Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.
49 Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn!
Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin aráyé.
2 Àti ẹni tí ó ga àti ẹni tí ó kéré
tálákà àti ọlọ́lá pẹ̀lú!
3 Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,
èrò láti ọkàn mi yóò mú òye wá
4 Èmi yóò dẹ etí mi sílẹ̀ sí òwe,
èmi yóò ṣí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mi sílẹ̀ lójú okùn dùùrù.
5 Èéṣe ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi dé?
Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ajinnilẹ́sẹ̀ mi yí mi ká,
6 Àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn,
tí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ wọn.
7 Kò sí ọkùnrin tí ó lè ra ẹ̀mí ẹnìkejì rẹ̀
padà tàbí san owó ìràpadà fún
Ọlọ́run.
8 Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ́ iyebíye
kò sì sí iye owó tó tó fún sísan rẹ̀,
9 Ní ti kí ó máa wà títí ayé
láìrí isà òkú.
10 Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kú,
bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú ṣègbé
wọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.
11 Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláé,
ibùgbé wọn láti ìrandíran,
wọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn.
12 Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́
ó sì dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.
24 Má ṣe ṣe ìlara àwọn ènìyàn búburú
má ṣe jẹ́ kí àwùjọ wọn wù ọ́;
2 Nítorí ọkàn wọn ń gbèrò ohun búburú,
ètè wọn sì ń sọ̀rọ̀ nípa dídá rúgúdù sílẹ̀.
3 Nípa ọgbọ́n ni ilé di kíkọ́
nípa òye sì ni ó ti fìdímúlẹ̀;
4 Nípa ìmọ̀ ni àwọn yàrá rẹ̀ kún
pẹ̀lú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà tí ó sì ṣọ̀wọ́n.
5 Ọlọ́gbọ́n ènìyàn ní agbára púpọ̀,
ènìyàn tí ó ní ìmọ̀ sì ń ní agbára sí i
6 Láti jagun, ó nílò ìtọ́sọ́nà:
nínú ìṣẹ́gun ni ọ̀pọ̀ onígbìmọ̀.
7 Ọgbọ́n ga ju fún aṣiwèrè
àti gbọ̀ngàn ìlú níbi ibodè kò ní ohun tí yóò wí.
8 Ẹni tí ń pète ibi
ni a ó mọ̀ bí ènìyàn ibi.
9 Ète òmùgọ̀ ènìyàn jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,
àwọn ènìyàn sì kórìíra ẹlẹ́gàn.
10 Bí ìwọ bá dákú lásìkò ìdààmú
báwo ni agbára rẹ ha ti kéré tó!
11 Gba àwọn tí a ń wọ́ lọ sí ibi ikú là;
fa àwọn tó ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n lọ sí ibi ìparun padà.
12 Bí ìwọ bá wí pé, “Ṣùgbọ́n a kò mọ nǹkan kan nípa èyí,”
ǹjẹ́ ẹni tí ń díwọ̀n ọkàn kò kíyèsi i? Ǹjẹ́ ẹni tí ń ṣọ́ ẹ̀mí rẹ kò mọ̀ ọ́n?
Ǹjẹ́ kò ní san án fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó ti ṣe?
Gbígbé ìgbé ayé gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀
17 Ǹjẹ́ èyí ni mo ń wí, tí mo sì ń jẹ́rìí nínú Olúwa pé, láti ìsinsin yìí lọ, kí ẹ̀yin má ṣe rìn mọ́, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìkọlà ti ń rìn nínú ìrònú asán wọn. 18 Òye àwọn ẹni tí ó ṣókùnkùn, a sì yà wọ́n nínú ìyè Ọlọ́run nítorí àìmọ̀ tí ń bẹ nínú wọn, nítorí líle ọkàn wọn. 19 Àwọn ẹni tí ọkàn wọn le rékọjá, tí wọ́n sì ti fi ara wọn fún wọ̀bìà, láti máa fi ìwọra ṣiṣẹ́ ìwà èérí gbogbo.
20 Ṣùgbọ́n a kò fi Kristi kọ́ yín bẹ́ẹ̀. 21 Bí ó bá ṣe pé nítòótọ́ ni ẹ ti gbóhùn rẹ̀ ti a sì ti kọ́ yín nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ti ń bẹ nínú Jesu. 22 Pé, ní tì ìwà yín àtijọ́, kí ẹ̀yin bọ́ ògbólógbòó ọkùnrin nì sílẹ̀, èyí tí ó díbàjẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀tàn; 23 Kí ẹ sì di tuntun ni ẹ̀mí inú yín; 24 kí ẹ sì gbé ọkùnrin tuntun ni wọ̀, èyí tí a dá ni àwòrán Ọlọ́run nínú òdodo àti ìwà mímọ́ ti òtítọ́.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.