Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 16

Miktamu ti Dafidi.

16 Pa mí mọ́, Ọlọ́run,
    nítorí nínú rẹ ni ààbò mi wà.

Mo sọ fún Olúwa, “ìwọ ni Olúwa mi,
    lẹ́yìn rẹ èmi kò ní ìre kan.”
Sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ayé,
    àwọn ni ológo nínú èyí tí ayọ̀ mí wà.
Ìṣòro àwọn wọ̀n-ọn-nì yóò pọ̀ sí i, àní àwọn tí ń tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn.
    Ẹbọ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi kì yóò ta sílẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá orúkọ wọn lẹ́nu mi.

Olúwa, ni ìpín ìní mi tí mo yàn àti ago mi,
    ó ti pa ohun tí í ṣe tèmi mọ́.
Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára;
    nítòótọ́ mo ti ní ogún rere.
Èmi yóò yin Olúwa, ẹni tí ó gbà mí ní ìyànjú;
    ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀.
(A)Mo ti gbé Ọlọ́run síwájú mi ní ìgbà gbogbo.
    Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.

Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀;
    ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,
10 (B)nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú isà òkú,
    tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́.
11 Ìwọ ti fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí;
    Ìwọ yóò kún mi pẹ̀lú ayọ̀ ní iwájú rẹ,
    pẹ̀lú ìdùnnú ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

Daniẹli 4:28-37

Àlá náà ṣẹ

28 Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí Nebukadnessari ọba. 29 Lẹ́yìn oṣù kejìlá, bí ọba ṣe ń rìn káàkiri lórí òrùlé ààfin ìjọba Babeli, 30 Ó sọ pé, “Èyí ha kọ́ ni Babeli ńlá tí mo kọ́ gẹ́gẹ́ bí ilé ọba, nípa agbára à mi àti fún ògo ọláńlá à mi?”

31 Bí ọba ṣe ń sọ ọ̀rọ̀ náà lọ́wọ́ ohùn kan wá láti ọ̀run “Ìwọ Nebukadnessari ọba, ìwọ ni a ti pàṣẹ nípa rẹ̀, a ti gba ìjọba à rẹ kúrò ní ọwọ́ ọ̀ rẹ. 32 A ó lé ọ kúrò láàrín àwọn ènìyàn, ìwọ yóò sì lọ máa gbé àárín àwọn ẹranko igbó; ìwọ yóò jẹ koríko bí i màlúù, ìgbà méje yóò kọjá lórí i rẹ títí ìwọ yóò fi mọ̀ wí pé, Ọ̀gá-ògo jẹ ọba lórí ìjọba ènìyàn àti pé ó ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú.”

33 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ohun tí a sọ nípa Nebukadnessari ṣẹlẹ̀ sí i. A lé e kúrò láàrín ènìyàn, ó sì ń jẹ koríko bí i màlúù, ìrì ọ̀run sì ń sẹ̀ sí ara rẹ̀, títí irun orí rẹ̀ fi gùn bí i ti ìyẹ́ ẹyẹ idì, tí èékánná rẹ̀ sì dàbí i ti ẹyẹ.

34 Ní òpin ìgbà náà, Èmi, Nebukadnessari gbé ojú mi sókè sí ọ̀run, iyè mi sì sọjí. Mo fi ọpẹ́ fún Ọ̀gá-ògo; mo fi ọlá àti ògo fún ẹni tí ó wà láéláé.

Ìjọba rẹ̀ ìjọba títí ayé ni
    ìjọba rẹ̀ wà láti ìran dé ìran
35 Gbogbo àwọn ènìyàn ayé
    ni a kà sí asán.
Ó ń ṣe bí ó ti wù ú,
    pẹ̀lú àwọn ogun ọ̀run,
    àti gbogbo àwọn ènìyàn ayé
tí kò sì ṣí ẹnìkankan tí ó lè dí i lọ́wọ́
    tàbí sọ fún un wí pé: “Kí ni ìwọ ń ṣe?”

