Revised Common Lectionary (Complementary)
Ẹ̀ka òtítọ́
23 “Ègbé ni fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn tí ń tú agbo ẹran mi ká tí ó sì ń pa wọ́n run!” ni Olúwa wí. 2 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli sọ ní ti àwọn olùṣọ́-àgùntàn tí ń darí àwọn ènìyàn mi: “Nítorí tí ẹ̀yin tú agbo ẹran mi ká, tí ẹ lé wọn dànù tí ẹ̀yin kò sì bẹ̀ wọ́n wò. Èmi yóò jẹ yín ní yà nítorí nǹkan búburú tí ẹ ti ṣe,” ni Olúwa wí. 3 “Èmi Olúwa tìkára mi yóò kó ìyókù agbo ẹran mi jọ láti inú gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo ti lé wọn, Èmi yóò mú wọn padà sínú pápá oko wọn, níbẹ̀ ni wọn ó ti bí sí i, tí wọn ó sì pọ̀ sí i. 4 Èmi ó wá olùṣọ́-àgùntàn fún wọn, tí yóò darí wọn, wọn kì yóò bẹ̀rù tàbí dààmú, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan kì yóò sọnù,” ni Olúwa wí.
5 (A)“Ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí,
“tí Èmi yóò gbé ẹ̀ka òdodo dìde fún Dafidi,
ọba tí yóò lo ìjọba pẹ̀lú ọgbọ́n
tí yóò sì ṣe òdodo àti ohun tí ó yẹ lórí ilẹ̀ náà.
6 Ní ọjọ́ rẹ̀ ni a ó gba Juda là,
Israẹli yóò sì máa gbé ní aláìléwu
Èyí ni orúkọ tí a ó fi máa pè é:
Olúwa Òdodo wa.
Saamu ti Dafidi.
23 Olúwa ni Olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.
2 (A)Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù
Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́;
3 Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò
Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo
nítorí orúkọ rẹ̀.
4 Bí mo tilẹ̀ ń rìn
Láàrín àfonífojì òjìji ikú,
èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan;
nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;
ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ
wọ́n ń tù mí nínú.
5 Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi
ní ojú àwọn ọ̀tá à mi;
ìwọ ta òróró sí mi ní orí;
ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.
6 Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn
ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo,
èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwa
títí láéláé.
Ọ̀kan nínú Kristi
11 Nítorí náà ẹ rántí pé, nígbà àtijọ́ rí, ẹ̀yin tí ẹ ti jẹ́ Kèfèrí nípa ti ìbí, tí àwọn tí a ń pè ní “aláìkọlà” láti ọwọ́ àwọn tí ń pe ara wọn “akọlà” (Èyí ti a fi ọwọ́ ènìyàn ṣe sí ni ni ara)— 12 (A)Ẹ rántí pé ni àkókò náà ẹ̀yin wà láìní Kristi, ẹ jẹ́ àjèjì sí Israẹli, àti àjèjì sí àwọn májẹ̀mú ìlérí náà, láìní ìrètí, àti láìní Ọlọ́run ni ayé. 13 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí nínú Kristi Jesu ẹ̀yin tí ó ti jìnà réré nígbà àtijọ́ rí ni a mú súnmọ́ tòsí, nípa ẹ̀jẹ̀ Kristi.
14 Nítorí òun ni àlàáfíà wa, ẹni tí o ti ṣe méjèèjì ni ọ̀kan, tí ó sì ti wó ògiri ìkélé ti ìkórìíra èyí tí ń bẹ láàrín yín. 15 Ó sì ti fi òpin sí ọ̀tá náà nínú ara rẹ̀, àní sí òfin àti àṣẹ wọ̀n-ọn-nì tí ń bẹ nínú ìlànà, kí ó lè sọ àwọn méjèèjì di ẹni tuntun kan nínú ara rẹ̀, kí ó sì ṣe ìlàjà 16 àti kí ó lè mú àwọn méjèèjì bá Ọlọ́run làjà nínú ara kan nípa àgbélébùú; nípa èyí tí yóò fi pa ìṣọ̀tá náà run. 17 (B)Ó sì ti wá, ó sì ti wàásù àlàáfíà fún ẹ̀yin tí o jìnnà réré, àti àlàáfíà fún àwọn tí o súnmọ́ tòsí. 18 Nítorí nípa rẹ̀ ni àwa méjèèjì ti ni àǹfààní sọ́dọ̀ baba nípa Ẹ̀mí kan.
