Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Deuteronomi 4:1-2

Mose pàṣẹ ìgbọ́ràn

Gbọ́ Israẹli, gbọ́ òfin àti ìlànà tí èmi yóò kọ́ ọ yín. Ẹ tẹ̀lé wọn kí ẹ ba à lè yè, kí ẹ ba à lè lọ láti gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín yóò fi fún un yín. (A)Ẹ má ṣe fi kún àwọn ohun tí mo pàṣẹ fún un yín, ẹ kò sì gbọdọ̀ yọ kúrò nínú wọn, Ṣùgbọ́n ẹ pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín tí mo fún un yín mọ́.

Deuteronomi 4:6-9

Ẹ máa kíyèsi wọn dáradára. Èyí ni yóò fi ọgbọ́n àti òye yín han àwọn orílẹ̀-èdè. Àwọn tí wọn yóò gbọ́ nípa àwọn ìlànà wọ̀nyí, tí wọn yóò sì máa wí pé, “Dájúdájú, orílẹ̀-èdè ńlá yìí kún fún ọgbọ́n àti òye.” Orílẹ̀-èdè olókìkí wo ni ọlọ́run wọn tún súnmọ́ wọn, bí Olúwa Ọlọ́run wa ti súnmọ́ wa nígbàkúgbà tí a bá ń ké pè é? Orílẹ̀-èdè wo ló tún le lókìkí láti ní àwọn ìlànà òdodo, àti òfin gẹ́gẹ́ bí àwọn òfin wọ̀nyí tí mo ń gbé kalẹ̀ fún un yín lónìí.

(A)Kìkì i kí ẹ kíyèsára, kí ẹ sì ṣọ́ra a yín gidigidi kí ẹ má ba à gbàgbé àwọn ohun tí ojú yín ti rí, kí wọn má sì ṣe sá kúrò lóókan àyà yín níwọ̀n ìgbà tí ẹ sì wà láààyè. Ẹ máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín àti àwọn ọmọ wọn tí ń bọ̀ lẹ́yìn wọn.

Saamu 15

Saamu ti Dafidi

15 Olúwa, ta ni yóò máa ṣe àtìpó nínú àgọ́ rẹ?
    Ta ni yóò máa gbé ní òkè mímọ́ rẹ?

Ẹni tí ń rìn déédé
    tí ó sì ń sọ òtítọ́,
    láti inú ọkàn rẹ̀;
tí kò fi ahọ́n rẹ̀ sọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn,
    tí kò ṣe ibi sí aládùúgbò rẹ̀
    tí kò sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ẹnìkejì rẹ̀,
ní ojú ẹni tí ènìyànkénìyàn di gígàn
    ṣùgbọ́n ó bọ̀wọ̀ fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa,
Ẹni tí ó búra sí ibi ara rẹ̀
    àní tí kò sì yípadà,
tí ó ń yá ni lówó láìsí èlé
    tí kò sì gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ lòdì sí aláìlẹ́ṣẹ̀.

Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe èyí
    ni a kì yóò mì láéláé.

Jakọbu 1:17-27

17 Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé láti òkè ni ó ti wá, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ baba ìmọ́lẹ̀ wá, lọ́dọ̀ ẹni tí kò lè yípadà gẹ́gẹ́ bí òjìji àyídà. 18 Ó pinnu láti fi ọ̀rọ̀ òtítọ́ bí wa kí àwa kí ó le jẹ́ àkọ́so nínú ohun gbogbo tí ó dá.

Gbígbọ́ àti ṣíṣe ọrọ̀ náà

19 Kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́; jẹ́ kí olúkúlùkù ènìyàn kí ó máa yára láti gbọ́, kí ó lọ́ra láti fọhùn, kí ó si lọ́ra láti bínú; 20 Nítorí ìbínú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ òdodo irú èyí tí Ọlọ́run ń fẹ́. 21 Nítorí náà, ẹ lépa láti borí gbogbo èérí àti ìwà búburú tí ó gbilẹ̀ yíká, kí ẹ sì fi ọkàn tútù gba ọ̀rọ̀ náà tí a gbìn, tí ó lè gba ọkàn yín là.

