Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 51

Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Nígbà ti wòlíì Natani tọ wá, lẹ́yìn tí Dafidi dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè rẹ̀ pẹ̀lú Batṣeba.

51 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí
    ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ̀,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀
    kí o sì pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ́.
Wẹ gbogbo àìṣedéédéé mi nù kúrò
    kí o sì wẹ̀ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi!

Nítorí mo mọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi,
    nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi wà níwájú mi.
(A)Sí ọ, ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí
    ni mo sì ṣe búburú níwájú rẹ̀,
kí a lè dá ọ láre nígbà tí ìwọ bá ń sọ̀rọ̀,
    kí o sì le wà láìlẹ́bi, nígbà tí ìwọ bá ń ṣe ìdájọ́.
Nítòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi,
    nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi.
Nítòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú;
    ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀kọ̀.

Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé hísópù, èmi yóò sì mọ́;
    fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju yìnyín lọ.
Jẹ́ kí n gbọ́ ayọ̀ àti inú dídùn;
    jẹ́ kí gbogbo egungun tí ìwọ ti run kí ó máa yọ̀.
Pa ojú rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi
    kí o sì pa gbogbo àwọn àìṣedéédéé mi rẹ́.

10 Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run,
    kí o sì tún ẹ̀mí dídúró ṣinṣin ṣe sínú mi.
11 Má ṣe jù mi nù kúrò níwájú rẹ,
    kí o má ṣe gba ẹ̀mí mímọ́ rẹ lọ́wọ́ mi.
12 Mú ayọ̀ ìgbàlà rẹ tọ̀ mí wá,
    kí o sì fún mi ní ẹ̀mí ìfẹ́, tí yóò mú mi dúró.

13 Nígbà náà ni èmi yóò máa kọ́ àwọn olùrékọjá ní ọ̀nà rẹ,
    àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò sì yí padà sí ọ.
14 Gbà mí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, Ọlọ́run,
    ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà mi,
ahọ́n mi yóò sì máa kọrin òdodo rẹ kíkan.
15 Olúwa, ṣí mi ní ètè mi gbogbo,
    àti ẹnu mi yóò sì máa kéde ìyìn rẹ.
16 Nítorí ìwọ kò ní inú dídùn sí ẹbọ, tí èmi kò bá mú wá;
    Ìwọ kò ní inú dídùn sí ọrẹ ẹbọ sísun.
17 Ẹbọ Ọlọ́run ni ìròbìnújẹ́ ọkàn ìròbìnújẹ́ àti ìrora àyà.

18 Ṣe rere ní dídùn inú rẹ sí Sioni,
    ṣe rere; tún odi Jerusalẹmu mọ.
19 Nígbà náà ni inú rẹ yóò dùn sí ẹbọ òdodo,
    pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ọrẹ ẹbọ sísun,
    nígbà náà ni wọn yóò fi akọ màlúù rú ẹbọ lórí pẹpẹ rẹ.

Deuteronomi 28:58-29:1

58 Bí ìwọ kò bá rọra tẹ̀lé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí, tí a kọ sínú ìwé yìí, tí ìwọ kò sì bu ọlá fún ògo yìí àti orúkọ dáradára: orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ, 59 Olúwa yóò sọ ìyọnu rẹ di ìyanu, àti ìyọnu irú-ọmọ ọ̀ rẹ, àní àwọn ìyọnu ńlá èyí tí yóò pẹ́, àti ààrùn búburú èyí tí yóò pẹ́. 60 Olúwa yóò mú gbogbo ààrùn Ejibiti tí ó mú ẹ̀rù bà ọ́ wá padà bá ọ, wọn yóò sì lẹ̀ mọ́ ọ. 61 Olúwa yóò tún mú onírúurú àìsàn àti ìpọ́njú tí a kò kọ sínú Ìwé Òfin yìí wá sórí rẹ, títí ìwọ yóò fi run. 62 Ìwọ tí ó dàbí àìmoye bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò ṣẹ́ku kékeré níye, nítorí tí o kò ṣe ìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ. 63 Gẹ́gẹ́ bí ó ti dùn mọ́ Olúwa nínú láti mú ọ ṣe rere àti láti pọ̀ si ní iye, bẹ́ẹ̀ ni yóò dùn mọ́ ọ nínú láti bì ọ́ ṣubú kí ó sì pa ọ́ run. Ìwọ yóò di fífà tu kúrò lórí ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.

