Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 81

Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti Asafu.

81 Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára wa
    Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jakọbu!
Ẹ mú orin mímọ́, kí ẹ sì mú ìlù wá,
    tẹ dùùrù dídùn pẹ̀lú ohun èlò orin mímọ́.

Ẹ fún ìpè ní oṣù tuntun
    àní nígbà tí a yàn;
ní ọjọ́ àjọ wa tí ó ní ìrònú.
Èyí ni àṣẹ fún Israẹli,
    àti òfin Ọlọ́run Jakọbu.
Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Josẹfu
    nígbà tí ó la ilẹ̀ Ejibiti já.

    Níbi tí a ti gbọ́ èdè tí kò yé wa.

Ó wí pé, “Mo gbé àjàgà kúrò ní èjìká yín,
    a tú ọwọ́ wọn sílẹ̀ kúrò nínú apẹ̀rẹ̀.
Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là,
    mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá,
    mo dán an yín wò ní odò Meriba. Sela.

“Gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi ó sì kìlọ̀ fún un yín,
    bí ìwọ bá fetí sí mi, ìwọ Israẹli.
Ẹ̀yin kì yóò ní Ọlọ́run ilẹ̀ mìíràn láàrín yín;
    ẹ̀yin kì yóò foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run àjèjì.
10 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
    ẹni tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti.
    Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un.

11 “Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kì yóò gbọ́ tèmi;
    Israẹli kò ní tẹríba fún mi.
12 Nítorí náà ni mo ṣe fi wọ́n fún ọkàn líle wọn
    láti máa rìn ní ọ̀nà ẹ̀tàn wọn.

13 “Bí àwọn ènìyàn mi yóò bá gbọ́ tèmi
    bí Israẹli yóò bá tẹ̀lé ọ̀nà mi,
14 Ní kánkán ni èmi yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn
    kí n sì yí ọwọ́ mi padà sí ọ̀tá wọn!
15 Àwọn tí ó kórìíra Olúwa yóò tẹríba níwájú rẹ̀.
    Ìjìyà wọn yóò sì pẹ́ títí láé
16 Ṣùgbọ́n a ó fi ọkà tí ó dára bọ́ ọ yín
    èmi ó tẹ́ ẹ yín lọ́rùn pẹ̀lú oyin inú àpáta.”

1 Ọba 17:1-16

Elijah kéde ọ̀dá

17 (A)Elijah ará Tiṣibi láti Tiṣbi ní Gileadi wí fún Ahabu pé, “Bí Olúwa Ọlọ́run Israẹli ti wà, ẹni tí èmi ń sìn, kì yóò sí ìrì tàbí òjò ní ọdún díẹ̀ tí ń bọ̀ bí kò ṣe nípa ọ̀rọ̀ mi.”

Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ Elijah wá pé: “Kúrò níhìn-ín, kọjú sí ìhà ìlà-oòrùn, kí o sì fi ara rẹ pamọ́ níbi odò Keriti, tí ń bẹ níwájú Jordani. Ìwọ yóò mu nínú odò náà, mo sì ti pàṣẹ fún àwọn ẹyẹ ìwò láti máa bọ́ ọ níbẹ̀.”

Bẹ́ẹ̀ ni ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ fún un. Ó sì lọ sí ẹ̀bá odò Keriti, tí ń bẹ níwájú Jordani, ó sì dúró síbẹ̀. Àwọn ẹyẹ ìwò sì mú àkàrà àti ẹran wá fún un ní òwúrọ̀, àti àkàrà àti ẹran ní alẹ́, ó sì ń mu nínú odò náà.

Elijah àti opó Sarefati

Ó sì ṣe lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, odò náà sì gbẹ nítorí kò sí òjò ní ilẹ̀ náà. (B)Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ ọ́ wá wí pé: “Lọ nísinsin yìí sí Sarefati ti Sidoni, kí o sì dúró síbẹ̀. Èmi ti pàṣẹ fún obìnrin opó kan níbẹ̀ láti máa bọ́ ọ.” 10 Bẹ́ẹ̀ ni ó sì lọ sí Sarefati. Nígbà tí ó sì dé ibodè ìlú náà, obìnrin opó kan ń ṣa igi jọ níbẹ̀. Ó sì ké sí i, ó sì béèrè pé, “Ǹjẹ́ o lè bu omi díẹ̀ fún mi wá nínú ohun èlò kí èmi kí ó lè mu?” 11 Bí ó sì ti ń lọ bù ú wá, ó ké sí i pé, “Jọ̀ ọ́, mú òkèlè oúnjẹ díẹ̀ fún mi wá lọ́wọ́ rẹ.”

