Revised Common Lectionary (Complementary)
111 Ẹ máa yin Olúwa.
Èmi yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi,
ní àwùjọ àwọn olóòtítọ́, àti ní ìjọ ènìyàn.
2 Iṣẹ́ Olúwa tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀.
3 Iṣẹ́ rẹ̀ ni ọláńlá àti ògo:
àti òdodo rẹ̀ dúró láéláé.
4 Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, láti máa rántí:
Olúwa ni olóore-ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú.
5 Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀:
òun ń rántí májẹ̀mú rẹ̀.
6 Ó ti fihan àwọn ènìyàn rẹ̀ agbára iṣẹ́ rẹ̀
láti fún wọn ní ilẹ̀ ìlérí ní ìní
7 Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́;
gbogbo òfin rẹ̀ sì dájú.
8 Wọ́n dúró láé àti láé,
ní òtítọ́ àti òdodo ni a ṣe wọ́n.
9 Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn rẹ̀:
ó pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ títí láé:
Mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ̀.
10 Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n:
òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀,
ìyìn rẹ̀ dúró láé.
6 Ní orí òkè yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun
yóò ti pèsè
àsè oúnjẹ àdídùn kan fún gbogbo ènìyàn
àpèjẹ ti ọtí wáìnì àtijọ́
ti ẹran tí ó dára jù àti ti ọtí wáìnì
tí ó gbámúṣé.
7 Ní orí òkè yìí ni yóò pa
aṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn,
abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀;
8 (A)Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé.
Olúwa Olódùmarè yóò sì nu gbogbo omijé nù,
kúrò ní ojú gbogbo wọn;
Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò
ní gbogbo ilẹ̀ ayé.
Olúwa ni ó ti sọ ọ́.
9 Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé,
“Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa;
àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, òun sì gbà wá là.
Èyí ni Olúwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé e,
ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.”
10 (B)Ọwọ́ Olúwa yóò sinmi lé orí òkè yìí
ṣùgbọ́n a ó tẹ Moabu mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀;
gẹ́gẹ́ bí a ti gún koríko mọ́lẹ̀ di ajílẹ̀.
35 Nígbà tí ọjọ́ sì ti bù lọ tán, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n wí fún un pé, ibi aṣálẹ̀ ni ìbí yìí, ọjọ́ sì bù lọ tán. 36 “Rán àwọn ènìyàn wọ̀nyí láti lọ sí àwọn abúlé àti ìlú láti ra oúnjẹ fún ara wọn.”
37 (A)Ṣùgbọ́n Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ fún wọn ní oúnjẹ.”
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wí fún pé, “Èyí yóò ná wa tó owó iṣẹ́ ọya oṣù mẹ́jọ, Ṣe kí a lọ fi èyí ra àkàrà fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn yìí láti jẹ.”
38 Jesu tún béèrè pé, “Ìṣù àkàrà mélòó ni ẹ̀yin ni lọ́wọ́? Ẹ lọ wò ó.”
Wọ́n padà wá jíṣẹ́ pé, “Ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì.”
39 Nígbà náà ni Jesu sọ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn náà kí a mú wọn jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ lórí koríko. 40 Lẹ́sẹ̀kan náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jókòó, ní àádọ́ta tàbí ọgọọgọ́rùn-ún. 41 (B)Nígbà tí ó sì mú ìṣù àkàrà márùn-ún àti ẹja méjì náà, ó gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run. Ó dúpẹ́ fún oúnjẹ náà, ó bù wọ́n sí wẹ́wẹ́, ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbé e kalẹ̀ síwájú àwọn ènìyàn náà àti àwọn ẹja méjì náà ni ó pín fún gbogbo wọn. 42 Gbogbo wọn sì jẹ àjẹyó. 43 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì kó agbọ̀n méjìlá tí ó kún fún àjẹkù àkàrà àti ti ẹja pẹ̀lú. 44 Àwọn tí ó sì jẹ́ àkàrà náà tó ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ọkùnrin.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.