36 Ní àkókò kan náà, iyè mi padà, ọlá àti ògo dídán mi padà tọ̀ mí wá fún ògo ìjọba mi. Àwọn ìgbìmọ̀ àti àwọn ọlọ́lá mi, wá mi rí, wọ́n sì dá mi padà sórí ìjọba mi, mo sì di alágbára ju ti ìṣáájú lọ. 37 Báyìí, èmi, Nebukadnessari fi ọpẹ́, mo sì gbé Ọlọ́run ga, mo sì fi ògo fún ọba ọ̀run, nítorí pé gbogbo nǹkan tí ó ṣe ló dára, gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì tọ́. Gbogbo àwọn tó sì ń rìn ní ìgbéraga ni ó le rẹ̀ sílẹ̀.

Marku 12:1-12

Òwe àwọn ayálégbé

12 (A)Lẹ́yìn ìgbà tí Jesu pa àwọn olórí ẹ̀sìn lẹ́nu mọ́: ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkùnrin kan gbin ọgbà àjàrà kan. Ó ṣe ọgbà yìí ká, ó sì wá ibi ìfúntí wáìnì, ó sì kọ́ ilé ìṣọ́ sí i ó sì fi ṣe àgbàtọ́jú fún àwọn olùṣọ́gbà, ó sì lọ sí ìrìnàjò tí ó jìnnà. Lákokò ìkórè, ọkùnrin náà rán ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí àwọn olùṣọ́gbà náà, kí ó gbà nínú èso ọgbà àjàrà náà lọ́wọ́ àwọn olùṣọ́gbà. Ṣùgbọ́n àwọn àgbẹ̀ wọ̀n-ọn-nì lu ìránṣẹ́ ọkùnrin náà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo. Ó sì tún rán ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn sí wọn. Bí àwọn àgbẹ̀ ti tún rí ọmọ ọ̀dọ̀ tí ó rán sí wọn; wọ́n lù ú. Àní, wọ́n tilẹ̀ dá ọgbẹ́ sí i lórí, wọn rán an lọ ni ìtìjú. Ó sì tún rán òmíràn, èyí n nì wọ́n sì pa, àti ọ̀pọ̀ mìíràn, wọ́n lu òmíràn wọ́n sì pa òmíràn.

“Ìránṣẹ́ kan ṣoṣo ló kù tí Baba olóko kò ì tí ì rán níṣẹ́, èyí ni ọmọ òun tìkára rẹ̀. Níkẹyìn ó ran an sí àwọn olùṣọ́gbà náà, pẹ̀lú èrò pé, ‘Wọn yóò bu ọlá fún ọmọ òun.’

“Ṣùgbọ́n àwọn olùṣọ́gbà wọ̀n-ọn-nì wí fún ara wọn pé, ‘Èyí yìí ni àrólé. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, ogún rẹ̀ yóò sì jẹ́ tiwa.’ Báyìí ni wọ́n mú ọmọ náà tí wọ́n pa á. Wọ́n sì wọ́ òkú rẹ̀ jáde kúrò nínú ọgbà àjàrà náà.

“Kí ni olúwa ọgbà àjàrà yóò ṣe nígbà tí ó bá gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Dájúdájú yóò pa àwọn ẹni ibi wọ̀nyí. Yóò sì gba àwọn olùtọ́jú mìíràn sínú oko rẹ̀. 10 (B)Tàbí ẹ̀yin kò ì tí ka ẹsẹ yìí nínú ìwé mímọ́:

“ ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀
    òun náà ni ó di pàtàkì igun ilé.
11 Èyí ni iṣẹ́ Olúwa
    ó sì jẹ́ ìyàlẹ́nu lójú tiwa’?”

12 (C)Àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin pẹ̀lú àwọn àgbàgbà fẹ́ mú Jesu lákokò náà. Nítorí tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ló ń pòwe mọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn ni alágbàtọ́jú búburú nínú ìtàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà wọ́n láti fọwọ́ kàn án nítorí pé wọ́n bẹ̀rù ìhùwàsí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí náà wọ́n fi í sílẹ̀ lọ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.