Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 16

Miktamu ti Dafidi.

16 Pa mí mọ́, Ọlọ́run,
    nítorí nínú rẹ ni ààbò mi wà.

Mo sọ fún Olúwa, “ìwọ ni Olúwa mi,
    lẹ́yìn rẹ èmi kò ní ìre kan.”
Sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ayé,
    àwọn ni ológo nínú èyí tí ayọ̀ mí wà.
Ìṣòro àwọn wọ̀n-ọn-nì yóò pọ̀ sí i, àní àwọn tí ń tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn.
    Ẹbọ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi kì yóò ta sílẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá orúkọ wọn lẹ́nu mi.

Olúwa, ni ìpín ìní mi tí mo yàn àti ago mi,
    ó ti pa ohun tí í ṣe tèmi mọ́.
Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára;
    nítòótọ́ mo ti ní ogún rere.
Èmi yóò yin Olúwa, ẹni tí ó gbà mí ní ìyànjú;
    ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀.
(A)Mo ti gbé Ọlọ́run síwájú mi ní ìgbà gbogbo.
    Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.

Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀;
    ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,
10 (B)nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú isà òkú,
    tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́.
11 Ìwọ ti fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí;
    Ìwọ yóò kún mi pẹ̀lú ayọ̀ ní iwájú rẹ,
    pẹ̀lú ìdùnnú ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

Daniẹli 4:19-27

Daniẹli túmọ̀ àlá náà

19 Nígbà náà ni Daniẹli (ẹni tí à ń pè ní Belṣassari) páyà gidigidi fún ìgbà díẹ̀, èrò inú rẹ̀ sì bà á lẹ́rù. Nígbà náà ni ọba wí pé, “Belṣassari, má ṣe jẹ́ kí àlá náà tàbí ìtumọ̀ rẹ̀ kí ó dẹ́rùbà ọ́.”

Belṣassari sì dáhùn wí pé, “olúwa mi, kí àlá yìí jẹ́ ti àwọn ọ̀tá a rẹ, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ti àwọn aṣòdì sí ọ: 20 Igi tí ìwọ rí, tí ó dàgbà, tí ó sì lágbára, tí orí rẹ̀ sì ń kan ọ̀run, tí ó lẹ́wà àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso, tí ó ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn, tí ó ṣe ààbò lórí ẹranko igbó àti èyí tí ẹ̀ka rẹ̀ pèsè ààyè fún ẹyẹ ojú ọ̀run. 21 Èyí tí ewé e rẹ̀ lẹ́wà, tí èso rẹ̀ si pọ̀, nínú èyí tí oúnjẹ sì wà fún gbogbo ẹ̀dá, lábẹ́ èyí tí àwọn ẹranko igbó ń gbé, lórí ẹ̀ka èyí ti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní ibùgbé wọn. 22 Ìwọ ọba ni igi náà, ìwọ ti dàgbà, o sì lágbára, títóbi i rẹ ga ó sì kan ọ̀run, ìjọba rẹ sì gbilẹ̀ títí dé òpin ayé.

23 “Ìwọ ọba, rí ìránṣẹ́ ẹni mímọ́ kan, tí ó ń bọ̀ láti ọ̀run ó sì sọ pé, ‘Gé igi náà kí o sì run ún, ṣùgbọ́n fi kùkùté rẹ tí a dè pẹ̀lú irin àti idẹ sílẹ̀ nínú koríko igbó, nígbà tí gbòǹgbò rẹ̀ sì wà nínú ilẹ̀ kí o sì jẹ́ kí ìrì ọ̀run sẹ̀ sórí i rẹ̀, jẹ́ kí ìpín in rẹ̀ wà láàrín ẹranko búburú títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí i rẹ̀.’

24 “Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ ọba àti àṣẹ tí Ọ̀gá-ògo mú wá sórí ọba olúwa mi: 25 A ó lé ọ jáde kúrò láàrín ènìyàn, ìwọ yóò sì máa gbé láàrín ẹranko búburú: ìwọ yóò jẹ koríko bí i màlúù, ìrì ọ̀run yóò sì sẹ̀ sára rẹ. Ìgbà méje yóò sì kọjá lórí rẹ, títí ìwọ yóò fi mọ̀ wí pé Ọ̀gá-ògo ń jẹ ọba lórí ìjọba ènìyàn, ó sì ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú. 26 Bí wọ́n ṣe pàṣẹ pé kí wọn fi kùkùté àti gbòǹgbò igi náà sílẹ̀, èyí túmọ̀ sí wí pé a ó dá ìjọba rẹ padà fún ọ lẹ́yìn ìgbà tí o bá ti mọ̀ wí pé, Ọ̀run jẹ ọba. 27 Nítorí náà ọba, jẹ́ kí ìmọ̀ràn mi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ọ, kọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ sílẹ̀ kí o sì ṣe rere, àti ìwà búburú rẹ nípa ṣíṣe àánú fún àwọn tálákà. Ó lè jẹ́ pé nígbà náà ni ìwọ yóò ṣe rere.”

Kolose 2:6-15

Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nínú ẹ̀mí nínú Kristi

Nítorí náà, bí ẹ̀yin ti gba Jesu Kristi gẹ́gẹ́ bí Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin máa gbé nínú rẹ̀. Ẹ fi gbòǹgbò múlẹ̀, kí a sì gbé yín ró nínú rẹ̀, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ yín, bí a ti kọ́ yín, àti kí ẹ sì máa pọ̀ nínú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́.

Ẹ rí dájú pé ẹnikẹ́ni kò mú yin ní ìgbèkùn pẹ̀lú ẹ̀kọ́ àròsọ àti ìmọ̀ ẹ̀tàn, èyí tí ó gbára lé ìlànà ti ènìyàn àti àgbékalẹ̀ àwọn ẹ̀mí ayé yìí tí ó yàtọ̀ sí ti Kristi.

Nítorí nínú Kristi ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwàláàyè Ọlọ́run gbé ní ara, 10 (A)ẹ̀yin sì ní ohun gbogbo ní kíkún nínú Kristi, ẹni tí i ṣe orí fún gbogbo agbára àti àṣẹ. 11 Nínú ẹni tí a kò fi ìkọlà tí a fi ọwọ́ kọ kọ yín ní ilà, ni bíbọ ara ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, nínú ìkọlà Kristi. 12 Bí a ti sin yín pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìtẹ̀bọmi, tí a sì ti jí yín dìde pẹ̀lú rẹ̀ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú agbára Ọlọ́run, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú.

13 Àti ẹ̀yin, ẹni tí ó ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti àìkọlà ará yín, mo ní, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín; 14 Ó sì ti pa ìwé májẹ̀mú nì rẹ́, tí ó lòdì sí wa, tí a kọ nínú òfin, èyí tí o lòdì sí wa: òun ni ó sì ti mú kúrò lójú ọ̀nà, ó sì kàn án mọ àgbélébùú. 15 (B)Ó sì ti gba agbára kúrò lọ́wọ́ àwọn ìjọba ẹ̀mí búburú àti àwọn alágbára gbogbo, ó sì ti dójútì wọn ní gbangba, bí ó ti ń yọ̀ fún ìṣẹ́gun lórí wọn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.