Revised Common Lectionary (Complementary)
93 Olúwa ń jẹ ọba, ọláńlá ni ó wọ̀ ní aṣọ;
ọláńlá ni Olúwa wọ̀ ní aṣọ
àti ìhámọ́ra rẹ̀ pẹ̀lú agbára.
Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;
kò sì le è yí.
2 Ìjọba rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́;
ìwọ wà títí ayérayé.
3 A ti gbé Òkun sókè, Olúwa,
Òkun ti gbé ohùn wọn sókè;
Òkun ti gbé rírú omi wọn sókè.
4 Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ,
ó ni ògo ju Òkun rírú lọ
Olúwa ga ní ògo.
5 Ẹ̀rí rẹ̀ dúró ṣinṣin;
ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́
fún ọjọ́ àìlópin, Olúwa.
Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Sidoni
20 (A)Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 21 “Ọmọ ènìyàn, kọ ojú sí Sidoni; kí o sì sọtẹ́lẹ̀ sí i 22 Kí ó sì wí pé: ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Sidoni,
a ó sì ṣe mí lógo láàrín rẹ.
Wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa,
Nígbà tí mo bá mú ìdájọ́ mi ṣẹ nínú rẹ,
tí a sì yá mí sí mímọ́ nínú rẹ,
23 Èmi yóò sì rán àjàkálẹ̀-ààrùn sínú rẹ,
èmi yóò sì mú kí ẹ̀jẹ̀ sàn ní ìgboro rẹ,
ẹni ti á pa yóò ṣubú ní àárín rẹ,
pẹ̀lú idà lára rẹ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́,
nígbà náà wọn yóò mọ̀ wí pé èmi ni Olúwa.
24 “ ‘Kì yóò sì ṣí ẹ̀gún tí ń gun ni ní ilẹ̀ Israẹli mọ́, tàbí ẹ̀gún bíbani nínú jẹ́ ti gbogbo àwọn tí wọn wà ní àyíká wọn, tí wọ́n sì ń fi ojú yẹpẹrẹ wò wọ́n, nígbà náà ni wọn yóò mọ́ wí pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.
25 “ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí èmi yóò bá sa àwọn ènìyàn Israẹli jọ kúrò ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fọ́nká sí, tí a ó sì yà mí sí mímọ́ láàrín wọn lójú àwọn aláìkọlà; Nígbà náà ni wọn yóò gbé ní ilẹ̀ àwọn tìkálára wọn, èyí tí mo fún ìránṣẹ́ mi Jakọbu. 26 Wọn yóò sì máa gbé ní inú rẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì kọ́lé, wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà; nítòótọ́ wọn yóò wà ní ìbàlẹ̀ àyà, nígba tí èmi bá ti mú ìdájọ́ mi ṣẹ̀ sí ara àwọn tí ń ṣátá wọn ní gbogbo àyíká wọn; Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.’ ”
20 Ǹjẹ́ nísinsin yìí Kristi tí jíǹde kúrò nínú òkú, ó sì dí àkọ́bí nínú àwọn tí ó sùn. 21 (A)Nítorí ìgbà tí ó jẹ́ pé nípa ènìyàn ní ikú ti wá, nípa ènìyàn ní àjíǹde òkú sì ti wá pẹ̀lú. 22 (B)Nítorí bí gbogbo ènìyàn ti kú nínú Adamu, bẹ́ẹ̀ ní a ó sì sọ gbogbo ènìyàn dí alààyè nínú Kristi. 23 (C)Ṣùgbọ́n olúkúlùkù ènìyàn ní ipá tirẹ̀: Kristi àkọ́bí; lẹ́yìn èyí àwọn tí ó jẹ́ tí Kristi ni wíwá rẹ̀. 24 Nígbà náà ni òpin yóò dé, nígbà tí ó bá ti fi ìjọba fún Ọlọ́run Baba, nígbà tí ó bá pa gbogbo àṣẹ àti gbogbo ọlá àti agbára run. 25 (D)Nítorí ti òun gbọdọ̀ ti jẹ ọba kí òun to fi gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. 26 Ikú ní ọ̀tá ìkẹyìn tí a ó parun 27 (E)“Nítorí ó ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.” Ṣùgbọ́n nígbà tí ó wí pé, “Ohun gbogbo ni á fi sí abẹ́ rẹ̀,” o dájú pé Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ní kò sí ní abẹ́ rẹ̀, Òun ní ó fi ohun gbogbo sí abẹ́ àkóso Kristi. 28 (F)Nígbà tí a bá sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ rẹ̀ tán, nígbà náà ni á ó fi ọmọ tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sábẹ́ Ẹni tí ó fi ohun gbogbo sí abẹ́ rẹ̀, kí Ọlọ́run lè jásí ohun gbogbo nínú ohun gbogbo.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.