Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi. Nígbà ti wòlíì Natani tọ wá, lẹ́yìn tí Dafidi dá ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè rẹ̀ pẹ̀lú Batṣeba.
51 Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí
ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ̀,
gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àánú rẹ̀
kí o sì pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi rẹ́.
2 Wẹ gbogbo àìṣedéédéé mi nù kúrò
kí o sì wẹ̀ mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi!
3 Nítorí mo mọ̀ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi,
nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi wà níwájú mi.
4 (A)Sí ọ, ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí
ni mo sì ṣe búburú níwájú rẹ̀,
kí a lè dá ọ láre nígbà tí ìwọ bá ń sọ̀rọ̀,
kí o sì le wà láìlẹ́bi, nígbà tí ìwọ bá ń ṣe ìdájọ́.
5 Nítòótọ́, nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni a ti bí mi,
nínú ẹ̀ṣẹ̀ ni ìyá mí sì lóyún mi.
6 Nítòótọ́ ìwọ fẹ́ òtítọ́ ní inú;
ìwọ kọ́ mi ní ọgbọ́n ní ìhà ìkọ̀kọ̀.
7 Wẹ̀ mí pẹ̀lú ewé hísópù, èmi yóò sì mọ́;
fọ̀ mí, èmi yóò sì funfun ju yìnyín lọ.
8 Jẹ́ kí n gbọ́ ayọ̀ àti inú dídùn;
jẹ́ kí gbogbo egungun tí ìwọ ti run kí ó máa yọ̀.
9 Pa ojú rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi
kí o sì pa gbogbo àwọn àìṣedéédéé mi rẹ́.
10 Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọ́run,
kí o sì tún ẹ̀mí dídúró ṣinṣin ṣe sínú mi.
11 Má ṣe jù mi nù kúrò níwájú rẹ,
kí o má ṣe gba ẹ̀mí mímọ́ rẹ lọ́wọ́ mi.
12 Mú ayọ̀ ìgbàlà rẹ tọ̀ mí wá,
kí o sì fún mi ní ẹ̀mí ìfẹ́, tí yóò mú mi dúró.
13 Nígbà náà ni èmi yóò máa kọ́ àwọn olùrékọjá ní ọ̀nà rẹ,
àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò sì yí padà sí ọ.
14 Gbà mí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, Ọlọ́run,
ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà mi,
ahọ́n mi yóò sì máa kọrin òdodo rẹ kíkan.
15 Olúwa, ṣí mi ní ètè mi gbogbo,
àti ẹnu mi yóò sì máa kéde ìyìn rẹ.
16 Nítorí ìwọ kò ní inú dídùn sí ẹbọ, tí èmi kò bá mú wá;
Ìwọ kò ní inú dídùn sí ọrẹ ẹbọ sísun.
17 Ẹbọ Ọlọ́run ni ìròbìnújẹ́ ọkàn ìròbìnújẹ́ àti ìrora àyà.
18 Ṣe rere ní dídùn inú rẹ sí Sioni,
ṣe rere; tún odi Jerusalẹmu mọ.
19 Nígbà náà ni inú rẹ yóò dùn sí ẹbọ òdodo,
pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ọrẹ ẹbọ sísun,
nígbà náà ni wọn yóò fi akọ màlúù rú ẹbọ lórí pẹpẹ rẹ.
10 Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá mú yín dé ilẹ̀ náà tí ó ti búra fún àwọn baba yín: Fún Abrahamu, Isaaki, àti Jakọbu láti fi fún un yín, Ilẹ̀ tí ó kún fún àwọn ìlú ńláńlá tí kì í ṣe ẹ̀yin ló kọ́ ọ, 11 àwọn ilé tí ó kún fún gbogbo ohun mèremère tí kì í ṣe ẹ̀yin ló rà wọ́n, àwọn kànga tí ẹ kò gbẹ́, àti àwọn ọgbà àjàrà àti èso olifi tí kì í ṣe ẹ̀yin ló gbìn wọ́n: Nígbà tí ẹ bá jẹ tí ẹ sì yó, 12 ẹ ṣọ́ra kí ẹ má ṣe gbàgbé Olúwa, tí o mú un yín jáde láti Ejibiti wá, kúrò ní oko ẹrú.
