Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Ti Dafidi ìránṣẹ́ Olúwa
36 (A)Ìré-òfin-kọjá ènìyàn búburú
jẹ́ kí n mọ̀ nínú ọkàn mi pé;
Ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò sí
níwájú wọn.
2 Nítorí pé wọ́n pọ́n ara wọn ní ojú ara wọn
títí tí a kò fi le rí ẹ̀ṣẹ̀ wọn láti kórìíra.
3 Ọ̀rọ̀ ẹnu wọn ni ẹ̀ṣẹ̀ òhun ẹ̀tàn;
wọ́n ti fi ọgbọ́n àti ṣíṣe rere sílẹ̀;
4 Wọ́n gbìmọ̀ ìwà ìkà nígbà tí wọ́n wà lórí ibùsùn wọn:
wọ́n gba ọ̀nà tí kò dára
wọn kò sì kọ ọ̀nà ibi sílẹ̀.
5 Ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ, ìwọ Olúwa, ó ga dé ọ̀run,
òtítọ́ ọ̀ rẹ ga dé àwọsánmọ̀.
6 Òdodo rẹ dàbí àwọn òkè Ọlọ́run,
àwọn ìdájọ́ rẹ dàbí ibú ńlá;
ìwọ gba ẹranko àti ènìyàn là, Olúwa.
7 Báwo ni ìṣeun ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ rẹ ti tó! Ọlọ́run!
Kí gbogbo ọmọ ènìyàn le sá sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ rẹ.
8 Àsè ilé rẹ yóò tẹ́ wọn lọ́rùn gidigidi;
ìwọ yóò sì mú wọn mu nínú odò inú dídùn rẹ.
9 Nítorí pé pẹ̀lú rẹ ni orísun ìyè wà:
nínú ìmọ́lẹ̀ rẹ ni àwa yóò rí ìmọ́lẹ̀.
10 Mú ìṣeun ìfẹ́ ẹ̀ rẹ sí àwọn tí ó mọ̀ ọ́n
àti ìgbàlà rẹ sí àwọn tí ó ní ìdúró ṣinṣin ọkàn!
11 Má ṣe jẹ́ kí ẹsẹ̀ agbéraga kí ó wá sí orí mi,
kí o má sì jẹ́ kí ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú sí mi ní ipò.
12 Níbẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ gbé ṣubú sí:
a rẹ̀ wọ́n sílẹ̀, wọn kì yóò le è dìde!
Ìrìnàjò ẹ̀ẹ̀kejì lọ sí Ejibiti
43 Báyìí, ìyàn náà sì mú gidigidi ní ilẹ̀ náà. 2 Nígbà tí wọ́n sì ti jẹ gbogbo ọkà tí wọ́n rà ní Ejibiti tan, baba wọn wí fún wọn pé, “Ẹ padà lọ ra oúnjẹ díẹ̀ si wá fún wa.”
3 Ṣùgbọ́n Juda wí fún un pé, “Ọkùnrin náà tẹnumọ́ ọn nínú ìkìlọ̀ rẹ̀ fún wa pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò rí ojúrere mi mọ́, àyàfi bí arákùnrin yín bá bá a yín wá’. 4 Tí ìwọ yóò bá rán Benjamini arákùnrin wa lọ pẹ̀lú wa, a ó lọ ra oúnjẹ wá fún ọ. 5 Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá ni jẹ́ kí ó bá wa lọ, àwa kì yóò lọ, nítorí ọkùnrin náà sọ fún wa pé, ‘Ẹ̀yin kì yóò rí ojúrere mi mọ́ àyàfi bí arákùnrin yín bá bá a yín wá.’ ”
6 Israẹli béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ fi kó ìdààmú yìí bá mi nípa sísọ fún ọkùnrin náà wí pé ẹ ní arákùnrin mìíràn?”
7 Wọ́n dáhùn pé, “Ọkùnrin náà fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí lọ́wọ́ wa nípa ìdílé wa àti àwa fúnra wa. Ó béèrè pé, ‘Ṣe baba yín ṣì wà láààyè? Ǹjẹ́ ẹ tún ní arákùnrin mìíràn?’ A kàn dáhùn ìbéèrè rẹ̀ ni. Báwo ni a ṣe le mọ̀ pé yóò wí pé, ‘Ẹ mú arákùnrin yín wá’?”
