Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 49:1-12

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.

49 Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn!
    Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin aráyé.
Àti ẹni tí ó ga àti ẹni tí ó kéré
    tálákà àti ọlọ́lá pẹ̀lú!
Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,
    èrò láti ọkàn mi yóò mú òye wá
Èmi yóò dẹ etí mi sílẹ̀ sí òwe,
    èmi yóò ṣí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mi sílẹ̀ lójú okùn dùùrù.

Èéṣe ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi dé?
    Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ajinnilẹ́sẹ̀ mi yí mi ká,
Àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn,
    tí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ wọn.
Kò sí ọkùnrin tí ó lè ra ẹ̀mí ẹnìkejì rẹ̀
    padà tàbí san owó ìràpadà fún
Ọlọ́run.
Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ́ iyebíye
    kò sì sí iye owó tó tó fún sísan rẹ̀,
Ní ti kí ó máa wà títí ayé
    láìrí isà òkú.
10 Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kú,
    bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú ṣègbé
wọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.
11 Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláé,
    ibùgbé wọn láti ìrandíran,
wọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn.

12 Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́
    ó sì dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.

Oniwaasu 1:1-11

Asán ni ohun ayé

Ọ̀rọ̀ Oniwaasu, ọmọ Dafidi, ọba Jerusalẹmu:

“Asán inú asán!”
    oníwàásù náà wí pé,
“Asán inú asán!
    Gbogbo rẹ̀ asán ni.”

Kí ni ènìyàn rí jẹ ní èrè lórí gbogbo iṣẹ́ rẹ̀,
    lórí èyí tí ó ń ṣe wàhálà sí lábẹ́ oòrùn?
Bí ìran kan ti wá ni ìran mìíràn ń kọjá lọ,
    síbẹ̀ ayé dúró títí láé.
Oòrùn ń ràn, oòrùn sì ń wọ̀,
    ó sì sáré padà sí ibi tí ó ti yọ.
Afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ sí ìhà gúúsù,
    Ó sì ń fẹ́ yípo sí ìhà àríwá,
a sì tún padà sí ọ̀nà rẹ̀.
Gbogbo odò ń sàn sí inú Òkun,
    síbẹ̀síbẹ̀ Òkun kò kún.
Níbi tí àwọn odò ti wá,
    níbẹ̀ ni wọ́n tún padà sí.
Ohun gbogbo ni ó ń mú àárẹ̀ wá,
    ju èyí tí ẹnu le è sọ.
Ojú kò tí ì rí ìrírí tí ó tẹ́ ẹ lọ́rùn,
    bẹ́ẹ̀ ni, etí kò tí ì kún fún gbígbọ́.
Ohun tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ náà ni yóò sì máa wà, ohun tí a ti ṣe sẹ́yìn
    òun ni a ó tún máa ṣe padà
    kò sí ohun tuntun lábẹ́ oòrùn.
10 Ǹjẹ́ ohun kan wà tí ẹnìkan le è sọ wí pé,
    “Wò ó! Ohun tuntun ni èyí”?
Ó ti wà tẹ́lẹ̀ rí ní ọjọ́ tó ti pẹ́,
    o ti wà ṣáájú tiwa.
11 Kò sí ìrántí ohun ìṣáájú
    bẹ́ẹ̀ ni ìrántí kì yóò sí fún
ohun ìkẹyìn tí ń bọ̀
    lọ́dọ̀ àwọn tí ń bọ̀ ní ìgbà ìkẹyìn.

Marku 10:17-22

Ọ̀dọ́mọkùnrin ọlọ́rọ̀

17 (A)(B) Bí Jesu ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ, ọkùnrin kan sáré wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sì kúnlẹ̀, ó béèrè pé, “Olùkọ́ rere, kí ni èmi yóò ṣe láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”

18 Jesu béèrè pé, Arákùnrin, “Èéṣe tí o fi ń pè mí ní ẹni rere? Ẹni rere kan kò sí Ọlọ́run nìkan ni ẹni rere. 19 (C)Ìwọ mọ àwọn òfin bí: Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà, ìwọ kò gbọdọ̀ jalè, ìwọ kò gbọdọ̀ purọ́, ìwọ kò gbọdọ̀ rẹ́ ọmọnìkejì jẹ, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.”

20 Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Olùkọ́, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń ṣe láti ìgbà èwe mi wá.”

21 (D)Jesu wò ó tìfẹ́tìfẹ́. Ó wí fún un pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun kan ló kù fún ọ láti ṣe, lọ nísinsin yìí, ta gbogbo nǹkan tí o ní, kí o sì pín owó náà fún àwọn aláìní ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run, sì wá, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

22 Nígbà tí ọkùnrin yìí gbọ́ èyí, ojú rẹ̀ korò, ó sì lọ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí pé ó ní ọrọ̀ púpọ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.