Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 119:17-24

Ohun ìyanu tí o wà nínú òfin rẹ̀

17 Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ, èmi yóò sì wà láààyè;
    èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ rẹ.
18 La ojú mi kí èmi lè ríran rí
    ohun ìyanu tí ó wà nínú òfin rẹ.
19 Àlejò ní èmi jẹ́ láyé;
    Má ṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fún mi.
20 Ọkàn mi pòruurù pẹ̀lú ìfojúsọ́nà
    nítorí òfin rẹ nígbà gbogbo.
21 Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn ún
    tí ó ṣìnà kúrò nínú àṣẹ rẹ.
22 Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi,
    nítorí èmi pa òfin rẹ mọ́.
23 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọpọ̀, wọ́n
    ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi,
    ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ rẹ.
24 Òfin rẹ ni dídùn inú mi;
    àwọn ní olùbádámọ̀ràn mi.

Eksodu 4:1-17

Àwọn ààmì fún Mose

Mose dáhùn ó sì wí pé; “Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gbà mí gbọ́ ńkọ́? Tàbí tí wọn kò fi etí sílẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi, tí wọn sì wí pé, ‘Olúwa kò farahàn ọ́’?”

Ní ìgbà náà ni Olúwa sọ fún un pé, “Kí ni ó wà ní ọwọ́ rẹ n nì?”

Ó sì dáhùn pé, “ọ̀pá ni.”

Olúwa sì sọ pé, “Sọ ọ̀pá náà sílẹ̀.”

Mose sì sọ ọ̀pá náà sílẹ̀, lọ́gán ni ọ̀pá náà di ejò, ó sì sá fún un. Nígbà náà ni Ọlọ́run wá sọ fún un pé, “na ọwọ́ rẹ, kí o sì mú un ni ìrù.” Mose sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì mu ejò náà, ejò náà sì padà di ọ̀pá tí ó wà ni ọwọ́ rẹ̀. Olúwa sì wí pé, “Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí wọn bá à le è gbàgbọ́ pé, Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn: Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu; tí farahàn ọ́.”

Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé, “Ti ọwọ́ rẹ bọ inú aṣọ ní igbá àyà rẹ̀.” Mose sì ti ọwọ́ rẹ̀ bọ inú aṣọ ní igbá àyà rẹ̀, ní ìgbà ti ó sì yọ ọ́ jáde, ọwọ́ rẹ̀ ti dẹ́tẹ̀, ó sì ti funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú.

Ó sì wí pé, “Nísinsin yìí, fi ọwọ́ náà padà sí abẹ́ aṣọ ní igbá àyà rẹ.” Mose sì ṣe bẹ́ẹ̀, ọwọ́ rẹ̀ sì padà bọ́ sípò bí àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ tókù.

Ní ìgbà náà ni Olúwa wí pé; “Bí wọn kò bá gbà ọ́ gbọ́ tàbí kọ ibi ara sí iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́, wọ́n le è ti ipasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu kejì gbàgbọ́. Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gba ààmì méjèèjì wọ̀nyí gbọ́, tí wọn kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ, bu omi díẹ̀ láti inú odò Naili kí o si dà á sí orí ìyàngbẹ ilẹ̀, omi tí ìwọ bù láti inú odò yìí yóò sì di ẹ̀jẹ̀.”

10 Mose sì sọ fún Olúwa pé, “Èmi jẹ́ akólòlò, èmi kì í ṣe ẹni tó lè sọ̀rọ̀ já gaara láti ìgbà àtijọ́ wá tàbí láti ìgbà ti o ti ń bá ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀, mo jẹ́ ẹni ti ahọ́n rẹ̀ lọ́, tí ó sì ń lọ́ra àti sọ̀rọ̀.”

11 Olúwa sì sọ fún un pé, “Ta ni ó fún ènìyàn ni ẹnu? Ta ni ó mú un ya odi tàbí adití? Ta ni ó mú un ríran, tàbí mú un fọ́jú? Ǹjẹ́ kì í ṣe Èmi Olúwa? 12 Lọ nísinsin yìí, èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀. Èmi yóò sì kọ́ ọ ni ohun ti ìwọ yóò sọ.”

