Revised Common Lectionary (Complementary)
42 Ọkùnrin kan wá láti Baali-Ṣaliṣa, ó sì mú àkàrà àkọ́so èso, ogún ìṣù àkàrà barle, tí wọ́n dín láti ara àkọ́so èso àgbàdo, àti pẹ̀lú síírí ọkà tuntun nínú àpò rẹ̀ wá fún ènìyàn Ọlọ́run náà. Òun sì wí pé “Fún àwọn ènìyàn láti jẹ.”
43 “Báwo ni èmi yóò ṣe gbé èyí ka iwájú àwọn ọgọ́ọ̀rún (100) ènìyàn?” ìránṣẹ́ rẹ̀ béèrè.
Ṣùgbọ́n Eliṣa dá a lóhùn pé, “Gbé e fún àwọn ènìyàn láti jẹ, nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Wọn yóò jẹ yóò sì tún ṣẹ́kù’ ” 44 Nígbà náà ó gbé e ka iwájú wọn, wọ́n sì jẹ ẹ́, wọ́n sì ní èyí tó ṣẹ́kù, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa.
10 Gbogbo ohun tí ìwọ ti dá ni
yóò máa yìn ọ́ Olúwa;
àwọn ẹni mímọ́ yóò máa pòkìkí rẹ.
11 Wọn yóò sọ ògo ìjọba rẹ
wọn yóò sì sọ̀rọ̀ agbára rẹ,
12 Kí gbogbo ènìyàn le mọ iṣẹ́ agbára rẹ̀
àti ọláńlá ìjọba rẹ tí ó lógo.
13 Ìjọba rẹ ìjọba ayérayé ni,
àti ìjọba rẹ wà ní gbogbo ìrandíran.
14 Olúwa mú gbogbo àwọn tí ó ṣubú ró
ó sì gbé gbogbo àwọn tí ó tẹríba dìde.
15 Ojú gbogbo ènìyàn ń wò ọ́,
ó sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó yẹ
16 Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ
ìwọ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.
17 Olúwa jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀
àti ìfẹ́ rẹ̀ sí gbogbo ohun tí o dá.
18 Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é,
sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.
Àdúrà fún àwọn ará Efesu
14 Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń fi eékún mi kúnlẹ̀ fún Baba Olúwa wa Jesu Kristi. 15 Orúkọ ẹni tí a fi ń pe gbogbo ìdílé tí ń bẹ ni ọ̀run àti ní ayé. 16 Kí òun kí ó lè fi agbára rẹ̀ fún ẹni inú yín ní okun, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. 17 Kí Kristi lè máa gbé inú ọkàn yín nípa ìgbàgbọ́; pé bí ẹ ti ń fi gbòǹgbò múlẹ̀ tí ẹ sì ń fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìfẹ́; 18 kí ẹ̀yin lè ní agbára láti mọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́, ohun tí ìbú, àti gígùn, àti jíjìn, àti gíga ìfẹ́ Kristi jẹ́. 19 Àti láti mọ̀ ìfẹ́ Kristi yìí tí ó ta ìmọ̀ yọ, kí a lè fi gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọlọ́run kún yín.
20 Ǹjẹ́ ẹni tí o lè ṣe lọ́pọ̀lọpọ̀ ju gbogbo èyí tí a ń béèrè tàbí tí a ń rò lọ, gẹ́gẹ́ bí agbára tí ń ṣiṣẹ́ nínú wa. 21 Òun ni kí a máa fi ògo fún nínú ìjọ àti nínú Kristi Jesu láti ìrandíran gbogbo àní, ayé àìnípẹ̀kun, Àmín.
Jesu bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún
6 (A)Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jesu kọjá sí apá kejì Òkun Galili, tí í ṣe Òkun Tiberia. 2 Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, nítorí tí wọ́n rí iṣẹ́ ààmì rẹ̀ tí ó ń ṣe lára àwọn aláìsàn. 3 Jesu sì gun orí òkè lọ, níbẹ̀ ni ó sì gbé jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 4 Àjọ ìrékọjá ọdún àwọn Júù sì súnmọ́ etílé.
5 (B)Ǹjẹ́ bí Jesu ti gbé ojú rẹ̀ sókè, tí ó sì rí ọ̀pọ̀ ènìyàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wí fún Filipi pé, “Níbo ni a ó ti ra àkàrà, kí àwọn wọ̀nyí lè jẹ?” 6 Ó sì sọ èyí láti dán an wò; nítorí tí òun fúnrarẹ̀ mọ ohun tí òun ó ṣe.
7 Filipi dá a lóhùn pé, “Àkàrà igba owó idẹ kò lè tó fún wọn, bí olúkúlùkù wọn kò tilẹ̀ ní í rí ju díẹ̀ bù jẹ.”
8 (C)Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Anderu, arákùnrin Simoni Peteru wí fún un pé, 9 (D)“Ọmọdékùnrin kan ń bẹ níhìn-ín yìí, tí ó ní ìṣù àkàrà barle márùn-ún àti ẹja wẹ́wẹ́ méjì: ṣùgbọ́n kín ni ìwọ̀nyí jẹ́ láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí?”
10 Jesu sì wí pé, “Ẹ mú kí àwọn ènìyàn náà jókòó!” Koríko púpọ̀ sì wá níbẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin náà jókòó; ìwọ̀n ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ènìyàn ní iye. 11 Jesu sì mú ìṣù àkàrà náà. Nígbà tí ó sì ti dúpẹ́, ó pín wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì pín wọn fún àwọn tí ó jókòó; bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni ẹja ní ìwọ̀n bí wọ́n ti ń fẹ́.
12 Nígbà tí wọ́n sì yó, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ kó àjẹkù tí ó kù jọ, kí ohunkóhun má ṣe ṣòfò.” 13 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kó wọn jọ wọ́n sì fi àjẹkù ìṣù àkàrà barle márùn-ún náà kún agbọ̀n méjìlá, èyí tí àwọn tí ó jẹun jẹ kù.
14 (E)Nítorí náà nígbà tí àwọn ọkùnrin náà rí iṣẹ́ ààmì tí Jesu ṣe, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ èyí ni wòlíì náà tí ń bọ̀ wá sí ayé.” 15 (F)Nígbà tí Jesu sì wòye pé wọ́n ń fẹ́ wá fi agbára mú òun láti lọ fi jẹ ọba, ó tún padà lọ sórí òkè, òun nìkan.
Jesu rin lórí omi
16 (G)Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun. 17 Wọ́n sì bọ́ sínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n sì rékọjá Òkun lọ sí Kapernaumu. Ilẹ̀ sì ti ṣú, Jesu kò sì tí ì dé ọ̀dọ̀ wọn. 18 Òkun sì ń ru nítorí ẹ̀fúùfù líle tí ń fẹ́. 19 Nígbà tí wọ́n wa ọkọ̀ ojú omi tó bí ìwọ̀n ibùsọ̀ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tàbí ọgbọ̀n, wọ́n rí Jesu ń rìn lórí Òkun, ó sì súnmọ́ ọkọ̀ ojú omi náà; ẹ̀rù sì bà wọ́n. 20 Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ni; ẹ má bẹ̀rù.” 21 Nítorí náà wọ́n fi ayọ̀ gbà á sínú ọkọ̀; lójúkan náà ọkọ̀ náà sì dé ilẹ̀ ibi tí wọ́n ń lọ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.