Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Amosi 5:6-7

Ẹ wá Olúwa, ẹ̀yin yóò sì yè,
    kí ó má ba à gbilẹ̀ bí iná ní Josẹfu
a sì jó o run
    Beteli kò sì ní rí ẹni tí yóò bu omi pa á.

Ẹ̀yin tí ẹ̀ sọ òdodo di ìkorò
    tí ẹ sì gbé olódodo ṣánlẹ̀.

Amosi 5:10-15

10 Ìwọ kórìíra ẹni tí ń bá ni wí ní ẹnu ibodè
    ó sì ń pẹ̀gàn ẹni tí ń sọ òtítọ́.

11 Ìwọ ń tẹ tálákà mọ́lẹ̀
    o ń fi ipá gba ọkà lọ́wọ́ wọn
Nítorí náà, ìwọ ti fi òkúta tí a gbẹ́ kọ́lé
    ṣùgbọ́n ẹ kò sì ní gbé inú wọn
Nítòótọ́ ìwọ ti gbin ọgbà àjàrà tí ó lẹ́wà.
    Ìwọ kò ní mu wáìnì inú wọn
12 Nítorí mo mọ iye àìṣedéédéé rẹ
    mo sì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí tóbi tó.

Ìwọ ni olódodo lára, ìwọ sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀
    o sì ń fi òtítọ́ du tálákà ní ilé ẹjọ́
13 Àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò wọ̀nyí,
    nítorí búburú ni gbogbo ọjọ́.

14 Wá rere, má ṣe wá búburú
    kí ìwọ ba à le yè
Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun yóò wà pẹ̀lú rẹ.
    Òun yóò sì wà pẹ̀lú rẹ bí ìwọ ṣe wí
15 Kórìíra búburú kí o sì fẹ́ rere
    dúró ní orí òtítọ́ ní ilé ẹjọ́
bóyá Olúwa Ọlọ́run alágbára
    yóò ṣíjú àánú wo ọmọ Josẹfu tó ṣẹ́kù.

Saamu 90:12-17

12 Kọ́ wa bí a ti ń kaye ọjọ́ wa dáradára,
    kí àwa ba à lè fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n.

13 Yípadà, Olúwa! Yóò ti pẹ́ tó?
    Ṣàánú fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ.
14 Tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀ nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ,
    kí àwa kí ó lè kọrin fún ayọ̀
    kí inú wa sì dùn ní gbogbo ọjọ́.
15 Mú inú wa dùn bí ọjọ́ tí ìwọ ti pọ́n wa lójú,
    fún ọjọ́ púpọ̀ tí àwa ti rí wàhálà.
16 Jẹ́ kí a fi iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀,
    ògo rẹ̀ sí àwọn ọmọ wọn.

17 Jẹ́ kí ẹwà Olúwa Ọlọ́run wa wà lára wa;
    fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ lára wa
    bẹ́ẹ̀ ni, kí ó sì fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀.

Heberu 4:12-16

12 Nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ní agbára, ó sì mu ju idàkídà olójú méjì lọ, ó sì ń gún ni, àní títí dé pínpín ọkàn àti ẹ̀mí ní yà, àti ní oríkèé àti ọ̀rá inú egungun, òun sì ni olùmọ̀ èrò inú àti ète ọkàn. 13 Kò sí ẹ̀dá kan tí kò farahàn níwájú rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun gbogbo ni ó wà níhòhò tí a sì ṣípáyà fún ojú rẹ̀, níwájú ẹni tí àwa yóò jíyìn.

Jesu ni olórí àlùfáà tòótọ́

14 Ǹjẹ́ bí a ti ní olórí àlùfáà ńlá kan, tí ó ti la àwọn ọ̀run kọjá lọ, Jesu ọmọ Ọlọ́run, ẹ jẹ́ kí a di ìjẹ́wọ́ wa mú ṣinṣin. 15 Nítorí a kò ní olórí àlùfáà tí kò lè ṣàì ba ni kẹ́dùn nínú àìlera wa, ẹni tí a ti dánwò lọ́nà gbogbo gẹ́gẹ́ bí àwa, ṣùgbọ́n òun kò dẹ́ṣẹ̀. 16 Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a wá si ibi ìtẹ́ oore-ọ̀fẹ́ pẹ̀lú ìgboyà, kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí oore-ọ̀fẹ́ láti máa ran ni lọ́wọ́ ní àkókò tí ó wọ̀.

