Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 64

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

64 Gbóhùn mi, Ọlọ́run, bí mo ti ń sọ àròyé mi
    pa ọkàn mi mọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀rù àwọn ọ̀tá.

Pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn ènìyàn búburú
    kúrò nínú ọ̀pọ̀ igbe lọ́wọ́ ìrúkèrúdò oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà,
    wọ́n sì fa ọrun wọn le láti tafà wọn, àní ọ̀rọ̀ kíkorò.
Wọ́n tafà ní ìkọ̀kọ̀ sí àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀:
    wọ́n tafà si lójijì, wọn kò sì bẹ̀rù.

Wọ́n, gba ara wọn níyànjú nínú èrò búburú,
    wọ́n sọ̀rọ̀ lórí dídẹkùn sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀
    wọ́n wí pé, “Ta ni yóò rí wa?”
Wọ́n gbìmọ̀ àìṣòdodo, wọ́n wí pé,
    “A wa ti parí èrò tí a gbà tán”
    lóòótọ́ àyà àti ọkàn ènìyàn kún fún àrékérekè.

Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ta wọ́n ní ọfà;
    wọn ó sì gbọgbẹ́ lójijì.
Ahọ́n wọn yóò sì dojú ìjà kọ wọ́n, yóò sì run wọ́n,
    Gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn yóò sì mi orí fún wọn.
Gbogbo ènìyàn yóò máa bẹ̀rù
    wọn ó kéde iṣẹ́ Ọlọ́run
    wọn ó dúró lé ohun tí ó ṣe.

10 Jẹ́ kí olódodo kí ó yọ̀ nínú Olúwa
    yóò sì rí ààbò nínú rẹ̀.
    Gbogbo ẹni ìdúró ṣinṣin ní ọkàn yóò máa yìn ín.

Esekiẹli 32:1-10

Ìpohùnréré ẹkún fún Farao

32 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kejìlá, ọdún kejìlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: “Ọmọ ènìyàn, ṣe ìpohùnréré ẹkún nítorí Farao ọba Ejibiti kí o sì wí fún un:

“ ‘Ìwọ dàbí kìnnìún láàrín àwọn
    orílẹ̀-èdè náà;
ìwọ dàbí ohun ẹ̀mí búburú inú àwọn omi okun to ń lọ
    káàkiri inú àwọn odò rẹ,
ìwọ fi ẹsẹ̀ rẹ tẹ omi
    láti mú kí àwọn odò ní ẹrẹ̀.

“ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìpéjọ ènìyàn
    èmi yóò da àwọ̀n mi bò ọ́
    wọn yóò sì fà ọ́ sókè nínú àwọ̀n mi.
Èmi yóò jù ọ́ sí orí ilẹ̀
    èmi yóò sì fà ọ́ sókè sí orí pápá gbangba.
Èmi yóò jẹ́ kí gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ṣe
    àtìpó ní orí rẹ.
Gbogbo àwọn ẹranko ayé yóò fi
    ìwọra gbé ara wọn lórí rẹ.
Èmi yóò tan ẹran-ara rẹ ká sórí
    àwọn òkè gíga
ìyókù ara rẹ ní wọn yóò fi kún
    àwọn àárín àwọn òkè gíga
Ẹ̀jẹ̀ rẹ ti ń sàn ní èmi yóò sì fi rin ilẹ̀ náà
    gbogbo ọ̀nà sí orí àwọn òkè gíga,
    àwọn àlàfo jíjìn ní wọn yóò kún fún ẹran-ara rẹ.
Nígbà tí mo bá fọ́n ọ jáde, èmi yóò pa ọ̀run dé
    àwọn ìràwọ̀ wọn yóò sì ṣókùnkùn;
èmi yóò sì fi ìkùùkuu bo oòrùn
    òṣùpá kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀
Gbogbo ìmọ́lẹ̀ títàn ní ojú ọ̀run
    ni èmi yóò mú ṣókùnkùn lórí rẹ;
èmi yóò mú òkùnkùn wá sórí ilẹ̀ rẹ,
    ni Olúwa Olódùmarè wí
Èmi yóò da ọkàn ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn rú
    nígbà tí mo bá mú ìparun rẹ wá
ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ
    kò í tí ì mọ̀.
10 Èmi yóò mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn dẹ́rùbà ọ́,
    àwọn ọba wọn yóò sì wárìrì fún
ìbẹ̀rù pẹ̀lú ìpayà nítorí rẹ,
    nígbà tí mo bá ju idà mi ní iwájú wọn
Ní ọjọ́ ìṣubú rẹ
    ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú wọn yóò wárìrì
    ní gbogbo ìgbà fún ẹ̀mí rẹ.

Luku 9:37-43

Ìwòsàn ọmọkùnrin kan tí o ní ẹ̀mí èṣù

37 (A)Ó sì ṣe, ní ọjọ́ kejì, nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti orí òkè, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn wá pàdé rẹ̀. 38 Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan nínú ìjọ ènìyàn kígbe sókè, pé “Olùkọ́ mo bẹ̀ ọ́, wo ọmọ mi: nítorí ọmọ mi kan ṣoṣo náà ni. 39 Sì kíyèsi i, ẹ̀mí èṣù a máa mú un, a sì máa kígbe lójijì; a sì máa nà án tàntàn títí yóò fi yọ ìfófó lẹ́nu, a máa pa á lára, kì í tilẹ̀ ń fẹ́ fi í sílẹ̀ lọ. 40 Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ láti lé e jáde: wọn kò sì lè ṣe é.”

41 Jesu sì dáhùn pé, “Ìran aláìgbàgbọ́ àti àrékérekè, èmi ó ti bá yín gbé pẹ́ tó? Èmi yóò sì ti ṣe sùúrù fún yín pẹ́ tó? Fa ọmọ rẹ wá níhìn-ín yìí.”

42 Bí ó sì ti ń bọ̀, ẹ̀mí èṣù náà gbé e ṣánlẹ̀, ó sì nà án tàntàn. Jesu sì bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí, ó sì mú ọmọ náà láradá, ó sì fà á lé baba rẹ̀ lọ́wọ́. 43 (B)Ẹnu sì ya gbogbo wọn sí iṣẹ́ títóbi Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nígbà tí hà sì ń ṣe gbogbo wọn sí ohun gbogbo tí Jesu ṣe, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé,

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.