19 Ǹjẹ́ nítorí náà ẹ̀yin kì í ṣe àlejò àti àjèjì mọ́, ṣùgbọ́n àjùmọ̀jogún ọmọ ìbílẹ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn ará ilé Ọlọ́run; 20 a sì ń gbé yín ró lórí ìpìlẹ̀ àwọn aposteli, àti àwọn wòlíì, pẹ̀lú Jesu Kristi fúnrarẹ̀ gẹ́gẹ́ bí pàtàkì òkúta igun ilé; 21 Nínú rẹ ni gbogbo ilé náà, tí a ń kọ wà papọ̀ ṣọ̀kan tí ó sì ń dàgbàsókè láti di tẹmpili mímọ́ kan nínú Olúwa: 22 Nínú rẹ̀ ni a ń gbé ẹ̀yin pẹ̀lú ró pẹ̀lú fún ibùjókòó Ọlọ́run nínú Ẹ̀mí rẹ̀.
Jesu bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ènìyàn
30 (A)Àwọn aposteli kó ara wọn jọ sí ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n sí ròyìn ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe àti ohun gbogbo tí wọ́n ti kọ́ni. 31 Nígbà tí Jesu rí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń lọ tí wọ́n sì ń bọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ààyè fún wọn láti jẹun, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí a kúrò láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí fún ìgbà díẹ̀, kí a sì sinmi.”
32 (B)Nítorí náà, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibi tí ó parọ́rọ́. 33 Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ènìyàn ni o rí wọn nígbà tí wọ́n ń lọ. Àwọn wọ̀nyí sì tún wá láti ìlú ńlá gbogbo wọn sáré gba etí Òkun, wọ́n ṣáájú wọn gúnlẹ̀ ní èbúté. 34 (C)Bí Jesu ti ń sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀ náà, ó bá ọ̀pọ̀ ènìyàn bí i tí àtẹ̀yìnwá, tí wọ́n ti ń dúró dè e. Ó káàánú fún wọn, nítorí wọ́n dàbí àgùntàn tí kò ní olùtọ́jú. Ó sì kọ́ wọn ni ọ̀pọ̀ nǹkan tí ó yẹ kí wọ́n mọ̀.
53 (A)Lẹ́yìn tí wọ́n la Òkun náà kọjá, wọ́n gúnlẹ̀ sí Genesareti. Wọ́n sì so ọkọ̀ sí èbúté. 54 Wọ́n jáde kúrò nínú ọkọ̀. Àwọn ènìyàn tó wà níbẹ̀ rí Jesu, wọ́n sì dá a mọ̀ ọ́n. 55 Wéré, wọ́n ròyìn dídé rẹ̀, gbogbo àwọn ènìyàn sáré gbé gbogbo àwọn aláìsàn lórí àkéte wọn wá pàdé rẹ̀. 56 (B)Ní ibi gbogbo tí ó sì dé, yálà ní abúlé, ìlú ńlá tàbí àrọ́ko, ń ṣe ni wọ́n ń kó àwọn aláìsàn pàdé rẹ̀ ní àárín ọjà. Wọ́n sì ń bẹ̀ ẹ́ kí ó jẹ́ kí wọn fi ọwọ́ kan etí aṣọ rẹ̀, gbogbo àwọn tí wọ́n sì fi ọwọ́ kàn án ni a mú láradá.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.