Revised Common Lectionary (Complementary)
Orin. Saamu ti àwọn ọmọ Kora. Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti mahalati leannoti. Maskili ti Hemani ará Esra.
88 Olúwa, Ọlọ́run tí ó gbà mí là,
ní ọ̀sán àti ní òru ni mo kígbe sókè sí Ọ.
2 Jẹ́ kí àdúrà mi kí ó wá sí iwájú rẹ;
dẹ etí rẹ sí igbe mi.
3 Nítorí ọkàn mi kún fún ìpọ́njú
ọkàn mi sì súnmọ́ isà òkú.
4 A kà mí mọ́ àwọn tí wọ́n lọ sí ọ̀gbun ilẹ̀
èmi dàbí ọkùnrin tí kò ni agbára.
5 A yà mí sọ́tọ̀ pẹ̀lú àwọn òkú
bí ẹni tí a pa tí ó dùbúlẹ̀ ní ipò ikú,
ẹni tí ìwọ kò rántí mọ́,
ẹni tí a gé kúrò lára àwọn tí ìwọ ń tọ́jú.
6 Ìwọ tí ó fi mí sí kòtò jíjìn,
ní ibi ọ̀gbun tó ṣókùnkùn.
7 Ìbínú rẹ ṣubú lé mi gidigidi;
ìwọ ti fi àwọn ìjì rẹ borí mi.
8 Ìwọ tí gba ọ̀rẹ́ mi tí ó súnmọ́ mi kúrò lọ́wọ́ mi
ìwọ sì sọ mi di ìríra sí wọn.
A há mi mọ́, èmi kò sì le è jáde;
9 Ojú mi káàánú nítorí ìpọ́njú.
Mo kígbe pè ọ́, Olúwa, ní gbogbo ọjọ́;
mo na ọwọ́ mi jáde sí ọ.
10 Ìwọ ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ hàn fún òkú bi?
Àwọn òkú yóò ha dìde láti yìn ọ́ bí?
11 A ó ha fi ìṣeun ìfẹ́ rẹ hàn ní ibojì bí:
Tàbí òtítọ́ rẹ ní ipò ìparun?
12 A ha lè mọ iṣẹ́ ìyanu rẹ ní òkùnkùn bí
àti òdodo rẹ ní ilẹ̀ ìgbàgbé?
13 Ṣùgbọ́n mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa;
ní òwúrọ̀ ni àdúrà mí wá sọ́dọ̀ rẹ.
14 Olúwa, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí
tí ìwọ fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?
15 Láti ìgbà èwe mi, ìṣẹ́ ń ṣẹ́ mi,
èmi múra àti kú;
nígbà tí ẹ̀rù rẹ bá ń bà mí,
èmi di gbére-gbère
16 Ìbínú rẹ ti kọjá lára mi;
ìbẹ̀rù rẹ ti gé mi kúrò
17 Ní gbogbo ọjọ́ ni wọn yí mi ká bí ìkún omi;
wọ́n mù mí pátápátá.
18 Ìwọ ti mú ọ̀rẹ́ àti olùfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi;
òkùnkùn sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi.
Òfin fún àwọn àlùfáà
21 (A)Olúwa sọ fún Mose wí pe, “Bá àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Aaroni sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé: ‘Ẹnikẹ́ni nínú wọn kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nítorí àwọn ènìyàn wọn tí ó kù. 2 Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe àwọn tí ó súnmọ́ ọn bí ìyá rẹ̀, baba rẹ̀, ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin, àti arákùnrin rẹ̀. 3 Tàbí fún arábìnrin rẹ̀ tí kò ì tí ì wọ ilé ọkọ tí ó ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí tí arábìnrin bẹ́ẹ̀, ó lè sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́. 4 Nítorí tí ó jẹ́ olórí, òun kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ ba ara rẹ̀ jẹ́ láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
5 (B)“ ‘Àlùfáà kò gbọdọ̀ fá irun orí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ rẹ́ irùngbọ̀n rẹ̀. Kò gbọdọ̀ fi abẹ ya ara rẹ̀ láti fihàn pé òun wà ní ipò ọ̀fọ̀. 6 Wọ́n gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún Ọlọ́run, kí wọ́n má ba à sọ orúkọ Ọlọ́run wọn di àìmọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń fi iná sun ẹbọ sí Olúwa wọn, ti ó jẹ oúnjẹ Ọlọ́run wọn. Nítorí náà wọn gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́.
