Revised Common Lectionary (Complementary)
Maskili ti Asafu.
78 Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ mi;
tẹ́tí rẹ sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
2 (A)Èmi ó la ẹnu mi ní òwe,
èmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́;
3 Ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀,
ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa.
4 Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́
kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ,
ní fífi ìyìn Olúwa, àti ipa rẹ̀
àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn
fún ìran tí ń bọ̀.
52 Ṣùgbọ́n ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde bí ọ̀wọ́ ẹran;
ó ṣọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú aginjù.
53 Ó dáàbò bò wọ́n dáradára, nítorí náà ni ẹ̀rù kò ṣe bà wọ́n
ṣùgbọ́n Òkun padé mọ́ àwọn ọ̀tá wọn.
54 Bákan náà ni ó mú wọn wá sí etí ilẹ̀ mímọ́ rẹ̀
òkè tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ti gbà
55 Ó lé kèfèrí jáde níwájú wọn
ó sì fi títa okùn pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní;
ó mú àwọn ẹ̀yà Israẹli jókòó ní ilẹ̀ wọn.
56 Ṣùgbọ́n wọn dán Ọlọ́run wò
wọn sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo;
wọn kò pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
57 Ṣùgbọ́n wọ́n yípadà,
wọn jẹ́ aláìṣòdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn
wọ́n sì pẹ̀yìndà sí apákan bí ọrun ẹ̀tàn.
58 Wọ́n bí i nínú pẹ̀lú ibi gíga wọn;
wọn rú owú rẹ̀ sókè nípa òrìṣà wọn
59 Nígbà tí Ọlọ́run gbọ́ wọn,
inú bí i gidigidi;
ó kọ Israẹli pátápátá.
60 Ó kọ àgọ́ Ṣilo sílẹ̀,
àgọ́ tí ó ti gbé kalẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn.
61 Ó rán àpótí ẹ̀rí, agbára rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn,
dídán ògo rẹ̀ lọ sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá.
62 Ó fi àwọn ènìyàn rẹ̀ lé idà lọ́wọ́,
ó sì bínú sí àwọn ohun ìní rẹ̀.
63 Iná run àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn,
àwọn ọmọbìnrin wọn kò sì ní orin ìgbéyàwó:
64 A fi àlùfáà wọn fún idà,
àwọn opó wọn kò sì le è sọkún.
65 Olúwa sì jí gẹ́gẹ́ bí ẹni ojú oorun,
gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ti i jí kúrò nínú ìraníyè ọtí.
66 Ó kọlu àwọn ọ̀tá rẹ̀ padà;
ó fi wọn sínú ìtìjú ayérayé.
67 Nígbà náà ni ó kọ́ àgọ́ Josẹfu,
kò sì yan ẹ̀yà Efraimu;
68 Ṣùgbọ́n ó yan ẹ̀yà Juda,
òkè Sioni, èyí tí ó fẹ́ràn.
69 Ó kọ́ ibi mímọ́ rẹ̀, ibi gíga,
gẹ́gẹ́ bí ayé tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.
70 Ó yan Dafidi ìránṣẹ́ rẹ̀
ó mú láti inú àwọn agbo ẹran;
71 Ó mú un jáde nínú ìtọ́jú àgùntàn
láti jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn rẹ̀ Jakọbu
àti Israẹli ogún un rẹ̀.
72 Dafidi sì ṣọ́ wọn pẹ̀lú òtítọ́ inú ọkàn;
pẹ̀lú ọwọ́ òye ni ó fi darí wọn.
Dafidi ní Nobu
21 Dafidi sì wá sí Nobu sọ́dọ̀ Ahimeleki àlùfáà, Ahimeleki sì bẹ̀rù láti pàdé Dafidi, ó sì wí fún un pé, “Èéha ti rí tí o fi ṣe ìwọ nìkan, àti tí kò sì sí ọkùnrin kan tí ó pẹ̀lú rẹ?”
2 Dafidi sì wí fún Ahimeleki àlùfáà pé, “Ọba pàṣẹ iṣẹ́ kan fún mi, ó sì wí fún mi pé, ‘Má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan mọ ìdí iṣẹ́ náà ti mo rán ọ, àti èyí tí èmi ti pàṣẹ fún ọ.’ Èmi sì yan àwọn ìránṣẹ́ mi sí ibí báyìí. 3 Ǹjẹ́ kín ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀? Fún mi ni ìṣù àkàrà márùn-ún tàbí ohunkóhun tí o bá rí.”
4 Àlùfáà náà sí dá Dafidi lóhùn ó sì wí pé, “Kò sí àkàrà mìíràn lọ́wọ́ mi bí kò ṣe àkàrà mímọ́; Kìkì pé bi àwọn ọmọkùnrin bá ti pa ara wọn mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin!”