13 (A)Bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ, Òun nìkan ni kí o sì máa sìn, búra ní orúkọ rẹ̀ nìkan. 14 Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ tẹ̀lé ọlọ́run mìíràn: ọlọ́run àwọn tí ó yí i yín ká; 15 torí pé Olúwa Ọlọ́run yín tí ó wà láàrín yín, Ọlọ́run owú ni, ìbínú rẹ̀ yóò sì run yín kúrò ní ilẹ̀ náà. 16 (B)Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run yín wò bí ẹ̀yin ti dán wò ní Massa. 17 Ẹ rí i dájú pé ẹ̀ ń pa àwọn òfin Olúwa Ọlọ́run yín mọ́ àti àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà tí ó ti fún un yín. 18 Ẹ ṣe èyí tí ó dára tí ó sì tọ́ lójú Olúwa, kí ó bá à lè dára fún un yín, kí ẹ̀yin bá à lè lọ láti gba ilẹ̀ dáradára náà tí Ọlọ́run ti fi ìbúra ṣèlérí fún àwọn baba ńlá a yín. 19 Ẹ̀yin yóò sì ti àwọn ọ̀tá yín jáde níwájú u yín bí Olúwa ti ṣèlérí.
20 Ní ọjọ́ iwájú, bí ọmọ rẹ bá béèrè pé, “Kí ni ìtumọ̀ àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin wọ̀nyí tí Olúwa Ọlọ́run wa ti pàṣẹ fún ọ?” 21 Sọ fún un pé: “Ẹrú Farao ní ilẹ̀ Ejibiti ni wá tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n Olúwa fi ọwọ́ agbára ńlá yọ wá jáde lóko ẹrú Ejibiti. 22 Lójú wa ni Olúwa tí ṣe iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu: tí ó lágbára tí ó sì ba ni lẹ́rù: lórí Ejibiti àti Farao, àti gbogbo ènìyàn rẹ̀. 23 Ṣùgbọ́n ó mú wa jáde láti ibẹ̀ wá láti mú wa wọ inú àti láti fún wa ní ilẹ̀ tí ó ti fì búra fún àwọn baba ńlá wa. 24 Olúwa pàṣẹ fún wa láti ṣe ìgbọ́ràn sí gbogbo ìlànà wọ̀nyí, láti bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa, kí ó ba à lè máa dára fún wa nígbà gbogbo, kí a sì lè wà láyé, bí a ṣe wà títí di òní. 25 Bí a bá ṣọ́ra láti pa gbogbo òfin wọ̀nyí mọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa, bí ó ti pàṣẹ fún wa, èyí ni yóò máa jẹ́ òdodo wa.”
17 (A)Ẹ má ṣe fi búburú san búburú fún ẹnikẹ́ni. Ẹ má pèsè ohun tí ó tọ́ níwájú gbogbo ènìyàn. 18 (B)Bí ó bá sé é ṣe, bí ó ti wà ní ipa tiyín, ẹ má wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. 19 (C)Olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ṣùgbọ́n ẹ fi ààyè sílẹ̀ fún ìbínú Ọlọ́run; nítorí a ti kọ ọ́ pé, Olúwa wí pé, “Tèmi ni ẹ̀san, èmi ó gbẹ̀san.” 20 (D)Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀,
“Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ;
bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu.
Ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó kó ẹ̀yín iná lé e ní orí.”
21 Má ṣe jẹ́ kí búburú ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n fi rere ṣẹ́gun búburú.
Ẹ jẹ gbèsè ìfẹ́
8 (A)Ẹ má ṣe jẹ ẹnikẹ́ni nígbésè ohun kan, bí kò ṣe pé kí a fẹ́ ọmọ ẹnìkejì ẹni, nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀, ó kó òfin já. 9 (B)Àwọn òfin, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò,” bí òfin mìíràn bá sì wà, ni a papọ̀ ṣọ̀kan nínú òfin kan yìí: “Fẹ́ ẹnìkéjì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀.” 10 (C)Ìfẹ́ kì í ṣe ohun búburú sí ọmọnìkejì rẹ̀: nítorí náà ìfẹ́ ni àkójá òfin.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.