12 Obìnrin opó náà sì dá a lóhùn wí pé, “Bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti wà, èmi kò ní àkàrà: bí kò ṣe ìkúnwọ́ ìyẹ̀fun nínú ìkòkò àti òróró díẹ̀ nínú kólòbó. Èmi ń ṣa igi díẹ̀ jọ láti kó lọ ilé, kí èmi kí ó sì pèsè rẹ̀ fún mi àti fún ọmọ mi, kí àwa lè jẹ ẹ́: kí a sì kú.”

13 Elijah sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù. Lọ, kí o sì ṣe gẹ́gẹ́ bí o ti wí. Ṣùgbọ́n kọ́kọ́ ṣe àkàrà kékeré kan fún mi nínú rẹ̀ ná, kí o sì mú fún mi wá, lẹ́yìn náà, kí o ṣe tìrẹ àti ti ọmọ rẹ. 14 Nítorí báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Ìkòkò ìyẹ̀fun náà kì yóò ṣófo, bẹ́ẹ̀ ni kólòbó òróró náà kì yóò gbẹ, títí di ọjọ́ tí Olúwa yóò rọ òjò sí orí ilẹ̀.’ ”

15 Ó sì lọ, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Elijah ti sọ fún un. Oúnjẹ sì wà fún Elijah àti obìnrin náà àti ilé rẹ̀ ní ojoojúmọ́. 16 Nítorí ìkòkò ìyẹ̀fun náà kò ṣófo, kólòbó òróró náà kò gbẹ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti ipa Elijah sọ.

Efesu 5:1-14

Nítorí náà, ẹ máa ṣe àfarawé Ọlọ́run bí àwọn olùfẹ́ ọmọ, (A)ẹ sì máa rìn ní ìfẹ́, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti fẹ́ wa, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún wa ní ọrẹ àti ẹbọ fún Ọlọ́run fún òórùn dídùn.

Ṣùgbọ́n àgbèrè àti gbogbo ìwà èérí, tàbí ojúkòkòrò, kí a má tilẹ̀ dárúkọ rẹ̀ láàrín yín mọ́, bí ó ti yẹ àwọn ènìyàn mímọ́; Ìbá à ṣe ìwà ọ̀bùn, àti ìṣọ̀rọ̀ òmùgọ̀, tàbí ìṣẹ̀fẹ̀ àwọn ohun tí kò tọ́; ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa dúpẹ́. Nítorí ẹ̀yin mọ èyí dájú pé, kò sí panṣágà, tàbí aláìmọ́ ènìyàn, tàbí wọ̀bìà, (tí í ṣé abọ̀rìṣà) tí yóò ni ìpín kan ni ìjọba Kristi àti Ọlọ́run. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fi ọ̀rọ̀ asán tàn yín jẹ: nítorí nípasẹ̀ nǹkan wọ̀nyí ní ìbínú Ọlọ́run fi ń bọ̀ wá sórí àwọn ọmọ aláìgbọ́ràn. Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ alájọpín pẹ̀lú wọn.

Nítorí ẹ̀yin tí jẹ́ òkùnkùn lẹ́ẹ̀kan ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin dí ìmọ́lẹ̀, nípa tí Olúwa: Ẹ máa rín gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ìmọ́lẹ̀: (Nítorí èso Ẹ̀mí ni ìṣoore, àti òdodo àti òtítọ́). 10 Ẹ sì máa wádìí ohun tí í ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa. 11 Ẹ má sì ṣe bá àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn kẹ́gbẹ́ pọ̀, ṣùgbọ́n ẹ kúkú máa bá wọn wí. 12 Nítorí ìtìjú tilẹ̀ ni láti máa sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí àwọn aláìgbọ́ràn ń ṣe ní ìkọ̀kọ̀. 13 Ṣùgbọ́n ohun gbogbo tí a tú síta ni ìmọ́lẹ̀ ń fì hàn: nítorí ohunkóhun tí ó bá fi nǹkan hàn, ìmọ́lẹ̀ ni. 14 Nítorí náà ni ó ṣe wí pé,

“Jí, ìwọ̀ ẹni tí ó sun,
    sí jíǹde kúrò nínú òkú
Kristi yóò sì fún ọ ní ìmọ́lẹ̀.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.