Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
13 Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa? Ìwọ o ha gbàgbé mi títí láé?
Yóò tí pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?
2 Yóò ti pẹ́ tó tí èmi ó máa bá èrò mi jà,
àti ní ojoojúmọ́ ni èmi ń ní ìbànújẹ́ ní ọkàn mi?
Yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ọ̀tá mi yóò máa borí mi?
3 Wò mí kí o sì dá mi lóhùn, Olúwa Ọlọ́run mi.
Fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú mi, kí èmi ó má sún oorun ikú;
4 Ọ̀tá mi wí pé, “Èmi ti ṣẹ́gun rẹ̀,”
àwọn ọ̀tá mi yóò yọ̀ tí mo bá ṣubú.
5 Ṣùgbọ́n mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà;
ọkàn mi ń yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.
6 Èmi ó máa kọrin sí Olúwa,
nítorí ó dára sí mi.
Daniẹli rí ìran àgbò kan àti òbúkọ kan
8 Nígbà tí ó di ọdún kẹta ìjọba Belṣassari ọba, èmi Daniẹli rí ìran kan èyí tí mo ti rí tẹ́lẹ̀. 2 Nínú ìran náà, mo rí ara mi nínú ilé ìṣọ́ ní Susa ní agbègbè ìjọba Elamu: nínú ìran náà mo wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Ulai. 3 Mo wo òkè mo sì rí àgbò kan tí ó ní ìwo méjì níwájú mi, ó dúró sí ẹ̀gbẹ́ odò Ulai, àwọn ìwo náà sì gùn. Ṣùgbọ́n ọ̀kan gùn ju èkejì lọ, èyí tí ó gùn jù ni ó yọ jáde kẹ́yìn. 4 Mo rí àgbò náà ó ń kàn sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, sí àríwá, àti sí gúúsù, kò sí ẹranko kankan tí ó le è dojúkọ ọ́, kò sí ẹnìkan tí ó le è yọ ọ́ kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀, ó ń ṣe bí ó ti wù ú, ó sì di alágbára.
5 Bí mo ṣe ń ronú nípa èyí, lójijì ni òbúkọ kan tí ó ní ìwo láàrín ojú u rẹ̀ méjèèjì jáde láti ìhà ìwọ̀-oòrùn, ó la gbogbo ayé kọjá láìfi ara kan ilẹ̀. 6 Ó tọ àgbò tí ó ni ìwo méjì náà wá, èyí tí mo rí tó dúró sí ẹ̀gbẹ́ odò Ulai, ó sì dojúkọ ọ́ pẹ̀lú ìrunú tí ó lágbára. 7 Mo rí i tí ó fi ìtara kọlu àgbò náà, ó lu àgbò náà bolẹ̀, ó sì ṣẹ́ ìwo rẹ̀ méjèèjì. Àgbò náà kò sì ní agbára láti dojúkọ ọ́, Òbúkọ náà kàn án mọ́lẹ̀, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, kò sì ṣí ẹni tí ó lè gba àgbò náà là kúrò lọ́wọ́ agbára rẹ̀. 8 Òbúkọ náà sì di alágbára púpọ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí ó dé góńgó, agbára rẹ̀ ru sókè, ìwo ńlá a rẹ̀ sì ṣẹ́ dànù, ní ipò o rẹ̀, ìwo mẹ́rin mìíràn hù, ó sì yọrí sí ìhà igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run.
9 Lára ọ̀kan nínú wọn, ìwo mìíràn yọ jáde, ó kékeré, ṣùgbọ́n ó dàgbà nínú agbára sí ìhà gúúsù, àti sí ìhà ìlà-oòrùn àti sí ilẹ̀ dídára. 10 (A)Ó sì dàgbà títí ó fi kan ẹgbẹ́ ogun ọ̀run, ó sì jù lára àwọn ẹgbẹ́ ogun ọ̀run sí ayé ó sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, 11 ó sì gbé ara rẹ̀ ga gẹ́gẹ́ bí ọmọ-aládé ẹgbẹ́ ogun ọ̀run; ó sì mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì gba ààyè ibi mímọ́ rẹ̀. 12 A fún un ní ẹgbẹ́ ogun ọ̀run àti ẹbọ ojoojúmọ́ nítorí ìwà ọlọ̀tẹ̀ ẹ rẹ̀: ó sọ òtítọ́ nù nínú gbogbo ohun tó ṣe.
13 (B)Nígbà náà, ni mo gbọ́ tí ẹni mímọ́ ń sọ̀rọ̀, àti ẹni mímọ́ mìíràn sọ̀rọ̀ fún un pé, “Yóò ti pẹ́ tó tí ìran yìí yóò fi wá sí ìmúṣẹ—ìran nípa ẹbọ ojoojúmọ́, ìṣọ̀tẹ̀ tí ó mú ìsọdahoro wa, àní láti fi ibi mímọ́ àti ogun ọ̀run fún ni ní ìtẹ̀mọ́lẹ̀?”
14 Ó sọ fún mi pé, “Yóò gbà tó ẹgbọ̀kànlá lé lọ́gọ́rùn-ún (2,300) alẹ́ àti òwúrọ̀; lẹ́yìn náà ni a ó tún ibi mímọ́ yà sí mímọ́.”
26 Nítorí bí àwa ba mọ̀ ọ́n mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí àwa bá ti gba ìmọ̀ òtítọ́ kò tún sí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. 27 (A)Bí kò ṣe ìrètí ìdájọ́ tí ó ba ni lẹ́rù, àti ti ìbínú ti o múná, tí yóò pa àwọn ọ̀tá run. 28 (B)Ẹnikẹ́ni tí ó ba gan òfin Mose, ó kú láìsí àánú nípa ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta: 29 (C)Mélòó mélòó ni ẹ rò pé a o jẹ ẹni náà ní ìyà kíkan, ẹni tí o tẹ ọmọ Ọlọ́run mọ́lẹ̀ tí ó sì ti ka ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú ti a fi sọ ọ́ di mímọ́ si ohun àìmọ́, tí ó sì ti kẹ́gàn ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́. 30 (D)Nítorí àwa mọ ẹni tí o wí pé: Ẹ̀san ni ti èmi, Olúwa wí pé, “Èmi ó gbẹ̀san.” Àti pẹ̀lú, “Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀.” 31 Ohun ẹ̀rù ni láti ṣubú sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.