Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Saamu ti Dafidi.
8 Olúwa, Olúwa wa,
orúkọ rẹ̀ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!
Ìwọ ti gbé ògo rẹ ga
ju àwọn ọ̀run lọ.
2 (A)Láti ẹnu ọmọ ọwọ́ àti ọmọ ọmú
ni o ti yan ìyìn nítorí àwọn ọ̀tá rẹ,
láti pa àwọn ọ̀tá àti àwọn olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.
3 Nígbà tí mo ro ọ̀run rẹ,
iṣẹ́ ìka rẹ,
òṣùpá àti ìràwọ̀,
tí ìwọ tí gbé kalẹ̀,
4 kí ni ènìyàn tí ìwọ ń rò nípa rẹ̀,
àní ọmọ ènìyàn tí ìwọ ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀?
5 Ìwọ ṣe é ní onírẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju Ọlọ́run lọ,
ìwọ sì dé e ní adé ògo àti ọlá.
6 Ìwọ mú un jẹ ọba lórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ;
ìwọ sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀:
7 àwọn agbo àgùntàn àti àwọn màlúù,
àti ẹranko igbó,
8 ẹyẹ ojú ọrun,
àti ẹja inú Òkun,
àti ohun tí ń wẹ nínú ipa Òkun.
9 Olúwa, Olúwa wa,
Orúkọ rẹ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!
Májẹ̀mú ní Beerṣeba
22 (A)Ní àkókò yìí ni ọba Abimeleki àti Fikoli, olórí ogun rẹ̀ wí fún Abrahamu pé, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣe. 23 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, fi Ọlọ́run búra fún mi, ìwọ kì yóò tàn mí àti àwọn ọmọ mi àti àwọn ìran mi, ìwọ yóò fi inú rere hàn fún mi àti orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti ṣe àtìpó, bí mo ti fihàn fún ọ pẹ̀lú.”
24 Abrahamu sì wí pé, “Èmí búra.”
25 Nígbà náà ni Abrahamu fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn fún Abimeleki nípa kànga tí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ gbà lọ́wọ́ rẹ̀. 26 Ṣùgbọ́n Abimeleki dáhùn pé, “Èmi kò mọ ẹni tí ó ṣe nǹkan yìí. Ìwọ kò sì sọ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gbọ́, bí kò ṣe lónìí.”
27 Abrahamu sì mú àgùntàn àti màlúù wá, ó sì kó wọn fún Abimeleki. Àwọn méjèèjì sì dá májẹ̀mú. 28 Abrahamu sì ya abo ọ̀dọ́-àgùntàn méje nínú agbo àgùntàn rẹ̀ sọ́tọ̀. 29 Abimeleki sì béèrè lọ́wọ́ Abrahamu pé, “Kín ni ìtumọ̀ yíyà tí ìwọ ya àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn méje wọ̀nyí sọ́tọ̀ sí.”
30 Ó dalóhùn pé “Gba àwọn abo ọ̀dọ́-àgùntàn méje wọ̀nyí lọ́wọ́ mi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé èmi ni mo gbẹ́ kànga yìí.”
31 (B)Nítorí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ náà ni Beerṣeba nítorí níbẹ̀ ni àwọn méjèèjì gbé búra.
32 Lẹ́yìn májẹ̀mú tí wọ́n dá ní Beerṣeba yìí, ni Abimeleki àti Fikoli olórí ogun rẹ̀ padà sí ilẹ̀ àwọn ará Filistini. 33 Abrahamu lọ́ igi tamariski kan sí Beerṣeba, níbẹ̀ ni ó sì pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run ayérayé. 34 Abrahamu sì gbé ilẹ̀ àwọn ará Filistini fún ọjọ́ pípẹ́.
Ìyè nípasẹ̀ ẹ̀mí
8 (A)Nítorí náà, kò sí ìdálẹ́bi nísinsin yìí fún àwọn tí ó wà nínú Kristi Jesu, àwọn tí kò rìn nípa ti ara, bí kò ṣe nípa ti Ẹ̀mí. 2 (B)Nítorí nípasẹ̀ òfin ti ẹ̀mí ìyè nínú Kristi Jesu ti sọ mí di òmìnira kúrò lọ́wọ́ òfin ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. 3 (C)Nítorí ohun tí òfin kò lè ṣe, bí ó ti jẹ aláìlera nítorí ara, Ọlọ́run rán ọmọ òun tìkára rẹ̀ ní àwòrán ara ẹ̀ṣẹ̀, ó sì di ẹ̀ṣẹ̀; àti bi ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, ó sì dá ẹ̀ṣẹ̀ lẹ́bi nínú ara, 4 (D)kí a lè mú òdodo òfin ṣẹ, nínú wa, nítorí tí àwa yé gẹ́gẹ́ bí ohun ti ara, bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ohun ti Ẹ̀mí.
5 (E)Àwọn tí ń gbe nípa ti ara, wọn a máa ronú ohun ti ara; ṣùgbọ́n àwọn ti ń gbe nípa ti Ẹ̀mí, wọn a máa ronú ohun ti Ẹ̀mí. 6 (F)Nítorí èrò ti ara ikú ni; ṣùgbọ́n èrò ti ẹ̀mí ni ìyè àti àlàáfíà. 7 Nítorí èrò ti ara ọ̀tá ni sí Ọlọ́run, nítorí kì í tẹríba fún òfin Ọlọ́run, òun kò tilẹ̀ le ṣe e. 8 (G)Ìdí nìyìí tí àwọn tí ó wà lábẹ́ àkóso ara ẹ̀ṣẹ̀, kò le è tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn.
9 (H)Ṣùgbọ́n ẹyin kò sí nínú ti ara, bí kò ṣe nínú ti Ẹ̀mí, bí ó bá ṣe pé Ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé inú yín, Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá ní Ẹ̀mí Kristi, òun kò sí nínú ẹni tirẹ̀. 10 (I)Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Kristi ń gbé inú yín síbẹ̀síbẹ̀, ara yín jẹ́ òkú nítorí ẹ̀ṣẹ̀; ṣùgbọ́n ẹ̀mí mímọ́ tí ń gbé inú yín yóò fún yín ní ìyè, nítorí ó ti fún un yín ní òdodo. 11 (J)Àti pé, bí ẹ̀mí Ọlọ́run, ẹni tí ó jí Jesu kúrò nínú òkú bá ń gbé inú yín, ẹni tí ó jí Kristi Jesu dìde kúrò nínú òkú, yóò fi ẹ̀mí rẹ̀ tí ń gbé inú yín sọ ara kíkú yín di ààyè pẹ̀lú.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.