Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Maskili ti Dafidi. Nígbà tí Doegi ará Edomu tọ Saulu lọ láti sọ fún pé, “Dafidi wà ní ilé Ahimeleki.”
52 Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe féfé nínú ìwà ìkà, ìwọ alágbára ọkùnrin?
Èéṣe tí ìwọ fi ń gbéraga nígbà gbogbo,
ìwọ ẹni ẹ̀gàn níwájú Ọlọ́run?
2 Ahọ́n rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun;
ó dàbí abẹ mímú,
ìwọ ẹni tí ń hùwà ẹ̀tàn.
3 Ìwọ fẹ́ràn ibi ju ìre lọ,
àti èké ju kí ó sọ òtítọ́ lọ.
4 Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo,
ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn!
5 Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé,
yóò sì dì ọ́ mú,
yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó rẹ,
yóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. Sela.
6 Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rù
wọn yóò sì rẹ́rìn-ín rẹ̀, wí pé,
7 “Èyí ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára rẹ̀,
bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé,
ó sì mu ara rẹ̀ le nínú ìwà búburú rẹ̀.”
8 Ṣùgbọ́n èmi dàbí igi Olifi
tí ó gbilẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run;
Èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í kùnà
láé àti láéláé.
9 Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe;
èmi ní ìrètí nínú orúkọ rẹ,
nítorí orúkọ rẹ dára.
Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́.
Òpépé igi Sedari ni Lebanoni
31 Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kẹta ọdún kọkànlá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 2 “Ọmọ ènìyàn, sọ fún Farao ọba Ejibiti àti sí ìjọ rẹ̀:
“ ‘Ta ní a le fiwé ọ ní ọláńlá?
3 Kíyèsi Asiria, tí ó jẹ́ igi kedari ni
Lebanoni ní ìgbà kan rí,
pẹ̀lú àwọn ẹ̀ka dáradára tí ó ṣẹ́ ìji bo igbó náà;
tí ó ga sókè,
òkè rẹ̀ lókè ni ewé tí ó nípọn wà.
4 Omi mú un dàgbàsókè:
orísun omi tí ó jinlẹ̀ mú kí o dàgbàsókè;
àwọn odo rẹ̀ ń sàn yí ìdí rẹ̀ ká,
ó sì rán ìṣàn omi rẹ̀ sí gbogbo igi orí pápá.
5 Nítorí náà ó ga sí òkè fíofío
ju gbogbo igi orí pápá lọ;
ẹ̀ka rẹ̀ pọ̀ sí i:
àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì gùn,
wọn tẹ́ rẹrẹ nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi.
6 (A)Ẹyẹ ojú ọ̀run
kọ ilé sí ẹ̀ka rẹ̀
gbogbo ẹranko igbó
ń bímọ ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀;
gbogbo orílẹ̀-èdè ńlá
ń gbé abẹ́ ìji rẹ̀.
7 Ọláńlá ní ẹwà rẹ̀ jẹ́,
pẹ̀lú títẹ́ rẹrẹ ẹ̀ka rẹ̀,
nítorí gbòǹgbò rẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀
sí ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi wà.
8 (B)Àwọn igi kedari nínú ọgbà Ọlọ́run
kò lè è bò ó mọ́lẹ̀;
tàbí kí àwọn igi junifa
ṣe déédé pẹ̀lú ẹ̀ka rẹ̀,
tàbí kí a fi igi títẹ́ rẹrẹ wé ẹ̀ka rẹ̀,
kò sí igi nínú ọgbà Ọlọ́run
tí ó dà bí rẹ̀ ní ẹwà rẹ̀.
9 Mo mú kí ó ní ẹwà
pẹ̀lú ẹ̀ka lọ́pọ̀lọpọ̀
tó fi jẹ́ ìlara àwọn igi gbogbo ní Edeni
tí í ṣe ọgbà Ọlọ́run.
10 “ ‘Nítorí náà, èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí; Nítorí pé ó ga lọ sókè fíofío, tí ó sì gbé òkè rẹ̀ ga ju ewé tí ó nípọn lọ, àti nítorí pé gíga rẹ mú kí ó gbéraga, 11 Mo fi lé alákòóso àwọn orílẹ̀-èdè náà lọ́wọ́, fún un láti fi ṣe ẹ̀tọ́ fún un gẹ́gẹ́ bí ìwà búburú rẹ̀. Mo pa á tì sí ẹ̀gbẹ́ kan, 12 àwọn orílẹ̀-èdè àjèjì aláìláàánú jùlọ ké e lulẹ̀, wọn sì fi kalẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ ṣubú sórí òkè àti sí gbogbo àárín àwọn òkè; àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tí ó ṣẹ nà sílẹ̀ ní gbogbo àlàfo jíjìn ilẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé jáde kúrò ní abẹ́ ìji rẹ̀ wọn sì fi sílẹ̀.
Kì í ṣe ìkọlà bí kò ṣe ẹ̀dá tuntun
11 (A)Ẹ wo bí mo ti fi ọwọ́ ara mi kọ̀wé gàdàgbà-gàdàgbà sí yín.
12 Iye àwọn tí ń fẹ́ ṣe àṣehàn ni ara wọn ń rọ yín láti kọlà; kìkì nítorí pé kí a má ba à ṣe inúnibíni sí wọn nítorí àgbélébùú Kristi. 13 Nítorí àwọn tí a kọ ní ilà pàápàá kò pa òfin mọ́, ṣùgbọ́n wọ́n ń fẹ́ mú yin kọlà, kí wọn lè máa ṣògo nínú ara yín. 14 Ṣùgbọ́n kí a má ṣe rí i pé èmi ń ṣògo, bí kò ṣe nínú àgbélébùú Jesu Kristi Olúwa wa, nípasẹ̀ ẹni tí a ti kan ayé mọ́ àgbélébùú fún mi, àti èmi fún ayé. 15 Nítorí pé nínú Kristi Jesu, ìkọlà kò jẹ́ ohun kan, tàbí àìkọlà, bí kò ṣe ẹ̀dá tuntun. 16 (B)Kí àlàáfíà àti àánú wà lórí gbogbo àwọn tí ń rìn ní ìlànà yìí, àti lórí Israẹli Ọlọ́run.
17 Láti ìsinsin yìí lọ, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yọ mí lẹ́nu mọ́; nítorí èmi ń ru àpá Jesu Olúwa kiri ní ara mi.
Oore-ọ̀fẹ́
18 Ará, oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín. Àmín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.