Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 34:15-22

15 Ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo;
    etí i rẹ̀ sì ṣí sí ẹkún wọn.
16 Ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú;
    láti ké ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.

17 Nígbà tí olódodo bá ké fún ìrànlọ́wọ́,
    Olúwa a máa gbọ́, a sì yọ wọ́n jáde láti inú gbogbo wàhálà wọn.
18 Olúwa súnmọ́ etí ọ̀dọ̀ àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn;
    ó sì gba irú àwọn tí í ṣe oníròra ọkàn là.

19 Ìpọ́njú àwọn olódodo pọ̀,
    ṣùgbọ́n Olúwa gbà wọ́n kúrò nínú gbogbo rẹ̀.
20 Ó pa gbogbo egungun wọn mọ́;
    kò sí ọ̀kan tí ó dá nínú wọn.

21 Ibi ni ó mú ikú ìkà wá,
    àti àwọn tí ó kórìíra olódodo ni yóò jẹ̀bi.
22 Olúwa ra ọkàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ padà;
    kò sí ọ̀kan nínú àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé tí yóò jẹ̀bi.

Joṣua 22:10-20

10 Nígbà tí wọ́n wá dé Geliloti ní ẹ̀bá Jordani ní ilẹ̀ Kenaani, àwọn ẹ̀yà Reubeni, ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase mọ pẹpẹ ńlá tí ó tóbi kan ní ẹ̀bá Jordani. 11 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ pé àwọn ọmọ Reubeni, àti àwọn ọmọ Gadi àti ìlàjì ẹ̀yà Manase mọ pẹpẹ kan dojúkọ ilẹ̀ Kenaani ní Geliloti ní ẹ̀bá Jordani ní ìhà kejì àwọn ọmọ Israẹli, 12 gbogbo àjọ Israẹli péjọ ní Ṣilo láti lọ bá wọn jagun.

13 Àwọn ọmọ Israẹli rán Finehasi ọmọ Eleasari àlùfáà, sí ilẹ̀ Gileadi, sí Reubeni, sí Gadi àti sí ìdajì ẹ̀yà Manase. 14 Pẹ̀lú rẹ̀ wọ́n rán àwọn ọkùnrin olóyè mẹ́wàá, ẹnìkan fún ẹ̀yà Israẹli kọ̀ọ̀kan, olórí ọ̀kọ̀ọ̀kan tiwọn jẹ́ olórí ìdílé láàrín àwọn ọmọ Israẹli.

15 Nígbà tí wọ́n lọ sí Gileadi—sí Reubeni, Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase—wọ́n sì sọ fún wọn pé, 16 “Gbogbo àjọ ènìyàn Olúwa wí pe: ‘A fẹ́ mọ ìdí tí ẹ fi sẹ̀ sí Ọlọ́run Israẹli nípa yíyí padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ẹ sì kọ́ pẹpẹ ìṣọ̀tẹ̀ ní ìlòdì sí Olúwa? 17 Ẹ̀ṣẹ̀ Peori kò ha tó fún wa bí? Títí di òní yìí àwa kò tí ì wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àjàkálẹ̀-ààrùn ti jà láàrín ènìyàn Olúwa! 18 Ṣé ẹ tún wá ń padà kúrò lẹ́yìn Olúwa ni báyìí?

“ ‘Tí ẹ̀yin bá ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa ní òní, ní ọ̀la ní òun o bínú sí gbogbo ìpéjọpọ̀ Israẹli. 19 Bí ilẹ̀ ìní yín bá di àìmọ́, ẹ wá sí orí ilẹ̀ ìní Olúwa, ní ibi tí àgọ́ Olúwa dúró sí, kí ẹ sì pín ilẹ̀ náà pẹ̀lú wa. Ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí Olúwa tàbí sí wa nípa mímọ pẹpẹ fún ara yín, lẹ́yìn pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run wa. 20 Nígbà tí Akani ọmọ Sera ṣe àìṣòótọ́ nípa ohun ìyàsọ́tọ̀, ǹjẹ́ ìbínú kò wá sí orí gbogbo àjọ ènìyàn Israẹli nítorí rẹ̀ bí? Òun nìkan kọ́ ni ó kú fún ẹ̀ṣẹ̀ ẹ rẹ̀.’ ”

Romu 13:11-14

Ọjọ́ Olúwa fẹ́rẹ dé

11 (A)Àti èyí, bí ẹ̀yin ti mọ àkókò pé, ó ti tó wákàtí nísinsin yìí fún yín láti jí lójú orun: nítorí nísinsin yìí ni ìgbàlà wa súnmọ́ etílé ju ìgbà tí àwa ti gbàgbọ́ lọ. 12 (B)Òru bù kọjá tan, ilẹ̀ sì fẹ́rẹ mọ́: nítorí náà ẹ jẹ́ kí a bọ́ ara iṣẹ́ òkùnkùn sílẹ̀, kí a sì gbé ìhámọ́ra ìmọ́lẹ̀ wọ̀. 13 (C)Jẹ́ kí a má rin ìrìn títọ́, bí ní ọ̀sán; kì í ṣe ní ìréde òru àti ní ìmutípara, kì í ṣe ni ìwà èérí àti wọ̀bìà, kì í ṣe ní ìjà àti ìlara. 14 (D)Ṣùgbọ́n ẹ gbé Jesu Kristi Olúwa wọ̀, kí ẹ má sì pèsè fún ara, láti máa mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣẹ.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.