64 Nígbà náà ni Olúwa yóò fọ́n ọ ká láàrín gbogbo orílẹ̀-èdè, láti òpin kan ní ayé sí òmíràn. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò ti sin ọlọ́run mìíràn: ọlọ́run igi àti ti òkúta. Èyí tí ìwọ àti àwọn baba rẹ kò mọ̀. 65 Ìwọ kì yóò sinmi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè náà, kò sí ibi ìsinmi fún àtẹ́lẹsẹ̀ rẹ. Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti fún ọ ní ọkàn ìnàngà, àárẹ̀ ojú, àti àìnírètí àyà. 66 Ìwọ yóò gbé ní ìdádúró ṣinṣin, kún fún ìbẹ̀rùbojo lọ́sàn án àti lóru, bẹ́ẹ̀ kọ́ láé ni ìwọ yóò rí i ní àrídájú wíwà láyé rẹ. 67 Ìwọ yóò wí ní òwúrọ̀ pé, “Bí ó tilẹ̀ lè jẹ́ pé ìrọ̀lẹ́ nìkan ni!” Nítorí ẹ̀rù tí yóò gba ọkàn rẹ àti ìran tí ojú rẹ yóò máa rí. 68 Olúwa yóò rán ọ padà nínú ọkọ̀ sí Ejibiti sí ìrìnàjò tí mo ní ìwọ kì yóò lọ mọ́. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò tún fi ara rẹ fún àwọn ọ̀tá à rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹrúkùnrin àti ẹrúbìnrin, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò rà ọ́.

Ìsọdi tuntun májẹ̀mú

29 Èyí ni àwọn ìpinnu májẹ̀mú tí Olúwa pàṣẹ fún Mose láti ṣe pẹ̀lú àwọn ọmọ Israẹli ní Moabu, ní àfikún májẹ̀mú tí ó ti ṣe pẹ̀lú u wọn ní Horebu.

Ìṣe àwọn Aposteli 7:17-29

17 (A)“Nígbà tí àkókò tí Ọlọ́run yóò mú ìlérí tí ó ṣe fún Abrahamu ṣẹ kù sí dẹ̀dẹ̀, àwọn ènìyàn wa ń gbèrú si gidigidi ní iye ní ilẹ̀ Ejibiti. 18 Ṣùgbọ́n ọba tuntun mìíràn tí kò mọ Josẹfu jẹ ní ilẹ̀ Ejibiti. 19 (B)Òun náà ni ó ṣe àrékérekè sí àwọn ìbátan wa. Wọn sì hùwà búburú sí àwọn baba wa, tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi já àwọn ọmọ ọwọ́ wọn kúrò lọ́wọ́ wọn nítorí kí wọn má ṣe yè.

20 (C)“Ní àkókò náà ni a bí Mose, (ẹni tí ó dára ní ojú Ọlọ́run) ẹni tí ó lẹ́wà púpọ̀, tí wọn sí bọ́ lóṣù mẹ́ta ni ilé baba rẹ̀. 21 (D)Nígbà tí wọn sí gbe é sọnù, ọmọbìnrin Farao gbé e, ó sì tọ ọ́ dàgbà gẹ́gẹ́ bí ọmọ ara rẹ̀. 22 A sì kọ́ Mose ni gbogbo ọgbọ́n ara Ejibiti, ó sì pọ̀ ni ọ̀rọ̀ àti ní ìṣe.

23 (E)“Nígbà tí Mose di ọmọ ogójì ọdún, ó sọ sí i lọ́kàn láti lọ bẹ àwọn ọmọ Israẹli ará rẹ̀ wò. 24 Nígbà tí ó sì rí ọ̀kan nínú wọ́n tí ará Ejibiti kan ń jẹ́ ní ìyà, ó gbèjà rẹ̀, ó gbẹ̀san ẹni tí wọ́n jẹ ní ìyà nípa lílu ará Ejibiti náà pa: 25 Mose rò bí àwọn ará òun mọ̀ pé Ọlọ́run yóò ti ọwọ́ òun gbà wọn; ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀. 26 Ní ọjọ́ kejì Mose yọ sí àwọn ọmọ Israẹli méjì bí wọ́n ti ń jà. Òun si fẹ́ parí ìjà fún wọn. Ó wí pé, ‘Ènìyàn mi, ará ni ẹ̀yin; èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣe ohun tí kò tọ́ sí ara yín?’

27 “Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fínràn sí ẹnìkejì rẹ̀ ti Mose sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó wí pé, ‘Ta ni ó fi ọ́ jẹ olórí àti onídàájọ́ lórí wa? 28 Ṣé ìwọ fẹ́ pa mí bí o ti pa ará Ejibiti lánàá?’ 29 (F)Mose sì sá nítorí ọ̀rọ̀ yìí, ó sì wa ṣe àtìpó ni ilẹ̀ Midiani, níbi tí ó gbé bí ọmọ méjì.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.