Revised Common Lectionary (Complementary)
9 Nítorí ìwọ fi Olúwa ṣe ààbò rẹ,
ìwọ fi Ọ̀gá-ògo ṣe ibùgbé rẹ.
10 Búburú kan ki yóò ṣubú lù ọ́
Bẹ́ẹ̀ ni ààrùnkárùn kì yóò súnmọ́ ilé rẹ.
11 (A)Nítorí yóò fi àṣẹ fún àwọn angẹli nípa tìrẹ
láti pa ọ́ mọ́ ní gbogbo ọ̀nà rẹ;
12 Wọn yóò gbé ọ sókè ní ọwọ́ wọn,
nítorí kí ìwọ má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gún òkúta.
13 (B)Ìwọ yóò rìn lórí kìnnìún àti paramọ́lẹ̀;
ìwọ yóò tẹ kìnnìún ńlá àti ejò ńlá ni ìwọ yóò fi ẹsẹ̀ tẹ̀ mọ́lẹ̀.
14 “Nítorí ti ìfẹ́ rẹ sí mi, èmi yóò gbà ọ́;
èmi yóò pa ọ́ mọ́, nítorí ìwọ jẹ́wọ́ orúkọ mi.
15 Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn;
èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìpọ́njú,
èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un
16 Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn
èmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án.”
10 Ìwọ ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìwà ìkà rẹ
ó sì ti wí pé, ‘kò sí ẹni tí ó rí mi?’
Ọgbọ́n àti òye rẹ ti ṣì ọ́ lọ́nà
nígbà tí o wí fún ara rẹ pé,
‘Èmi ni, kò sí ẹlòmíràn lẹ́yìn mi.’
11 Ìparun yóò dé bá ọ
bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò mọ ọ̀nà láti ré e kúrò.
Àjálù kan yóò ṣubú lù ọ́
tí o kì yóò le è fi ètùtù ré kúrò;
òfò kan tí o kò le faradà ni
yóò wá lójijì sí oríì rẹ.
12 “Tẹ̀síwájú nígbà náà, pẹ̀lú àfọ̀ṣẹ rẹ
àti pẹ̀lú ìwà oṣó rẹ gbogbo,
tí o ti ń ṣiṣẹ́ fún láti ìgbà èwe rẹ wá.
Bóyá o le è ṣàṣeyọrí,
bóyá o le è dá rúgúdù sílẹ̀.
13 Gbogbo ìmọ̀ràn tí o ti gbà ni
ó ti sọ ọ́ di akúrẹtẹ̀!
Jẹ́ kí àwọn awòràwọ̀ rẹ bọ́ síwájú,
Àwọn awòràwọ̀ tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀
láti oṣù dé oṣù,
jẹ́ kí wọ́n gbà ọ́ lọ́wọ́ ohun tí ó ń bọ̀ wá bá ọ.
14 Lóòótọ́ wọ́n dàbí ìṣẹ́pẹ́ igi;
iná ni yóò jó wọn dànù.
Wọn kò kúkú lè gba ara wọn là
lọ́wọ́ agbára iná náà.
Kò sí èédú láti mú ara ẹnikẹ́ni gbóná
níhìn-ín kò sí iná tí ènìyàn le jókòó tì.
15 Gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe fún ọ nìyìí
gbogbo èyí ní o tí ṣíṣẹ́ pẹ̀lú u rẹ̀
tí o sì ti ń rù kiri láti ìgbà èwe.
Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ń lọ nínú àṣìṣe rẹ̀;
kò sí ẹyọ ẹnìkan tí ó lè gbà ọ́.
24 (A)Ìjà kan sì ń bẹ láàrín wọn, ní ti ẹni tí a kà sí olórí nínú wọn. 25 (B)Ó sì wí fún wọn pé, “Àwọn ọba aláìkọlà a máa fẹlá lórí wọn: a sì máa pe àwọn aláṣẹ wọn ní olóore. 26 (C)Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba pọ̀jù nínú yín kí ó jẹ́ bí ẹni tí o kéré ju àbúrò; ẹni tí ó sì ṣe olórí, bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́. 27 Nítorí ta ni ó pọ̀jù, ẹni tí ó jókòó tí oúnjẹ, tàbí ẹni tí ó ń ṣe ìránṣẹ́. Ẹni tí ó jókòó ti oúnjẹ kọ́ bí? Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ láàrín yín bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́. 28 (D)(E)Ẹ̀yin ni àwọn tí ó ti dúró tì mí nínú ìdánwò mi. 29 (F)Mo sì yan ìjọba fún yín, gẹ́gẹ́ bí Baba mi ti yàn fún mi: 30 (G)Kí ẹ̀yin lè máa jẹ, kí ẹ̀yin sì lè máa mu lórí tábìlì mi ní ìjọba mi, kí ẹ̀yin lè jókòó lórí ìtẹ́, àti kí ẹ̀yin lè máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.