Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Esekiẹli 17:22-24

22 “ ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Èmi fúnra mi yóò mú ọ̀kan lára ẹ̀ka tí ó ga jùlọ lórí igi Kedari gíga, tí èmi yóò sì gbìn ín, èmi yóò sì gé ọ̀mùnú tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ láti òkè, èmi yóò sì gbìn ín sórí òkè tó ga tó sì lókìkí. 23 (A)Ní ibi gíga òkè Israẹli ni èmi yóò gbìn ín sí; yóò pẹ̀ka, yóò sì so èso, yóò wa di igi Kedari tí ó lọ́lá. Oríṣìíríṣìí ẹyẹ yóò sì fi òjìji abẹ ẹ̀ka rẹ ṣe ibùgbé; wọn yóò ṣe ibùgbé si abẹ́ òjìji ẹ̀ka rẹ̀ 24 Gbogbo igi inú oko yóò mọ̀ pé, Èmi Olúwa ni ó mú igi gíga walẹ̀, tí mo sì mú kúkúrú ga sókè, tí mo mu igi tútù gbẹ, tí mo sì mú igi gbígbẹ rúwé.

“ ‘Èmi Olúwa ni ó sọ bẹ́ẹ̀, Èmi yóò sì ṣe e.’ ”

Saamu 92:1-4

Saamu. Orin. Fún ọjọ́ Ìsinmi

92 Ohun rere ni láti máa fi ọpẹ́ fún Olúwa
    àti láti máa kọrin sí orúkọ rẹ̀, Ọ̀gá-ògo,
Láti kéde ìfẹ́ rẹ̀ ní òwúrọ̀
    àti òtítọ́ rẹ̀ ní alẹ́
Lára ohùn èlò orin olókùn mẹ́wàá
    àti lára ohun èlò orin haapu.

Nítorí ìwọ ni ó mú inú mi dùn
    nípa iṣẹ́ rẹ Olúwa;
èmi kọrin ayọ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

Saamu 92:12-15

12 Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ,
    wọn yóò dàgbà bí i igi kedari Lebanoni;
13 Tí a gbìn sí ilé Olúwa,
    Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa.
14 Wọn yóò máa so èso ní ìgbà ogbó,
    wọn yóò dúró ní àkọ̀tun, wọn yóò sì tutù nini,
15 Láti fihàn pé “Ẹni ìdúró ṣinṣin ni Olúwa;
    òun ni àpáta mi, kò sì ṣí aburú
    kankan nínú rẹ̀.”

2 Kọrinti 5:6-10

Nítorí náà àwa ní ìgboyà nígbà gbogbo, àwa sì mọ̀ pé, nígbà tí àwa ń bẹ ní ilé nínú ara, àwa kò sí lọ́dọ̀ Olúwa. Àwa ń gbé nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa rí rí. Mo ní, àwa ní ìgboyà, àwa sì ń fẹ́ kí a kúkú ti inú ara kúrò, kí a sì lè wà ní ilé lọ́dọ̀ Olúwa. Nítorí náà àwa ń ṣakitiyan, pé, bí àwa bá wà ní ilé tàbí bí a kò sí, kí àwa lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀. 10 Nítorí pé gbogbo wa ni ó gbọdọ̀ fi ara hàn níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Kristi; kí olúkúlùkù lè gbà èyí tí ó ṣe gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó tọ́ sí i nígbà tí ó wà nínú ara ìbá à ṣe rere tàbí búburú.

2 Kọrinti 5:11-13

Iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìlàjà tí a yà sọ́tọ̀

11 Nítorí náà bí àwa ti mọ ẹ̀rù Olúwa, àwa ń yí ènìyàn lọ́kàn padà; ṣùgbọ́n a ń fi wá hàn fún Ọlọ́run; mo sì gbàgbọ́ pé, a sì ti fì wá hàn ní ọkàn yín pẹ̀lú. 12 (A)Nítorí àwa kò sì ní máa tún yin ara wá sí i yín mọ́, ṣùgbọ́n àwa fi ààyè fún yín láti máa ṣògo nítorí wa, kí ẹ lè ní ohun tí ẹ̀yin yóò fi dá wọn lóhùn, àwọn ti ń ṣògo lóde ara kì í ṣe ní ọkàn. 13 Nítorí náà bí àwa bá ń sínwín, fún Ọlọ́run ni: tàbí bí iyè wá bá ṣí pépé, fún yín ni.

2 Kọrinti 5:14-17

14 (A)Nítorí ìfẹ́ Kristi ń rọ̀ wá, nítorí àwa mọ̀ báyìí pé, bí ẹnìkan bá kú fún gbogbo ènìyàn, ǹjẹ́ nígbà náà, gbogbo wọ́n ni ó ti kú. 15 Ó sì ti kú fún gbogbo wọn, pé kí àwọn tí ó wà láààyè má sì ṣe wà láààyè fún ara wọn mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú nítorí wọn, tí ó sì ti jíǹde.

16 Nítorí náà láti ìsinsin yìí lọ, àwa kò mọ ẹnìkan nípa ti ara mọ́; bí àwa tilẹ̀ ti mọ Kristi nípa ti ara, ṣùgbọ́n nísinsin yìí àwa kò mọ̀ ọ́n bẹ́ẹ̀ mọ́. 17 (B)Nítorí náà bí ẹnìkan bá wà nínú Kristi, ó di ẹ̀dá tuntun: ohun àtijọ́ ti kọjá lọ; kíyèsi i, ohun tuntun ti dé.

Marku 4:26-34

Òwe irúgbìn tó ń dàgbà

26 (A)Ó sì tún sọ èyí pé, “Èyí ni a lè fi ìjọba Ọlọ́run wé. Ọkùnrin kan ń fúnrúgbìn sí ilẹ̀. 27 Lóru àti ní ọ̀sán, bóyá ó sùn tàbí ó dìde, irúgbìn náà hu jáde, ó sì dàgbà, òun kò sì mọ̀ bí ó ti ṣẹlẹ̀. 28 Nítorí tí ilẹ̀ kọ́kọ́ hù èso jáde fún ara rẹ̀, ó mú èéhù ewé jáde, èyí tí ó tẹ̀lé e ní orí ọkà, ní ìparí, ọkà náà gbó. 29 Nígbà tí èso bá gbó tán, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun a tẹ dòjé bọ inú ọkà náà, ó sì kórè rẹ̀.”

Òwe musitadi

30 (B)Jesu sì tún wí pé, “Kí ni kí èmi fi ìjọba Ọlọ́run wé? Òwe wo ni kí èmi fi ṣe àkàwé rẹ̀? 31 Ó dàbí èso hóró musitadi kan, lóòótọ́, ó jọ ọ̀kan nínú àwọn èso tí ó kéré jùlọ ti a gbìn sínú ilẹ̀. 32 Síbẹ̀, nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbàsókè, ó gbilẹ̀, ó sì di títóbi ju gbogbo ewéko inú ọgbà yòókù lọ. Ó sì yọ ẹ̀ka ńlá níbi tí àwọn ẹyẹ ọ̀run lè kọ́ ìtẹ́ wọn sí, kí wọn sì rí ìdáàbòbò.”

33 Òun lo ọ̀pọ̀ irú òwe wọ̀nyí láti fi kọ́ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n bá ti ń fẹ́ láti ní òye tó. 34 (C)Kìkì òwe ni Jesu fi ń kọ́ àwọn ènìyàn ní ẹ̀kọ́ ìta gbangba rẹ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí, nígbà tí ó bá sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, òun a sì sọ ìtumọ̀ ohun gbogbo.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.