7 “ ‘Àwọn àlùfáà kò gbọdọ̀ fẹ́ panṣágà tàbí obìnrin tí ó ti fi ọkùnrin ba ara rẹ̀ jẹ́ tàbí obìnrin tí ọkọ rẹ̀ ti kọ̀sílẹ̀ nítorí pé àwọn àlùfáà jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run wọn. 8 Àwọn ènìyàn gbọdọ̀ máa kà wọ́n sí mímọ́, nítorí pé àwọn ni wọ́n ń rú ẹbọ oúnjẹ fún mi. Èmi ni Olúwa, mo jẹ́ mímọ́, mo sì ya àwọn ènìyàn mi sí mímọ́.
9 “ ‘Bí ọmọbìnrin àlùfáà kan bá fi iṣẹ́ àgbèrè ba ara rẹ̀ jẹ́: ó dójútì baba rẹ̀, iná ni a ó dá sun ún.
10 “ ‘Lẹ́yìn tí a ti fi òróró yan olórí àlùfáà láàrín àwọn arákùnrin rẹ̀, tí a sì ti fi ààmì òróró yàn án láti máa wọ aṣọ àlùfáà, ó gbọdọ̀ tọ́jú irun orí rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ fa aṣọ rẹ̀ ya láti fihàn pé òun wà ní ipò ọ̀fọ̀. 11 Kí ó ma ṣe wọlé tọ òkú lọ, kí ó má ṣe sọ ará rẹ di àìmọ́ nítorí baba tàbí nítorí ìyá rẹ̀. 12 Kò gbọdọ̀ kúrò ní ibi mímọ́ Ọlọ́run tàbí kí ó sọ ọ́ di aláìmọ́ torí pé a ti fi ìfòróróyàn Ọlọ́run yà á sí mímọ́. Èmi ni Olúwa.
13 “ ‘Ọmọbìnrin tí yóò fẹ́ gbọdọ̀ jẹ́ ẹni tí kò mọ Ọkùnrin rí. 14 Kò gbọdọ̀ fẹ́ opó tàbí ẹni tí a kọ̀sílẹ̀ tàbí obìnrin tí ó ti fi àgbèrè ba ara rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n kí ó fẹ́ obìnrin tí kò mọ ọkùnrin rí, láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀. 15 Kí ó má ba à sọ di aláìmọ́ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀. Èmi ni Olúwa tí ó sọ ọ́ di mímọ́.’ ”
A rán Titu sí Kọrinti
16 Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ní fún Ọlọ́run ẹni tí ó fi ìtara àníyàn kan náà yìí sí ọkàn Titu fún yín. 17 Nítorí kì í ṣe pé òun gba ọ̀rọ̀ ìyànjú wa nìkan ni; ṣùgbọ́n bí òun ti ní ìtara púpọ̀, òun tìkára rẹ̀ tọ̀ yín wá, fúnrarẹ̀. 18 (A)Àwa ti rán arákùnrin náà pẹ̀lú rẹ̀, ìyìn ẹni tí ó wà nínú ìhìnrere yíká gbogbo ìjọ. 19 (B)Kì í sì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣùgbọ́n ẹni tí a tí yàn wá pẹ̀lú láti ọ̀dọ̀ ìjọ láti máa bá wa rìn kiri nínú ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ yìí, tí àwa ń ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀ fún ògo Olúwa àti ìmúra ìtara wa. 20 Àwa ń yẹra fún èyí, kí ẹnikẹ́ni má ba à rí wí sí wa ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí tí àwa pín. 21 Àwa ń gbèrò ohun rere, kì í ṣe níwájú Olúwa nìkan, ṣùgbọ́n níwájú ènìyàn pẹ̀lú.
22 Àwa sì ti rán arákùnrin wa pẹ̀lú wọn, ẹni tí àwa rí dájú nígbà púpọ̀ pé ó ní ìtara nínú ohun púpọ̀, ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí ni ìtara rẹ̀ túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ìfọkàntán ńlá tí ó ní sí yín. 23 Bí ẹnikẹ́ni bá béèrè ẹni tí Titu jẹ́, ẹlẹgbẹ́ àti olùbáṣiṣẹ́ mi ni, nítorí yín; tàbí ní ti àwọn arákùnrin wa ni ẹnikẹ́ni ń béèrè, ìránṣẹ́ ìjọ ni wọ́n jẹ́, àti ògo Kristi. 24 Nítorí náà ẹ fi ẹ̀rí ìfẹ́ yín hàn wọ́n níwájú ìjọ, àti ìṣògo wa nítorí yín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.