Revised Common Lectionary (Complementary)
146 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Fi ìyìn fún Olúwa, ìwọ ọkàn mi.
2 Èmi yóò yin Olúwa ní gbogbo ayé mi;
Èmi yóò kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, níwọ̀n ìgbà tí mo bá wà láààyè.
3 Ẹ má ṣe ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ọmọ-aládé,
àní, ọmọ ènìyàn,
lọ́wọ́ ẹni tí kò sí ìrànlọ́wọ́.
4 Ẹ̀mí rẹ jáde lọ, ó padà sí erùpẹ̀:
Ní ọjọ́ náà gan, èrò wọn yóò di òfo:
5 Ìbùkún ni fún ẹni tí
Ọlọ́run Jakọbu ń ṣe ìrànlọ́wọ́ rẹ̀
tí ìrètí rẹ̀ wà nínú Olúwa Ọlọ́run rẹ̀.
6 Ẹni tí ó dá ọ̀run àti ayé,
òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn,
ẹni tí ó pa òtítọ́ mọ́ títí ayé.
7 Ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ni lára
tí ó fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa
Olúwa, tú àwọn oǹdè sílẹ̀ (ẹlẹ́wọ̀n)
8 Olúwa mú àwọn afọ́jú ríran,
Olúwa, gbé àwọn tí a rẹ̀ sílẹ̀ ga,
Olúwa fẹ́ràn àwọn olódodo.
9 Olúwa ń dá ààbò bo àwọn àlejò
ó sì ń dá àwọn aláìní baba àti opó sí
ṣùgbọ́n ó ba ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú jẹ́.
10 Olúwa jẹ ọba títí láé;
Ọlọ́run rẹ, ìwọ Sioni, àti fún gbogbo ìran.
Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ogún ọmọbìnrin Ṣelofehadi
36 Àwọn olórí ìdílé Gileadi, ọmọkùnrin Makiri ọmọ Manase tí ó wá láti ara ìdílé ìran Josẹfu wá, wọ́n sì sọ̀rọ̀ níwájú Mose àti àwọn olórí, àwọn ìdílé Israẹli. 2 (A)Wọ́n sọ pé, “Nígbà tí Olúwa pàṣẹ fún olúwa mi láti fi ilẹ̀ yìí fún àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí ogún nípa kèké ṣíṣẹ́. Ó pa á láṣẹ fún ọ láti fi ogún Ṣelofehadi arákùnrin wa fún àwọn ọmọbìnrin rẹ̀. 3 Wàyí, tí wọn bá fẹ́ ọkùnrin láti ẹ̀yà Israẹli mìíràn; nígbà náà a ó gba ogún un wọn kúrò nínú ogún ìran wa, a ó sì fi kún ogún ẹ̀yà tí a fẹ́ wọn sí. Bẹ́ẹ̀ ni a ó sì gbà á kúrò nínú ìpín ilẹ̀ ogún ti wa. 4 Nígbà tí ọdún ìdásílẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli bá dé, a ó pa ogún wọn pọ̀ mọ́ ẹ̀yà tí wọ́n fẹ́ wọn sí, a ó sì gba ogún ẹ̀yà wọn kúrò lọ́wọ́ baba ńlá wọn.”
5 Gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa, Mose pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli pé: “Ohun ti ẹ̀yà àwọn ìran Josẹfu ń sọ tọ̀nà. 6 Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ fún àwọn ọmọbìnrin Ṣelofehadi: Wọ́n lè fẹ́ ẹni tí ọkàn wọn fẹ́, kìkì pé wọ́n fẹ́ nínú ẹ̀yà ìdílé baba wọn. 7 Kò sí ogún kan ní Israẹli tí ó gbọdọ̀ kọjá láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà mìíràn, nítorí gbogbo ọmọ Israẹli ni yóò fi ilẹ̀ ogún ẹ̀yà tí wọ́n jogún láti ọ̀dọ̀ baba ńlá wọn pamọ́. 8 Gbogbo ọmọbìnrin tí ó bá jogún ilẹ̀ nínú ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan gbọdọ̀ fẹ́ ènìyàn nínú ẹ̀yà ìdílé baba rẹ̀, kí gbogbo ọmọ Israẹli lè ní ìpín nínú ogún baba wọn. 9 Kò sí ogún kankan tí ó gbọdọ̀ kọjá láti ẹ̀yà kan sí ẹ̀yà òmíràn, nítorí olúkúlùkù ẹ̀yà ọmọ Israẹli gbọdọ̀ tọ́jú ilẹ̀ tí ó jogún.”
10 Nígbà náà, àwọn ọmọbìnrin Ṣelofehadi ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose. 11 Nítorí pé a gbé Mahila, Tirsa, Hogla, Milka, àti Noa, àwọn ọmọbìnrin Ṣelofehadi ní ìyàwó fún àwọn ọmọ arákùnrin baba wọn. 12 Wọ́n fẹ́ ọkọ nínú ìdílé ìran Manase, ọmọ Josẹfu ogún wọn kù nínú ìdílé àti ẹ̀yà baba wọn.
13 Wọ̀nyí ni àṣẹ àti ìdájọ́ tí Olúwa ti ipasẹ̀ Mose fún àwọn ọmọ Israẹli ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu lẹ́bàá Jordani létí Jeriko.
6 Nítorí ìgbà tí àwa jẹ́ aláìlera, ní àkókò tí ó yẹ, Kristi kú fún àwa aláìwà-bí-Ọlọ́run. 7 Nítorí ó ṣọ̀wọ́n kí ẹnìkan tó kú fún olódodo: ṣùgbọ́n fún ènìyàn rere bóyá ẹlòmíràn tilẹ̀ lè dábàá láti kú. 8 (A)Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìfẹ́ òun pàápàá sí wa hàn nínú èyí pé, nígbà tí àwa jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.
9 (B)Mélòó mélòó sì ni tí a dá wa láre nísinsin yìí nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni a ó gbà wá là kúrò nínú ìbínú nípasẹ̀ rẹ̀. 10 (C)Ǹjẹ́, nígbà tí àwa wà ní ọ̀tá, a mú wa, ba Ọlọ́run làjà nípa ikú Ọmọ rẹ̀, mélòó mélòó, nígbà tí a là wá ní ìjà tan, ni a ó gbà wá là nípa ìyè rẹ̀. 11 (D)Kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n àwa ń ṣògo nínú Ọlọ́run nípa Olúwa wa Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí àwa ti rí ìlàjà gbà nísinsin yìí.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.