8 Juda sì wí fún Israẹli baba rẹ̀, “Jẹ́ kí ọmọkùnrin náà lọ pẹ̀lú mi, a ó sì lọ ní kíákíá, kí àwa àti ìwọ àti àwọn ọmọ wa le yè, kí a má sì kú. 9 Èmi fúnra mi yóò ṣe onídùúró fún un, èmi ni kí o gbà pé o fi lé lọ́wọ́. Bí n kò bá sì mú un padà tọ̀ ọ́ wá, jẹ́ kí ẹ̀bi rẹ̀ kí ó jẹ́ tèmi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi níwájú rẹ. 10 Bí ó bá ṣe pé a kò fi falẹ̀ ni, àwa ìbá ti lọ, à bá sì ti padà ní ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.”
11 Nígbà náà ni Israẹli baba wọn wí fún wọn, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, èyí ni kí ẹ ṣe: Ẹ mú àwọn ohun dáradára ilẹ̀ yìí lọ́wọ́ lọ bí ẹ̀bùn fún ọkùnrin náà—ìkunra díẹ̀, oyin díẹ̀, tùràrí àti òjìá, èso pisitakio àti èso almondi 12 ìlọ́po owó méjì ni kí ẹ mú lọ́wọ́, nítorí ẹ gbọdọ̀ dá owó tí ẹ bá lẹ́nu àpò yín padà. Bóyá ẹnìkan ló ṣèèṣì fi síbẹ̀. 13 Ẹ mú arákùnrin yín lọ́wọ́ pẹ̀lú ki ẹ sì tọ arákùnrin náà lọ. 14 Kí Ọlọ́run alágbára (Eli-Ṣaddai) jẹ́ kí ẹ rí àánú gbà lọ́dọ̀ ọkùnrin náà kí ó ba à le jẹ́ kí arákùnrin yín tí ó wà lọ́hùn ún àti Benjamini padà wá pẹ̀lú yín. Ní tèmi, bí mo bá pàdánù àwọn ọmọ mi, n ó ṣọ̀fọ̀ wọn náà ni.”
15 Nítorí náà wọ́n mú àwọn ẹ̀bùn náà àti owó ìlọ́po méjì àti Benjamini, wọ́n sì yára lọ sí ilẹ̀ Ejibiti, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Josẹfu.
Yíyan àwọn méje
6 Ǹjẹ́ ní ọjọ́ wọ̀nyí, nígbà tí iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ń pọ̀ sí i, ìkùnsínú wà ní àárín àwọn Helleni tí ṣe Júù àti àwọn Heberu tí ṣe Júù, nítorí tí a gbàgbé nípa ti àwọn opó wọn nínú ìpín fún ni ojoojúmọ́. 2 Àwọn méjìlá sì pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn jọ sọ́dọ̀, wọn wí pé, “Kò yẹ kí àwa ó fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀, kí a sì máa ṣe ìránṣẹ́ tábìlì. 3 Nítorí náà, ará, ẹ wo ọkùnrin méje nínú yín, olórúkọ rere, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ọgbọ́n, tí àwa lè yàn sí iṣẹ́ yìí. 4 Ṣùgbọ́n àwa yóò dúró ṣinṣin nínú àdúrà gbígbà, àti nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ọ̀rọ̀ náà.”
5 Ọ̀rọ̀ náà sì tọ́ lójú gbogbo ìjọ; wọ́n sì yan Stefanu, ọkùnrin tí ó kún fún ìgbàgbọ́ àti fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti Filipi, àti Prokoru, àti Nikanoru, àti Timoni, àti Parimena, àti Nikolasi aláwọ̀ṣe Júù ará Antioku. 6 Ẹni tí wọ́n mú dúró níwájú àwọn Aposteli; nígbà tí wọ́n sì gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn.
7 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì gbilẹ̀, iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì pọ̀ sí i gidigidi ni Jerusalẹmu, ọ̀pọ̀ nínú ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà sí fetí sí tí ìgbàgbọ́ náà.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.