀yin kì yóò lè dúró níwájú àwọn ọ̀tá a yín títí ẹ̀yin yóò fi mú kúrò.

14 “ ‘Ní òwúrọ̀, kí ẹ mú ará yín wá síwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Ẹ̀yà tí Olúwa bá mú yóò wá sí iwájú ní agbo ilé kọ̀ọ̀kan, agbo ilé tí Olúwa bá mú yóò wá sí iwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, ìdílé tí Olúwa bá sì mú yóò wá sí iwájú ní ẹni kọ̀ọ̀kan. 15 Ẹnikẹ́ni tí a bá ká mọ́ pẹ̀lú ohun ìyàsọ́tọ̀ náà, a ó fi iná pa á run, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní. Ó ti ba májẹ̀mú Olúwa jẹ́, ó sì ti ṣe nǹkan ìtìjú ní Israẹli!’ ”

16 Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Joṣua mú Israẹli wá síwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, a sì mú ẹ̀yà Juda. 17 Àwọn agbo ilé e Juda wá sí iwájú, ó sì mú agbo ilé Sera. Ó sì mú agbo ilé Sera wá síwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, a sì mú ìdílé Sabdi. 18 Joṣua sì mú ìdílé Simri wá síwájú ní ọkùnrin kọ̀ọ̀kan, a sì mú Akani ọmọ Karmi, ọmọ Sabdi, ọmọ Sera ti ẹ̀yà Juda.

19 Nígbà náà ní Joṣua sọ fún Akani pé, “Ọmọ mi fi ògo fún Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, kí o sì fi ìyìn fún un. Sọ fún mi ohun tí ìwọ ti ṣe, má ṣe fi pamọ́ fún mi.”

20 Akani sì dáhùn pé, “Òtítọ́ ni! Mo ti ṣẹ̀ sí Olúwa, Ọlọ́run Israẹli. Nǹkan tí mo ṣe nìyìí: 21 Nígbà tí mo rí ẹ̀wù Babeli kan tí ó dára nínú ìkógun, àti igba ṣékélì fàdákà àti odindi wúrà olóṣùnwọ́n àádọ́ta ṣékélì, mo ṣe ojúkòkòrò wọn mo sì mú wọn. Mo fi wọ́n pamọ́ ní abẹ́ àgọ́ mi àti fàdákà ní abẹ́ rẹ̀.”

22 Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ran àwọn òjíṣẹ́, wọ́n sì sáré wọ inú àgọ́ náà, ó sì wà níbẹ̀, a sì fi pamọ́ nínú àgọ́ ọ rẹ̀, àti fàdákà ní abẹ́ ẹ rẹ̀. 23 Wọ́n sì mú àwọn nǹkan náà jáde láti inú àgọ́ rẹ̀, wọ́n mú wọn wá fún Joṣua àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì fi wọ́n lélẹ̀ níwájú Olúwa.

24 Nígbà náà ni Joṣua pẹ̀lú gbogbo Israẹli, mú Akani ọmọ Sera, fàdákà, ẹ̀wù àti wúrà tí a dà, àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin, màlúù rẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti àgùntàn àgọ́ rẹ̀ àti gbogbo ohun tí ó ni, wọ́n sì kó wọn lọ sí ibi Àfonífojì Akori. 25 Joṣua sì wí pé, “Èéṣe tí ìwọ mú wàhálà yìí wá sí orí wa? Olúwa yóò mú ìpọ́njú wá sí orí ìwọ náà lónìí.”

Nígbà náà ni gbogbo Israẹli sọ ọ́ ní òkúta pa, lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n sọ àwọn tókù ní òkúta pa tán, wọ́n sì jó wọn níná. 26 Wọ́n sì kó òkìtì òkúta ńlá lé Akani lórí títí di òní yìí. Nígbà náà ní Olúwa sì yí ìbínú gbígbóná rẹ̀ padà. Nítorí náà ni a ṣe ń pe orúkọ ibẹ̀ ní Àfonífojì Akori láti ìgbà náà.

Heberu 10:26-31

26 Nítorí bí àwa ba mọ̀ ọ́n mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí àwa bá ti gba ìmọ̀ òtítọ́ kò tún sí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. 27 (A)Bí kò ṣe ìrètí ìdájọ́ tí ó ba ni lẹ́rù, àti ti ìbínú ti o múná, tí yóò pa àwọn ọ̀tá run. 28 (B)Ẹnikẹ́ni tí ó ba gan òfin Mose, ó kú láìsí àánú nípa ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta: 29 (C)Mélòó mélòó ni ẹ rò pé a o jẹ ẹni náà ní ìyà kíkan, ẹni tí o tẹ ọmọ Ọlọ́run mọ́lẹ̀ tí ó sì ti ka ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú ti a fi sọ ọ́ di mímọ́ si ohun àìmọ́, tí ó sì ti kẹ́gàn ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́. 30 (D)Nítorí àwa mọ ẹni tí o wí pé: Ẹ̀san ni ti èmi, Olúwa wí pé, “Èmi ó gbẹ̀san.” Àti pẹ̀lú, “Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.” 31 Ohun ẹ̀rù ni láti ṣubú sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.