Marku 10:17-31

Ọ̀dọ́mọkùnrin ọlọ́rọ̀

17 (A)(B) Bí Jesu ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò rẹ, ọkùnrin kan sáré wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó sì kúnlẹ̀, ó béèrè pé, “Olùkọ́ rere, kí ni èmi yóò ṣe láti jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”

18 Jesu béèrè pé, Arákùnrin, “Èéṣe tí o fi ń pè mí ní ẹni rere? Ẹni rere kan kò sí Ọlọ́run nìkan ni ẹni rere. 19 (C)Ìwọ mọ àwọn òfin bí: Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà, ìwọ kò gbọdọ̀ jalè, ìwọ kò gbọdọ̀ purọ́, ìwọ kò gbọdọ̀ rẹ́ ọmọnìkejì jẹ, bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ.”

20 Ọkùnrin náà dáhùn pé, “Olùkọ́, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni èmi ń ṣe láti ìgbà èwe mi wá.”

21 (D)Jesu wò ó tìfẹ́tìfẹ́. Ó wí fún un pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun kan ló kù fún ọ láti ṣe, lọ nísinsin yìí, ta gbogbo nǹkan tí o ní, kí o sì pín owó náà fún àwọn aláìní ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run, sì wá, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

22 Nígbà tí ọkùnrin yìí gbọ́ èyí, ojú rẹ̀ korò, ó sì lọ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí pé ó ní ọrọ̀ púpọ̀.

23 Jesu wò ó bí ọkùnrin náà ti ń lọ. Ó yípadà, ó sì sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Àní, ohun ìṣòro ni fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run!”

24 Ọ̀rọ̀ yìí ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́nu. Jesu tún sọ fún wọn pé, “Ẹyin ọmọ yóò tí ṣòro tó fún àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ọrọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọ́run. 25 Ó rọrùn fún ìbákasẹ láti gba ojú abẹ́rẹ́ wọlé jù fún ọlọ́rọ̀ kan láti wọ ìjọba ọ̀run.”

26 Ẹnu túbọ̀ ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sí i. Wọ́n béèrè wí pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ni nínú ayé ni ó lè ní ìgbàlà?”

27 Jesu wò wọ́n, ó sì wí fún wọn pé, “Ènìyàn ní èyí kò ṣe é ṣe fún ṣùgbọ́n kì í ṣe fún Ọlọ́run, nítorí ohun gbogbo ni ṣíṣe fún Ọlọ́run.”

28 (E)Nígbà náà ni Peteru kọjú sí Jesu, ó wí pé, “Àwa ti fi ohun gbogbo sílẹ̀, a sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”

29 Jesu dáhùn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín pé, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó fi ohunkóhun sílẹ̀ bí: ilé, tàbí àwọn arákùnrin, tàbí àwọn arábìnrin, tàbí ìyá, tàbí baba, tàbí àwọn ọmọ tàbí ohun ìní nítorí mi àti nítorí ìhìnrere, 30 (F)tí a kì yóò fún padà ní ọgọọgọ́rùn-ún àwọn ilé, tàbí arákùnrin, tàbí arábìnrin, tàbí ìyá, tàbí ọmọ, tàbí ilẹ̀, àti inúnibíni pẹ̀lú. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò jẹ́ tirẹ̀ ní ayé yìí àti pé ní ayé tó ń bọ̀ yóò ní ìyè àìnípẹ̀kun. 31 (G)Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó síwájú ni yóò di ẹni ìkẹyìn, àwọn tí ó sì kẹ́yìn yóò síwájú.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.