Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin fífọn. Saamu ti Dafidi.
5 Fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, Olúwa,
kíyèsi àròyé mi.
2 Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́,
ọba mi àti Ọlọ́run mi,
nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí.
3 Ní òwúrọ̀, Olúwa, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi;
ní òwúrọ̀, èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú rẹ̀
èmi yóò sì dúró ní ìrètí.
4 Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ní inú dídùn sí búburú;
bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi kò le è bá ọ gbé.
5 Àwọn agbéraga kò le è dúró
níwájú rẹ̀.
Ìwọ kórìíra gbogbo àwọn aṣebi;
6 ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run.
Apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyàn
ni Olúwa yóò kórìíra.
7 Ṣùgbọ́n èmi, nípa títóbi àánú rẹ̀,
èmi yóò wá sínú ilé rẹ̀;
ní tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni èmi yóò tẹríba
sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀.
8 Tọ́ mi, Olúwa, nínú òdodo rẹ,
nítorí àwọn ọ̀tá mi,
mú ọ̀nà rẹ tọ́ níwájú mi.
9 (A)Kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ẹnu wọn tí a lè gbàgbọ́;
ọkàn wọn kún fún ìparun.
Ọ̀nà ọ̀fun wọn ni isà òkú tí ó ṣí sílẹ̀;
pẹ̀lú ahọ́n wọn ni wọ́n ń sọ ẹ̀tàn.
10 Dá wọn lẹ́bi Ọlọ́run!
Jẹ́ kí rìkíṣí wọn jẹ́ ìṣubú wọn.
Lé wọn jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
nítorí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.
11 Ṣùgbọ́n, jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó sádi ọ́ kí ó yọ̀;
jẹ kí wọn máa kọrin fún ayọ̀ títí.
Tan ààbò rẹ sórí wọn,
àti àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ yóò máa yọ̀ nínú rẹ.
12 Dájúdájú, Olúwa, ìwọ bùkún olódodo;
ìwọ fi ojúrere rẹ yí wọn ká bí asà.
Adé fún Joṣua
9 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé: 10 “Mú nínú ìgbèkùn, nínú àwọn Heldai, tí Tobiah, àti ti Jedaiah, tí ó ti Babeli dé, kí ìwọ sì wá ní ọjọ́ kan náà, kí o sì wọ ilé Josiah ọmọ Sefaniah lọ. 11 Kí o sì mú fàdákà àti wúrà, kí o sì fi ṣe adé púpọ̀, sì gbé wọn ka orí Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà. 12 (A)Sì sọ fún un pé: ‘Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ wí pé, wo ọkùnrin náà ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ̀ka; yóò sì yọ ẹ̀ka láti abẹ́ rẹ̀ wá, yóò si kọ́ tẹmpili Olúwa wa. 13 Òun ni yóò sì kọ́ tẹmpili Olúwa òun ni yóò sì wọ̀ ní ògo, yóò sì jókòó, yóò sì jẹ ọba lórí ìtẹ́ rẹ̀; òun ó sì jẹ́ àlùfáà lórí ìtẹ́ rẹ̀; ìmọ̀ àlàáfíà yóò sì wá láàrín àwọn méjèèjì.’ 14 Adé wọ̀nyí yóò sì wà fún Helemu àti fún Tobiah, àti fún Jedaiah, àti fún Heni ọmọ Sefaniah fún ìrántí ni tẹmpili Olúwa. 15 Àwọn tí ó jìnnà réré yóò wá láti kọ́ tẹmpili Olúwa, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti rán mi sí yín. Yóò sì rí bẹ́ẹ̀ bí ẹ̀yin yóò bá gbà ohùn Olúwa, Ọlọ́run yín gbọ́ nítòótọ́.”
Ìyìn sí Ọlọ́run fún ìrètí tó wà láààyè
3 Ìyìn yẹ Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa! Ẹni tí ó tún wa bí gẹ́gẹ́ bí àánú ńlá rẹ̀ sínú ìrètí ààyè nípa àjíǹde Jesu Kristi kúrò nínú òkú, 4 àti sínú ogún àìdíbàjẹ́, àti àìlábàwọ́n, àti èyí tí kì í ṣá, tí a ti fi pamọ́ ni ọ̀run dè yin, 5 ẹyin tí a ń pamọ́ nípa agbára Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ si ìgbàlà, tí a múra láti fihàn ní ìgbà ìkẹyìn. 6 Ẹ yọ̀ nínú èyí púpọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe nísinsin yìí fún ìgbà díẹ̀, níwọ̀n bí ó ti yẹ, a ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdánwò bá yín nínú jẹ́: 7 Àwọn wọ̀nyí sì wáyé ki ìdánwò ìgbàgbọ́ yín tí ó ni iye lórí ju wúrà, ti ń ṣègbé lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iná ni a fi ń dán an wò, lè yọrísí ìyìn àti ògo àti ọlá ni ìgbà ìfarahàn Jesu Kristi. 8 Ẹni tí ẹ̀yin fẹ́ láìrí, ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ kò rí i nísinsin yìí ẹ̀yin sì ń yọ ayọ̀ tí a kò lè fi ẹnu sọ, tí ó sì kún fún ògo; 9 ẹyin sì ń gba ìlépa ìgbàgbọ́ yín, àní ìgbàlà ọkàn yín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.