22 Ẹ má kan jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà lásán, kí ẹ má ba à ti ipa èyí tan ara yín jẹ́. Ẹ ṣe ohun tí ó sọ. 23 Nítorí bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ olùgbọ́ ọ̀rọ̀ náà tí kò sì jẹ́ olùṣe, òun dàbí ọkùnrin tí ó ń ṣàkíyèsí ojú ara rẹ̀ nínú dígí 24 Nítorí, lẹ́yìn tí ó bá ti ṣàkíyèsí ara rẹ̀, tí ó sì bá tirẹ̀ lọ, lójúkan náà òun sì gbàgbé bí òun ti rí. 25 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé, òfin òmìnira ni, tí ó sì dúró nínú rẹ̀, tí òun kò sì jẹ́ olùgbọ́ tí ń gbàgbé bí kò ṣe olùṣe rẹ̀, òun yóò jẹ́ alábùkún nínú iṣẹ́ rẹ̀.

26 Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ń sin Ọlọ́run nígbà tí kò kó ahọ́n rẹ̀ ní ìjánu, ó ń tan ọkàn ara rẹ̀ jẹ, ìsìn rẹ̀ sì jẹ́ asán. 27 Ìsìn mímọ́ àti aláìléèérí níwájú Ọlọ́run àti baba ni èyí, láti máa bojútó àwọn aláìní baba àti àwọn opó nínú ìpọ́njú wọn, àti láti pa ara rẹ̀ mọ́ láìlábàwọ́n kúrò nínú ayé.

Marku 7:1-8

Mímọ́ àti àìmọ́

(A)Àwọn Farisi sì péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti àwọn kan nínú àwọn akọ̀wé, tí ó wá láti Jerusalẹmu, wọ́n sì ṣe àkíyèsí wí pé díẹ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun, èyí yìí ni wẹ ọwọ́. (Àwọn Farisi, àti gbogbo àwọn Júù, bí wọ́n kò bá wẹ ọwọ́ wọn gidigidi, wọn kì í jẹun nítorí wọ́n ti pa òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn àgbà mọ́. (B)Nígbà tí wọ́n bá sì ti ọjà dé sílé, wọn kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan oúnjẹ àfi tí wọ́n bá bu omi wẹ ara wọn. Èyí sì jẹ́ ọ̀kan nínú ogunlọ́gọ̀ àpẹẹrẹ òfin àti ìlànà tí wọ́n ti dì mú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, bí i fífọ kọ́ọ̀bù, àwọn ìkòkò, àti kẹ́tù.)

(C)Nítorí èyí àwọn Farisi àti àwọn olùkọ́ òfin béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò tẹ̀lé àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn àgbà nítorí wọ́n fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun.”

(D)Jesu dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹyin àgàbàgebè yìí, òtítọ́ ni wòlíì Isaiah ń sọtẹ́lẹ̀ nípa tí ẹ̀yin àgàbàgebè, bí a ti kọ ọ́ pé:

“ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi ẹnu wọn bu ọlá fún mi
    ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnà sí mi.
Ìsìn wọn jẹ́ lásán,
    ìkọ́ni wọ́n jẹ́ kìkìdá òfin tí àwọn ènìyàn fi ń kọ́ni.’

Nítorí tí ẹ̀yin fi òfin Ọlọ́run sí apá kan, ẹ̀yin ń tẹ̀lé àṣà àwọn ènìyàn.”

Marku 7:14-15

14 Lẹ́yìn náà, Jesu pe ọ̀pọ̀ ènìyàn láti wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó sì wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí èyí ó yé e yín. 15 Kò sí ohunkóhun láti òde ènìyàn, tí ó wọ inú rẹ̀ lọ, tí ó lè sọ ọ́ di aláìmọ́, Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan tí ó ti inú rẹ jáde, àwọn wọ̀nyí ní ń sọ ènìyàn di aláìmọ́.

Marku 7:21-23

21 Nítorí pé láti inú ọkàn ènìyàn ni àwọn èrò búburú wọ̀nyí ti ń jáde wá: àgbèrè, olè, ìpànìyàn, panṣágà, 22 (A)ọ̀kánjúwà, odì yíyàn, ìtànjẹ, ìmọtaraẹni, ìlara, ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìgbéraga, òmùgọ̀. 23 Gbogbo àwọn nǹkan búburú wọ̀nyí ń tí inú wá, àwọn ló sì ń sọ yín di aláìmọ́.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.