5 Dafidi sì dá àlùfáà náà lóhùn, ó sì wí fún un pé, “Nítòótọ́ ni a tí ń pa ara wá mọ́ kúrò lọ́dọ̀ obìnrin láti ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta wá, tí èmí ti jáde. Gbogbo nǹkan àwọn ọmọkùnrin náà ni ó mọ́, àti àkàrà náà sì wá dàbí àkàrà mìíràn, pàápàá nígbà tí ó jẹ́ pé òmíràn wà tí a yà sí mímọ́ lónìí nínú ohun èlò náà!” 6 Bẹ́ẹ̀ ni àlùfáà náà sì fi àkàrà mímọ́ fún un; nítorí tí kò sí àkàrà mìíràn níbẹ̀ bí kò ṣe àkàrà ìfihàn tí a ti kó kúrò níwájú Olúwa, láti fi àkàrà gbígbóná síbẹ̀ ní ọjọ́ tí a kó o kúrò.
Ìwòsàn ní etí odò adágún
5 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, àjọ àwọn Júù kan kò; Jesu sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu. 2 (A)Adágún omi kan sì wà ní Jerusalẹmu, létí bodè àgùntàn, tí a ń pè ní Betisaida ní èdè Heberu, tí ó ní ẹnu-ọ̀nà márùn-ún. 3 Ní ẹ̀gbẹ́ odò yìí ni ọ̀pọ̀ àwọn abirùn ènìyàn máa ń gbé dùbúlẹ̀ sí, àwọn afọ́jú, arọ àti aláàrùn ẹ̀gbà, wọ́n sì ń dúró de rírú omi. 4 Nítorí angẹli a máa sọ̀kalẹ̀ lọ sínú adágún náà, a sì máa rú omi rẹ̀: lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti rú omi náà tan ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ wọ inú rẹ̀ a di alára dídá kúrò nínú ààrùnkárùn tí ó ní. 5 Ọkùnrin kan wà níbẹ̀, ẹni tí ó tí wà ní àìlera fún ọdún méjì-dínlógójì. 6 Bí Jesu ti rí i ní ìdùbúlẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó pẹ́ tí ó ti wà bẹ́ẹ̀, ó wí fún un pé, “Ìwọ fẹ́ kí a mú ọ láradá bí?”
7 Abirùn náà dá a lóhùn wí pé, “Arákùnrin, èmi kò ní ẹni tí ìbá gbé mi sínú adágún, nígbà tí a bá ń rú omi náà: bí èmi bá ti ń bọ̀ wá, ẹlòmíràn a sọ̀kalẹ̀ sínú rẹ̀ síwájú mi.”
8 (B)Jesu wí fún un pé, “Dìde, gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn.” 9 Lọ́gán, a sì mú ọkùnrin náà láradá, ó sì gbé àkéte rẹ̀, ó sì ń rìn.
Ọjọ́ náà sì jẹ́ ọjọ́ ìsinmi. 10 (C)Nítorí náà àwọn Júù wí fún ọkùnrin náà tí a mú láradá pé, “Ọjọ́ ìsinmi ni òní; kò tọ́ fún ọ láti gbé àkéte rẹ.”
11 Ó sì dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹni tí ó mú mi láradá, ni ó wí fún mi pé, ‘Gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn.’ ”
12 Nígbà náà ni wọ́n bi í lérè wí pé, “Ọkùnrin wo ni ẹni tí ó wí fún ọ pé gbé àkéte rẹ, kí o sì máa rìn?”
13 Ẹni tí a mú láradá náà kò sì mọ̀ ẹni tí ó jẹ́ nítorí Jesu ti kúrò níbẹ̀, àwọn ènìyàn púpọ̀ wà níbẹ̀.
14 (D)Lẹ́yìn náà, Jesu rí i nínú tẹmpili ó sì wí fún un pé, “Wò ó, a mú ọ láradá: má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́, kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má ba à bá ọ!” 15 Ọkùnrin náà lọ, ó sì sọ fún àwọn Júù pé, Jesu ni ẹni tí ó mú òun láradá.
Àṣẹ ọmọ Ọlọ́run
16 Nítorí èyí ni àwọn Júù ṣe inúnibíni sí Jesu, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí tí o ń ṣe nǹkan wọ̀nyí ní ọjọ́ ìsinmi. 17 (E)Ṣùgbọ́n Jesu dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsin yìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.” 18 (F)Nítorí èyí ni àwọn Júù túbọ̀ ń wá ọ̀nà láti pa á, kì í ṣe nítorí pé ó ba ọjọ́ ìsinmi jẹ́ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó wí pẹ̀lú pé, Baba òun ni Ọlọ́run jẹ́, ó ń mú ara rẹ̀ bá Ọlọ́run dọ́gba.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.