Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 64

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.

64 Gbóhùn mi, Ọlọ́run, bí mo ti ń sọ àròyé mi
    pa ọkàn mi mọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀rù àwọn ọ̀tá.

Pa mí mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìmọ̀ ìkọ̀kọ̀ àwọn ènìyàn búburú
    kúrò nínú ọ̀pọ̀ igbe lọ́wọ́ ìrúkèrúdò oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀.
Wọ́n pọ́n ahọ́n wọn bí idà,
    wọ́n sì fa ọrun wọn le láti tafà wọn, àní ọ̀rọ̀ kíkorò.
Wọ́n tafà ní ìkọ̀kọ̀ sí àwọn aláìlẹ́ṣẹ̀:
    wọ́n tafà si lójijì, wọn kò sì bẹ̀rù.

Wọ́n, gba ara wọn níyànjú nínú èrò búburú,
    wọ́n sọ̀rọ̀ lórí dídẹkùn sílẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀
    wọ́n wí pé, “Ta ni yóò rí wa?”
Wọ́n gbìmọ̀ àìṣòdodo, wọ́n wí pé,
    “A wa ti parí èrò tí a gbà tán”
    lóòótọ́ àyà àti ọkàn ènìyàn kún fún àrékérekè.

Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ta wọ́n ní ọfà;
    wọn ó sì gbọgbẹ́ lójijì.
Ahọ́n wọn yóò sì dojú ìjà kọ wọ́n, yóò sì run wọ́n,
    Gbogbo ẹni tí ó bá rí wọn yóò sì mi orí fún wọn.
Gbogbo ènìyàn yóò máa bẹ̀rù
    wọn ó kéde iṣẹ́ Ọlọ́run
    wọn ó dúró lé ohun tí ó ṣe.

10 Jẹ́ kí olódodo kí ó yọ̀ nínú Olúwa
    yóò sì rí ààbò nínú rẹ̀.
    Gbogbo ẹni ìdúró ṣinṣin ní ọkàn yóò máa yìn ín.

Jobu 19:1-22

Ìdáhùn Jobu fún Bilidadi

19 Ìgbà náà ni Jobu dáhùn, ó sì wí pé:

“Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin ó fi máa fi ìyà jẹ mí,
    tí ẹ̀yin ó fi máa fi ọ̀rọ̀ yìí?
Ìgbà mẹ́wàá ní yin yọ mi lénu ẹ̀yin ti ń gàn mí;
    ojú kò tì yín tí ẹ fi jẹ mí ní yà.
Kí a sì wí bẹ́ẹ̀ pé, mo ṣìnà nítòótọ́,
    ìṣìnà mi wà lára èmi tìkára mi.
Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ̀yin ó ṣògo si mi lórí nítòótọ́,
    tí ẹ ó sì máa fi ẹ̀gàn mi gún mí lójú,
Kí ẹ mọ̀ nísinsin yìí pé, Ọlọ́run ni ó bì mí ṣubú,
    ó sì nà àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká.

“Kíyèsi, èmi ń kígbe pe, ‘Ọwọ́ alágbára!’ Ṣùgbọ́n a kò gbọ́ ti èmi;
    mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdájọ́.
Ó ṣọgbà dí ọ̀nà mi tí èmi kò le è kọjá,
    Ó sì mú òkùnkùn ṣú sí ipa ọ̀nà mi.
Ó ti bọ́ ògo mi,
    ó sì ṣí adé kúrò ní orí mi.
10 Ó ti bà mí jẹ́ ní ìhà gbogbo,
    ẹ̀mí sì pin; ìrètí mi ni a ó sì fàtu bí igi.
11 Ó sì tiná bọ ìbínú rẹ̀ sí mi,
    ó sì kà mí sí bí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀tá rẹ̀.
12 Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ sì dàpọ̀ sí mi,
    wọ́n sì mọ odi yí mi ká,
    wọ́n sì yí àgọ́ mi ká.

