Revised Common Lectionary (Complementary)
Ti Dafidi.
26 Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa,
nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi,
mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa
Ǹjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀.
2 Wádìí mi wò, Ìwọ Olúwa, kí o sì dán mi wò,
dán àyà àti ọkàn mi wò;
3 Nítorí ìfẹ́ ẹ̀ rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi,
èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ rẹ.
4 Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìṣòótọ́,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé;
5 Èmi ti kórìíra àwùjọ àwọn ènìyàn búburú
èmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó.
6 Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ rẹ ká Olúwa.
7 Èmi yóò kọrin sókè àní orin ọpẹ́,
èmi yóò sì máa sọ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.
8 Háà Olúwa, èmí ń fẹ́ ilé rẹ níbi tí ìwọ ń gbé,
àní níbi tí ògo rẹ̀ wà.
9 Má ṣe gbá mi dànù pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,
tàbí ẹ̀mí mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ,
10 Àwọn tí ọwọ́ wọn kún fún ìwà ibi,
tí ọwọ́ ọ̀tún wọn kún fún àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
11 Ṣùgbọ́n èmi ó máa rìn nínú ìwà títọ́;
rà mí padà, kí o sì ṣàánú fún mi.
12 Ẹsẹ̀ mi dúró lórí ilẹ̀ tí ó tẹ́jú;
nínú ìjọ ńlá èmi yóò fi ìbùkún fún Olúwa.
1 Ìran ti Ọbadiah.
(A)Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí nípa Edomu.
Àwa ti gbọ́ ohùn kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá:
A sì ti rán ikọ̀ kan sí gbogbo kèfèrí láti sọ pé,
“Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a dìde ogun sí i.”
2 “Kíyèsi i, Èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrín àwọn kèfèrí;
ìwọ yóò sì di gígàn lọ́pọ̀lọpọ̀,
3 Ìgbéraga àyà rẹ ti tàn ọ́ jẹ,
ìwọ tí ń gbé inú pálapàla àpáta,
tí o sì kọ́ ibùgbé rẹ sí ibi gíga,
ìwọ wí nínú ọkàn rẹ pé,
‘ta ni yóò mú mi sọ̀kalẹ̀?’
4 Bí ìwọ tilẹ̀ gbé ara rẹ ga bí ẹyẹ idì,
bí ìwọ tilẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ rẹ sí àárín àwọn ìràwọ̀,
láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti sọ̀ ọ kalẹ̀,”
ni Olúwa wí.
5 “Bí àwọn olè tọ̀ ọ́ wá,
bí àwọn ọlọ́ṣà ní òru,
Háà! Irú ìparun wo ló dúró dè ọ́:
wọn kò ha jalè tó bí wọ́n ti fẹ́?
Bí àwọn tí ń ká èso àjàrà tọ̀ ọ́ wá,
wọn kò ha ni fi èso àjàrà díẹ̀ sílẹ̀?
6 Báwo ni a ṣe ṣe àwárí nǹkan Esau,
tí a sì wá ohun ìní ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ jáde.
7 Gbogbo àwọn ẹni ìmùlẹ̀ rẹ
ti mú ọ dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ:
Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ;
àwọn tó jẹ oúnjẹ rẹ dẹ pàkúté dè ọ́,
ṣùgbọ́n ìwọ kò ní ní òye rẹ̀.”
8 Olúwa wí pé, “Ní ọjọ́ náà,
Èmi kì yóò ha pa àwọn ọlọ́gbọ́n Edomu run,
àti àwọn amòye run kúrò ní òkè Esau?
9 A ó ṣe ẹ̀rù ba àwọn jagunjagun rẹ, Ìwọ Temani,
gbogbo àwọn tó wà ní orí òkè Esau
ní a ó gé kúrò nínú ìpànìyàn náà.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn nínú ẹ̀wù funfun
9 Lẹ́yìn náà, mo ri, sì kíyèsi i, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ẹnikẹ́ni kò lè kà, láti inú orílẹ̀-èdè gbogbo, àti ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti láti inú èdè gbogbo wá, wọn dúró níwájú ìtẹ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-Àgùntàn náà, a wọ̀ wọ́n ni aṣọ funfun, imọ̀ ọ̀pẹ si ń bẹ ni ọwọ́ wọn. 10 Wọ́n sì kígbe ní ohùn rara, wí pé:
“Ìgbàlà ni ti Ọlọ́run wá
tí o jókòó lórí ìtẹ́,
àti ti Ọ̀dọ́-àgùntàn!”
11 Gbogbo àwọn angẹli sì dúró yí ìtẹ́ náà ká, àti yí àwọn àgbà àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà ká, wọn wólẹ̀ wọn si dojúbolẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà wọ́n sì sin Ọlọ́run. 12 Wí pe:
“Àmín!
Ìbùkún, àti ògo,
àti ọgbọ́n, àti ọpẹ́, àti ọlá,
àti agbára àti ipá fún Ọlọ́run wa láé àti láéláé!
Àmín!”
13 Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà si dáhùn, ó bi mí pé, “Ta ni àwọn wọ̀nyí tí a wọ ni aṣọ funfun? Níbo ni wọn sì ti wá?”
14 (A)Mo sì wí fún un pé, “Olúwa mi, ìwọ ni o lè mọ̀.”
Ó sì wí fún mí pé, “Àwọn wọ̀nyí ni o jáde láti inú ìpọ́njú ńlá, wọ́n sì fọ aṣọ wọ́n, wọ́n sì sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùntàn náà. 15 Nítorí náà ni,
“wọn ṣe ń bẹ níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run,
tí wọn sì ń sìn ín, lọ́sàn àti lóru nínú tẹmpili rẹ̀;
ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́ náà yóò si ṣíji bò wọn.
16 (B)Ebi kì yóò pa wọn mọ́,
bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kì yóò gbẹ́ wọ́n mọ́;
bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kì yóò pa wọn
tàbí oorukóoru kan.
17 (C)Nítorí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń bẹ ni àárín ìtẹ́ náà ni yóò máa ṣe olùṣọ́-àgùntàn wọn,
‘tí yóò sì máa ṣe amọ̀nà wọn sí ibi orísun omi ìyè:’
‘Ọlọ́run yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ni ojú wọn.’ ”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.