Revised Common Lectionary (Complementary)
Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora. Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti mahalati leannoti. Maskili ti Hemani ará Esra.
88 Olúwa, Ọlọ́run tí ó gbà mí là,
ní ọ̀sán àti ní òru ni mo kígbe sókè sí Ọ.
2 Jẹ́ kí àdúrà mi kí ó wá sí iwájú rẹ;
dẹ etí rẹ sí igbe mi.
3 Nítorí ọkàn mi kún fún ìpọ́njú
ọkàn mi sì súnmọ́ isà òkú.
4 A kà mí mọ́ àwọn tí wọ́n lọ sí ọ̀gbun ilẹ̀
èmi dàbí ọkùnrin tí kò ni agbára.
5 A yà mí sọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn òkú
bí ẹni tí a pa tí ó dùbúlẹ̀ ní ipò ikú,
ẹni tí ìwọ kò rántí mọ́,
ẹni tí a gé kúrò lára àwọn tí ìwọ ń tọ́jú.
6 Ìwọ tí ó fi mí sí kòtò jíjìn,
ní ibi ọ̀gbun tó ṣókùnkùn.
7 Ìbínú rẹ ṣubú lé mi gidigidi;
ìwọ ti fi àwọn ìjì rẹ borí mi.
8 Ìwọ tí gba ọ̀rẹ́ mi tí ó súnmọ́ mi kúrò lọ́wọ́ mi
ìwọ sì sọ mi di ìríra sí wọn.
A há mi mọ́, èmi kò sì le è jáde;
9 Ojú mi káàánú nítorí ìpọ́njú.
Mo kígbe pè ọ́, Olúwa, ní gbogbo ọjọ́;
mo na ọwọ́ mi jáde sí ọ.
10 Ìwọ ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ hàn fún òkú bi?
Àwọn òkú yóò ha dìde láti yìn ọ́ bí?
11 A ó ha fi ìṣeun ìfẹ́ rẹ hàn ní ibojì bí:
Tàbí òtítọ́ rẹ ní ipò ìparun?
12 A ha lè mọ iṣẹ́ ìyanu rẹ ní òkùnkùn bí
àti òdodo rẹ ní ilẹ̀ ìgbàgbé?
13 Ṣùgbọ́n mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa;
ní òwúrọ̀ ni àdúrà mí wá sọ́dọ̀ rẹ.
14 Olúwa, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí
tí ìwọ fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?
15 Láti ìgbà èwe mi, ìṣẹ́ ń ṣẹ́ mi,
èmi múra àti kú;
nígbà tí ẹ̀rù rẹ bá ń bà mí,
èmi di gbére-gbère
16 Ìbínú rẹ ti kọjá lára mi;
ìbẹ̀rù rẹ ti gé mi kúrò
17 Ní gbogbo ọjọ́ ni wọn yí mi ká bí ìkún omi;
wọ́n mù mí pátápátá.
18 Ìwọ ti mú ọ̀rẹ́ àti olùfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi;
òkùnkùn sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi.
Àìsàn Hesekiah
20 (A)Ní ayé ìgbà wọ̀n-ọn-nì Hesekiah ṣe àìsàn ó sì wà ní ojú ikú. Wòlíì Isaiah ọmọ Amosi lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: tún ilé rẹ ṣe, ṣùgbọ́n ìwọ yóò kú; o kò ní í gbádùn.”
2 Hesekiah yí ojú rẹ̀ padà sí ògiri ó sì gbàdúrà sí Olúwa pé, 3 “Rántí, Olúwa mi, bí èmi ṣe rìn níwájú rẹ àti pẹ̀lú bí èmi ṣe jẹ́ olóòtítọ́ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn ìfọkànsìn mi tí èmi sì ti ṣe ohun tí ó dára níwájú rẹ.” Hesekiah sọkún kíkorò.
4 Kí ó tó di wí pé Isaiah jáde kúrò ní àárín àgbàlá ààfin, ọ̀rọ̀ Olúwa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé. 5 “Lọ padà kí o sì sọ fún Hesekiah, olórí àwọn ènìyàn mi pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run baba rẹ Dafidi sọ: Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ: Èmi yóò wò ọ́ sàn. Ní ọjọ́ kẹta láti ìsinsin yìí, ìwọ yóò lọ sókè ilé tí a kọ́ fún Olúwa. 6 Èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kún ọjọ́ ayé rẹ. Èmi yóò sì gbà ọ́ àti ìlú ńlá yìí láti ọwọ́ ọba Asiria. Èmi yóò sì dáàbò bo ìlú yìí nítorí ti èmi tìkára mi àti nítorí ti Dafidi ìránṣẹ́ mi.’ ”
7 Nígbà náà ni Isaiah wí pé, “Mú odidi ọ̀pọ̀tọ́.” Wọ́n sì mú un, wọ́n sì fi lé oówo náà, ara rẹ̀ sì yá.
8 Hesekiah sì béèrè lọ́wọ́ Isaiah pé, “Kí ni yóò jẹ́ ààmì pé Olúwa yóò wò mí sàn àti wí pé èmi yóò lọ sókè sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa láti ọjọ́ kẹta títí di òní?”
