Revised Common Lectionary (Complementary)
Wíwá àlàáfíà
81 Ọkàn mi ń fojú ṣọ́nà nítorí ìgbàlà rẹ,
ṣùgbọ́n èmi ti fi ìrètí mi sínú ọ̀rọ̀ rẹ.
82 Ojú mi kùnà, pẹ̀lú wíwo ìpinnu rẹ;
èmi wí pé, “Nígbà wo ni ìwọ yóò tù mí nínú?”
83 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi dàbí awọ-wáìnì lójú èéfín,
èmi kò gbàgbé ìlànà rẹ.
84 Báwo ni ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò ṣe dúró pẹ́ tó?
Nígbà wo ni ìwọ yóò bá àwọn
tí ń ṣe inúnibíni sí mi wí?
85 Àwọn agbéraga wa ihò ìṣubú fún mi,
tí ó lòdì sí òfin rẹ.
86 Gbogbo àṣẹ rẹ yẹ ní ìgbẹ́kẹ̀lé:
ràn mí lọ́wọ́, nítorí ènìyàn
ń ṣe inúnibíni sí mi láìnídìí.
87 Wọ́n fẹ́rẹ pa mí rẹ́ kúrò nínú ayé,
ṣùgbọ́n èmi kò kọ ẹ̀kọ́ rẹ.
88 Pa ayé mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ,
èmi yóò sì gba ẹ̀rí ẹnu rẹ̀ gbọ́.
14 “Nítorí náà, ọjọ́ náà ń bọ̀ wá,” ni Olúwa wí, “tí àwọn ènìyàn kò ní sọ pé, ‘Dájúdájú Olúwa wà láààyè Olúwa ń bẹ Ẹni tí ó mú Israẹli jáde kúrò ní Ejibiti.’ 15 Ṣùgbọ́n wọn yóò sọ wí pé, ‘Bí Olúwa ṣe wà nítòótọ́ tí ó mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ àríwá àti ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó ti lé wọn.’ Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò dá wọn padà sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn.
16 “Ṣùgbọ́n báyìí, Èmi yóò ránṣẹ́ sí àwọn apẹja púpọ̀,” ni Olúwa wí. “Wọn ó sì dẹ wọ́n lẹ́yìn èyí yìí èmi yóò ránṣẹ́ sí àwọn ọdẹ púpọ̀, wọn yóò dẹ wọ́n lórí gbogbo òkè ńlá àti òkè gíga, àti ní gbogbo pálapàla àpáta. 17 Ojú mi wà ní gbogbo ọ̀nà wọn, wọn kò pamọ́ fún mi bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò fi ara sin lójú mi. 18 Èmi yóò san ẹ̀san ìwà búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún wọn ní ìlọ́po méjì, nítorí wọ́n ti ba ilẹ̀ mi jẹ́ pẹ̀lú àwọn ère wọn aláìlẹ́mìí, wọ́n sì fi òkú àti ohun ẹ̀gbin àti ìríra wọn kún ilẹ̀ ìní mi.”
19 Olúwa, alágbára àti okun mi,
ẹni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú
Háà! àwọn orílẹ̀-èdè yóò wá láti
òpin ayé wí pé,
“Àwọn baba ńlá wa kò ní ohun kan bí kò ṣe ẹ̀gbin òrìṣà,
ìríra tí kò dára fún wọn nínú rẹ̀.
20 Ṣé àwọn ènìyàn lè dá Ọlọ́run
fún ara wọn bí? Bẹ́ẹ̀ ni,
ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí kì í ṣe Ọlọ́run.”
21 “Nítorí náà, Èmi yóò kọ́ wọn ní
àkókò yìí, Èmi yóò kọ́ wọn pẹ̀lú
agbára àti títóbi mi; nígbà
náà ni wọn ó mọ orúkọ mi
ní Olúwa.
Jesu lọ sí àjọ ìpàgọ́
7 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí Jesu ń rìn ní Galili: nítorí tí kò fẹ́ rìn ní Judea, nítorí àwọn Júù ń wá a láti pa. 2 (A)Àjọ àwọn Júù tí í ṣe àjọ àgọ́ súnmọ́ etílé tan. 3 (B)Nítorí náà, àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, “Lọ kúrò níhìn-ín-yìí, kí o sì lọ sí Judea, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ pẹ̀lú lè fi iṣẹ́ rẹ hàn fún aráyé. 4 Nítorí pé kò sí ẹnikẹ́ni tí í ṣe ohunkóhun níkọ̀kọ̀, tí òun tìkára rẹ̀ sì ń fẹ́ kí a mọ òun ní gbangba. Bí ìwọ bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, fi ara rẹ hàn fún aráyé.” 5 Nítorí pé àwọn arákùnrin rẹ̀ pàápàá kò tilẹ̀ gbà á gbọ́.
6 (C)Nítorí náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Àkókò gan an fún mi kò tí ì dé; fún ẹ̀yin, gbogbo àkókò ni ó dára fún yín. 7 (D)Ayé kò lè kórìíra yín; ṣùgbọ́n èmi ni ó kórìíra, nítorí tí mo jẹ́rìí gbé é pé, iṣẹ́ rẹ̀ burú. 8 Ẹ̀yin ẹ gòkè lọ sí àjọ yìí: èmi kì yóò tí ì gòkè lọ sí àjọ yìí; nítorí tí àkókò mi kò ì tí ì dé.” 9 Nígbà tí ó ti sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn tan, ó dúró ní Galili síbẹ̀.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.