Revised Common Lectionary (Complementary)
11 Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa,
dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, nítorí tí ó tóbi.
12 Àwọn wo ni ó bẹ̀rù Olúwa?
Yóò kọ́ wọn ní ọ̀nà èyí tí wọn yóò yàn.
13 Wọn yóò lo ọjọ́ wọn nínú àlàáfíà,
àwọn ọmọ wọn yóò sì gba ilẹ̀ náà.
14 Olúwa fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u rẹ̀;
ó sọ májẹ̀mú rẹ̀ di mí mọ̀ fún wọn.
15 Ojú mi gbé sókè sọ́dọ̀ Olúwa,
nítorí pé yóò yọ ẹsẹ̀ mi kúrò nínú àwọ̀n náà.
16 Yípadà sí mi, kí o sì ṣe oore fún mi;
nítorí pé mo nìkan wà, mo sì di olùpọ́njú.
17 Tì mí lẹ́yìn kúrò nínú ìpọ́njú àyà mi;
kí o sì fà mí yọ kúrò nínú ìpọ́njú mi.
18 Kíyèsi ìjìyà àti wàhálà mi,
kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.
19 Kíyèsi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀tá mi,
tí wọn kórìíra mi pẹ̀lú ìwà ìkà wọn.
20 Pa ọkàn mi mọ́, kí o sì gbà mí sílẹ̀;
Má ṣe jẹ́ kí a fi mí sínú ìtìjú,
nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi mi.
19 Ó sàn kí ènìyàn jẹ́ tálákà tí ìrìn rẹ̀ kò lábùkù ju aláìgbọ́n tí ètè rẹ̀ jẹ́ àyídáyidà.
2 Kò dára láti ní ìtara láìní ìmọ̀ tàbí kí ènìyàn kánjú kí ó sì ṣìnà.
3 Ìwà òmùgọ̀ ènìyàn fúnrarẹ̀ a pa ẹ̀mí rẹ̀ run;
síbẹ̀ ọkàn rẹ̀ yóò máa bínú sí Olúwa.
4 Ọrọ̀ máa ń fa ọ̀rẹ́ púpọ̀;
ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ tálákà tún kọ̀ ọ́ sílẹ̀.
5 Ajẹ́rìí èké kò ní lọ láìjìyà, ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde kò ní lọ lọ́fẹ̀ẹ́.
6 Ọ̀pọ̀ ń wá ojúrere olórí;
gbogbo ènìyàn sì ni ọ̀rẹ́ ẹni tí ó lawọ́.
7 Gbogbo ará ilé e tálákà ni ó pa á tì
mélòó mélòó ni ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ń sá fún un!
Bí ó tilẹ̀ ń lé wọn kiri pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀,
kò tilẹ̀ le rí wọn rárá.
8 Ẹni tí ó gba ọgbọ́n fẹ́ràn ọkàn ara rẹ̀;
ẹni tí ó bá káràmáṣìkí òye yóò gbèrú.
9 Ajẹ́rìí èké kì yóò lọ láìjìyà
ẹni tí ó sì ń tú irọ́ jáde yóò parun.
10 Kò yẹ aláìgbọ́n láti máa gbé nínú ọláńlá,
mélòó mélòó bí ó ti burú tó fún ẹrú láti jẹ ọba lórí ọmọ-aládé.
11 Ọgbọ́n ènìyàn a máa fún un ní sùúrù;
fún ògo rẹ̀ ni láti fojú fo àṣìṣe dá.
12 Ìbínú ọba dàbí kíké e kìnnìún,
ṣùgbọ́n ojúrere rẹ̀ dàbí ìrì lára koríko.
13 Aṣiwèrè ọmọ jẹ́ ìparun baba rẹ̀,
Aya tí ó máa ń jà sì dàbí ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀ òjò.
14 A máa ń jogún ilé àti ọrọ̀ lọ́dọ̀ òbí
ṣùgbọ́n aya olóye láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni.
15 Ọ̀lẹ ṣíṣe máa ń fa oorun sísùn fọnfọn,
ebi yóò sì máa pa ènìyàn tí ó lọ́ra.
16 Ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́ ẹ̀kọ́ pa ẹnu rẹ̀ mọ́
ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kẹ́gàn ọ̀nà rẹ̀ yóò kú.
17 Ẹni tí ó ṣàánú tálákà, Olúwa ní ó yá
yóò sì pín in lérè ohun tí ó ti ṣe.
Fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ
11 (A)Nítorí èyí ni iṣẹ́ tí ẹ̀yin tí gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé ki àwa fẹ́ràn ara wa. 12 Kì í ṣe bí Kaini, tí í ṣe ẹni búburú, tí o sì pa arákùnrin rẹ̀. Nítorí kín ni ó sì ṣe pa á? Nítorí tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́ búburú ṣùgbọ́n tí arákùnrin rẹ̀ sì jẹ́ òdodo. 13 (B)Kì ẹnu má ṣe yà yín, ẹ̀yin ará mi, bí ayé bá kórìíra yín. 14 (C)Àwa mọ̀ pé àwa tí rékọjá láti inú ikú sínú ìyè, nítorí tí àwa fẹ́ràn àwọn ará. Ẹni tí kò ba ni ìfẹ́, ó ń gbé inú ikú. 15 Ẹnikẹ́ni tí ó ba kórìíra arákùnrin rẹ̀ apànìyàn ni: ẹ̀yin sì mọ́ pé kò sí apànìyàn tí ó ni ìyè àìnípẹ̀kun láti máa gbé inú rẹ̀.
16 (D)Nípa èyí ni àwa mọ ìfẹ́ nítorí tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa: ó sì yẹ kí àwa fi ẹ̀mí wa lélẹ̀ fún àwọn ará. 17 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ni ohun ìní ayé, tí ó sì ri arákùnrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí ó sì sé ìlẹ̀kùn ìyọ́nú rẹ̀ mọ́ ọn, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe ń gbé inú rẹ̀?
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.