9 Isaiah dáhùn pé, “Èyí ni ààmì tí Olúwa fún ọ wí pé Olúwa yóò ṣe ohun tí ó ti ṣe ìlérí: kí òjìji lọ síwájú ìgbésẹ̀ mẹ́wàá, tàbí kí ó padà lọ ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá?”
10 “Ó jẹ́ ohun ìrọ̀rùn fún òjìji láti lọ síwájú ìgbésẹ̀ mẹ́wàá,” Hesekiah wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí ó lọ padà ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá.”
11 Nígbà náà wòlíì Isaiah ké pe Olúwa, Olúwa sì ṣe òjìji padà sí ìgbésẹ̀ mẹ́wàá ó ti sọ̀kalẹ̀ ní òpópó ọ̀nà Ahasi.
Ìwòsàn ọmọkùnrin ẹlẹ́mìí èṣù
14 (A)Nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ pátápátá sí ẹsẹ̀ òkè náà, wọ́n bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí wọ́n yí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́sàn-án ìyókù ká. Àwọn olùkọ́ òfin díẹ̀ sì ń bá wọn jiyàn. 15 Bí Jesu ti ń súnmọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í wò ó pẹ̀lú ìbẹ̀rù, nígbà náà ni wọ́n sáré lọ kí i.
16 Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ló fa àríyànjiyàn?”
17 Ọkùnrin kan láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn dáhùn pé, “Olùkọ́, èmi ni mo mú ọmọ yìí wá fún ọ láti wò ó sàn. Kò lè sọ̀rọ̀ rárá, nítorí tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́. 18 Àti pé, nígbàkúgbà tí ó bá mú un, á gbé e ṣánlẹ̀, a sì máa hó itọ́ lẹ́nu, a sì máa lọ́ eyín rẹ̀. Òun pàápàá a wá le gbàgìdì. Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kí wọn lé ẹ̀mí àìmọ́ náà jáde, ṣùgbọ́n wọ́n kò lè ṣe é.”
19 Ó sì dá wọn lóhùn, ó wí pé, “Ẹ̀yin ìran aláìgbàgbọ́ yìí, Èmi yóò ti bá a yín gbé pẹ́ tó? Èmi yóò sì ti mú sùúrù fún un yín pẹ́ tó? Ẹ mú ọmọ náà wá sọ́dọ̀ mi.”
20 Wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ rẹ̀: nígbà tí ó sì rí i, lójúkan náà ẹ̀mí náà nà án tàntàn ó sì ṣubú lu ilẹ̀, ó sì ń fi ara yílẹ̀, ó sì ń yọ ìfófó lẹ́nu.
21 Jesu béèrè lọ́wọ́ baba ọmọ náà pé, “Ó tó ìgbà wo tí ọmọ rẹ̀ ti wà nínú irú ipò báyìí?”
Baba ọmọ náà dáhùn pé, “Láti kékeré ni.” 22 Nígbàkúgbà ni ó sì máa ń gbé e sínú iná àti sínú omi, láti pa á run, ṣùgbọ́n bí ìwọ bá lè ṣe ohunkóhun, ṣàánú fún wa, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.
23 (B)“Jesu sì wí fún un pé, ‘Bí ìwọ bá le gbàgbọ́: ohun gbogbo ni ó ṣe é ṣe fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́.’ ”
24 Lójúkan náà baba ọmọ náà kígbe ní ohùn rara, ó sì wí pé, “Olúwa, mo gbàgbọ́, ran àìgbàgbọ́ mi lọ́wọ́.”
25 Nígbà tí Jesu rí i pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ń péjọ sọ́dọ̀ wọn, ó bá ẹ̀mí àìmọ́ náà wí pé, “Ìwọ ẹ̀mí àìmọ́, adití àti odi, mo pàṣẹ fún ọ, kí ó jáde kúrò lára ọmọ yìí, kí ó má ṣe padà sí ibẹ̀ mọ́.”
26 Òun sì kígbe ńlá, ó sì nà án tàntàn, ó sì jáde kúrò lára rẹ̀: ọmọ náà sì dàbí ẹni tí ó kú tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ké wí pé, “Hé è, ọmọ náà ti kú.” 27 Ṣùgbọ́n Jesu fà á lọ́wọ́, ó sì ràn án lọ́wọ́ láti dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀. Ó dìde dúró.
28 Nígbà tí ó sì wọ ilé, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bi í léèrè níkọ̀kọ̀ wí pé, “Èéṣe tí àwa kò fi lè lé e jáde?”
29 Ó sì wí fún wọn pé, “Irú èyí kò le ti ipa ohun kan jáde, bí kò ṣe nípa àdúrà.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.