Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti gittiti. Ti Asafu.
81 Kọrin sókè sí Ọlọ́run agbára wa
Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Ọlọ́run Jakọbu!
2 Ẹ mú orin mímọ́, kí ẹ sì mú ìlù wá,
tẹ dùùrù dídùn pẹ̀lú ohun èlò orin mímọ́.
3 Ẹ fún ìpè ní oṣù tuntun
àní nígbà tí a yàn;
ní ọjọ́ àjọ wa tí ó ní ìrònú.
4 Èyí ni àṣẹ fún Israẹli,
àti òfin Ọlọ́run Jakọbu.
5 Ó fi múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìlànà fún Josẹfu
nígbà tí ó la ilẹ̀ Ejibiti já.
Níbi tí a ti gbọ́ èdè tí kò yé wa.
6 Ó wí pé, “Mo gbé àjàgà kúrò ní èjìká yín,
a tú ọwọ́ wọn sílẹ̀ kúrò nínú apẹ̀rẹ̀.
7 Nínú ìnilára ni ẹ pè mo sì gbà yín là,
mo dá a yín lóhùn nínú ìkọ̀kọ̀ àrá,
mo dán an yín wò ní odò Meriba. Sela.
8 “Gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, èmi ó sì kìlọ̀ fún un yín,
bí ìwọ bá fetí sí mi, ìwọ Israẹli.
9 Ẹ̀yin kì yóò ní Ọlọ́run ilẹ̀ mìíràn láàrín yín;
ẹ̀yin kì yóò foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run àjèjì.
10 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ,
ẹni tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti.
Ẹ la ẹnu yín gbòòrò, èmi yóò sì kún un.
5 (A)“Mú ìyẹ̀fun dáradára, kí o sì ṣe ìṣù àkàrà méjìlá, kí o lo ìdá méjì nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n efa (èyí jẹ́ lítà mẹ́rin ààbọ̀) fún ìṣù kọ̀ọ̀kan. 6 Tò wọ́n sí ọ̀nà ìlà méjì, mẹ́fàmẹ́fà ní ìlà kọ̀ọ̀kan lórí tábìlì tí a fi ojúlówó wúrà bọ̀. Èyí tí ó wà níwájú Olúwa. 7 Ẹ fi ojúlówó tùràrí sí ọnà kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ìpín ìrántí láti dípò àkàrà, àti láti jẹ ẹbọ sísun sí Olúwa. 8 Àkàrà yìí ni kí ẹ gbé wá síwájú Olúwa nígbàkúgbà, lọ́ṣọ̀ọ̀ṣẹ̀, nítorí tí àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú ayérayé. 9 Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ló ni í. Wọ́n gbọdọ̀ jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́ torí pé ó jẹ́ ipa tí ó mọ́ jùlọ ti ìpín wọn ojoojúmọ́ nínú ọrẹ tí a fi iná ṣe sí Olúwa.”
19 (A)Mose kò ha fi òfin fún yín, kò sí ẹnikẹ́ni nínú yín tí ó pa òfin náà mọ́? Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá ọ̀nà láti pa mí?”
20 (B)Ìjọ ènìyàn dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Ìwọ ní ẹ̀mí èṣù: Ta ni ń wá ọ̀nà láti pa ọ́?”
21 (C)Jesu dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Kìkì iṣẹ́ ààmì kan ni mo ṣe, ẹnu sì ya gbogbo yín. 22 (D)Síbẹ̀, nítorí pé Mose fi ìkọlà fún yín (kò tilẹ̀ kúkú wá láti ọ̀dọ̀ Mose bí kò ṣe láti ọ̀dọ̀ àwọn baba ńlá yín); nítorí náà ẹ sì ń kọ ènìyàn ní ilà ní ọjọ́ ìsinmi. 23 (E)Bí ènìyàn bá ń gba ìkọlà ní ọjọ́ ìsinmi, kí a má ba à rú òfin Mose, ẹ ha ti ṣe ń bínú sí mi, nítorí mo mú ènìyàn kan láradá ní ọjọ́ ìsinmi? 24 (F)Ẹ má ṣe ìdájọ́ nípa ti ara, ṣùgbọ́n ẹ máa ṣe ìdájọ́ òdodo.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.