13 “Ó mú àwọn arákùnrin mi jìnà sí mi réré,
    àti àwọn ojúlùmọ̀ mi di àjèjì sí mi pátápátá.
14 Àwọn alájọbí mi fàsẹ́yìn,
    àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi sì di onígbàgbé mi.
15 Àwọn ará inú ilé mi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi kà mí sí àjèjì;
    èmi jásí àjèjì ènìyàn ní ojú wọn.
16 Mo pe ìránṣẹ́ mi, òun kò sì dá mi lóhùn;
    mo fi ẹnu mi bẹ̀ ẹ́.
17 Ẹ̀mí mi ṣú àyà mi, àti òórùn mi
    ṣú àwọn ọmọ inú ìyá mi.
18 Àní àwọn ọmọdékùnrin fi mí ṣẹ̀sín:
    Mo dìde, wọ́n sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi.
19 Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi kórìíra mi,
    àwọn olùfẹ́ mi sì kẹ̀yìndà mí.
20 Egungun mi lẹ̀ mọ́ ara mi àti mọ́ ẹran-ara mi,
    mo sì yọ́ pẹ̀lú awọ eyín mi.

21 “Ẹ ṣàánú fún mi, ẹ ṣàánú fún mi,
    ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, nítorí ọwọ́ Ọlọ́run ti bà mí.
22 Nítorí kí ni ẹ̀yin ṣe lépa mi bí
    Ọlọ́run, tí ẹran-ara mi kò tẹ́ yín lọ́rùn?

Efesu 2:11-22

Ọ̀kan nínú Kristi

11 Nítorí náà ẹ rántí pé, nígbà àtijọ́ rí, ẹ̀yin tí ẹ ti jẹ́ Kèfèrí nípa ti ìbí, tí àwọn tí a ń pè ní “aláìkọlà” láti ọwọ́ àwọn tí ń pe ara wọn “akọlà” (Èyí ti a fi ọwọ́ ènìyàn ṣe sí ni ni ara)— 12 (A)Ẹ rántí pé ni àkókò náà ẹ̀yin wà láìní Kristi, ẹ jẹ́ àjèjì sí Israẹli, àti àjèjì sí àwọn májẹ̀mú ìlérí náà, láìní ìrètí, àti láìní Ọlọ́run ni ayé. 13 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí nínú Kristi Jesu ẹ̀yin tí ó ti jìnà réré nígbà àtijọ́ rí ni a mú súnmọ́ tòsí, nípa ẹ̀jẹ̀ Kristi.

14 Nítorí òun ni àlàáfíà wa, ẹni tí o ti ṣe méjèèjì ni ọ̀kan, tí ó sì ti wó ògiri ìkélé ti ìkórìíra èyí tí ń bẹ láàrín yín. 15 Ó sì ti fi òpin sí ọ̀tá náà nínú ara rẹ̀, àní sí òfin àti àṣẹ wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ nínú ìlànà, kí ó lè sọ àwọn méjèèjì di ẹni tuntun kan nínú ara rẹ̀, kí ó sì ṣe ìlàjà 16 àti kí ó lè mú àwọn méjèèjì bá Ọlọ́run làjà nínú ara kan nípa àgbélébùú; nípa èyí tí yóò fi pa ìṣọ̀tá náà run. 17 (B)Ó sì ti wá, ó sì ti wàásù àlàáfíà fún ẹ̀yin tí o jìnnà réré, àti àlàáfíà fún àwọn tí o súnmọ́ tòsí. 18 Nítorí nípa rẹ̀ ni àwa méjèèjì ti ni àǹfààní sọ́dọ̀ baba nípa Ẹ̀mí kan.

19 Ǹjẹ́ nítorí náà ẹ̀yin kì í ṣe àlejò àti àjèjì mọ́, ṣùgbọ́n àjùmọ̀jogún ọmọ ìbílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn ará ilé Ọlọ́run; 20 a sì ń gbé yín ró lórí ìpìlẹ̀ àwọn aposteli, àti àwọn wòlíì, pẹ̀lú Jesu Kristi fúnrarẹ̀ gẹ́gẹ́ bí pàtàkì òkúta igun ilé; 21 Nínú rẹ ni gbogbo ilé náà, tí a ń kọ wà papọ̀ ṣọ̀kan tí ó sì ń dàgbàsókè láti di tẹmpili mímọ́ kan nínú Olúwa: 22 Nínú rẹ̀ ni a ń gbé ẹ̀yin pẹ̀lú ró pẹ̀lú fún ibùjókòó Ọlọ́run nínú Ẹ̀mí rẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.