13 Mose dáhùn ó wí pé, “Olúwa jọ̀wọ́ rán ẹlòmíràn láti lọ ṣe iṣẹ́ yìí.”

14 Ìbínú Ọlọ́run ru sókè sí Mose, ó sì sọ pé, “Aaroni ará Lefi arákùnrin rẹ ńkọ́? Mo mọ̀ pé ó lè sọ̀rọ̀ já gaara, ó ti wà ní ọ̀nà rẹ̀ báyìí láti pàdé e rẹ. Inú rẹ̀ yóò sì dùn ti ó bá rí ọ. 15 Ìwọ yóò sọ̀rọ̀ fún un, ìwọ yóò sì fi ọ̀rọ̀ sí i lẹ́nu: Èmi yóò ràn yín lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀. Èmi yóò kọ́ ọ yín ni ohun ti ẹ ó ṣe. 16 Òun yóò bá ọ sọ̀rọ̀ sí àwọn ènìyàn, yóò sì dàbí i pé ẹnu un rẹ ni a gbà sọ ọ̀rọ̀ náà, ìwọ yóò sì dàbí Ọlọ́run ní iwájú rẹ̀. 17 Ṣùgbọ́n mú ọ̀pá yìí ni ọwọ́ rẹ kí ìwọ bá à lè fi ṣe àwọn iṣẹ́ ààmì ìyanu pẹ̀lú rẹ̀.”

1 Peteru 2:1-10

Nítorí náà, ẹ fi àrankàn gbogbo sílẹ̀ ni apá kan, àti ẹ̀tàn gbogbo, àti àgàbàgebè, àti ìlara, àti sísọ ọ̀rọ̀ búburú gbogbo. Bí ọmọ ọwọ́ tuntun, kí ẹ máa fẹ́ wàrà ti Ẹ̀mí, èyí tí kò lẹ́tàn, kí ẹ̀yin lè máa tipasẹ̀ rẹ̀ dàgbà sí ìgbàlà, (A)nísinsin yìí tí ẹ̀yin ti tọ́ ọ wò pé rere ni Olúwa.

Àpáta iyè àti ènìyàn tí a yàn

(B)Ẹni tí ẹ̀yin ń tọ̀ bọ̀, sí bi òkúta ààyè náà, èyí ti a ti ọwọ́ ènìyàn kọ̀ sílẹ̀ nítòótọ́, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àṣàyàn òkúta iyebíye. Ẹ̀yin pẹ̀lú, bí òkúta ààyè, ni a kọ́ ní ilé ẹ̀mí, àlùfáà mímọ́, láti máa rú ẹbọ ẹ̀mí, tí i ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa Jesu Kristi. (C)Nítorí nínú Ìwé Mímọ́, ó wí pe:

“Kíyèsi i, mo fi pàtàkì òkúta igun ilé àṣàyàn,
    iyebíye, lélẹ̀ ni Sioni:
ẹni tí ó bá sì gbà á gbọ́
    ojú kì yóò tì í.”

(D)Báyìí fún ẹ̀yin ti ẹ gbà á gbọ́, ó ṣe iyebíye; ṣùgbọ́n fún àwọn tí kò gbà á gbọ́,

“Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀sílẹ̀,
    òun ni ó di pàtàkì igun ilé,”

(E)àti pẹ̀lú,

“Òkúta ìdìgbòlù,
    àti àpáta ìkọ̀sẹ̀.”

Nítorí wọ́n kọsẹ̀ nípa ṣíṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, sínú èyí tí a gbé yàn wọ́n sí pẹ̀lú.

(F)Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni ìran tí a yàn olú àlùfáà, Orílẹ̀-èdè mímọ́, Ènìyàn ọ̀tọ̀ ki ẹ̀yin lè fi ọláńlá ẹni tí ó pè yín jáde kúrò nínú òkùnkùn sínú ìmọ́lẹ̀ ìyanu rẹ̀ hàn: 10 (G)Ẹ̀yin tí kì í ṣe ènìyàn nígbà kan rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ti di ènìyàn Ọlọ́run, ẹ̀yin tí kò rí àánú gbà rí, ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ ti rí àánú gbà.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.