Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Ní ti ohun orin “Ní ti ikú ọmọ.” Saamu ti Dafidi.
9 Èmi ó yìn ọ́, Olúwa, pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi;
Èmi ó sọ ti ìyanu rẹ gbogbo.
2 Inú mi yóò dùn, èmi yóò sì yọ̀ nínú rẹ;
Èmi ó kọrin ìyìn sí orúkọ rẹ, Ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.
3 Àwọn ọ̀tá mi pẹ̀yìndà;
Wọ́n kọsẹ̀ wọn sì ṣègbé níwájú rẹ.
4 Nítorí ìwọ ti di òtítọ́ àti ọ̀ràn mi mú;
ìwọ ti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ, láti ṣe ìdájọ́ òdodo.
5 Ìwọ ti bá orílẹ̀-èdè wí, Ìwọ sì ti pa ẹni búburú run;
Ìwọ ti yọ orúkọ wọn kúrò láé àti láéláé.
6 Ìparun àìlópin ti borí àwọn ọ̀tá,
Ìwọ ti fa àwọn ìlú wọn tu;
àní ìrántí wọn sì ti ṣègbé.
7 Olúwa jẹ ọba títí láé;
ó ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ fún ìdájọ́.
8 (A)Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ ayé ní òdodo;
yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo.
9 Olúwa ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,
ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú.
10 Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀lé ọ,
nítorí, Olúwa, kò kọ àwọn tó ń wá a sílẹ̀.
11 Kọ orin ìyìn sí Olúwa, tí o ń jẹ ọba ní Sioni;
kéde láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tí ó ṣe.
12 Nítorí ẹni tí ó ń gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ rántí;
òun kò kọ ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.
13 Olúwa, wo bí àwọn ọ̀tá ṣe ń ṣe inúnibíni sí mi!
Ṣàánú, kí o sì gbé mí sókè kúrò ní ẹnu-ọ̀nà ikú,
14 Kí èmi kí ó lè sọ ti ìyìn rẹ
ni ẹnu-ọ̀nà àwọn ọmọbìnrin Sioni
àti láti máa yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.
Ìdáhùn Jobu fún Elifasi
16 Ìgbà náà ní Jobu dáhùn, ó sì wí pé:
2 “Èmi ti gbọ́ irú ohun púpọ̀ bẹ́ẹ̀ rí
ayọnilẹ́nu onítùnú ènìyàn ní gbogbo yín.
3 Ọ̀rọ̀ asán lè ni òpin?
Tàbí kí ni ó gbó ọ láyà tí ìwọ fi dáhùn?
4 Èmi pẹ̀lú le sọ bí ẹ̀yin;
bí ọkàn yín bá wà ní ipò ọkàn mi,
èmi le sọ ọ̀rọ̀ dáradára púpọ̀ sí yín ní ọrùn,
èmi a sì mi orí mi sí i yín.
5 Èmi ìbá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi gbà yín ni
ìyànjú, àti ṣíṣí ètè mi ìbá sì tu ìbìnújẹ́ yín.
6 “Bí èmi tilẹ̀ sọ̀rọ̀, ìbìnújẹ́ mi kò lọ;
bí mo sì tilẹ̀ dákẹ́, níbo ni ìtùnú mí ko kúrò?
7 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó dá mi lágara;
Ìwọ Ọlọ́run mú gbogbo ẹgbẹ́ mi takété.
8 Ìwọ fi ìhunjọ kùn mí lára, èyí tí o jẹ́rìí tì mí;
àti rírù tí ó hàn lára mi, ó jẹ́rìí tì mí ní ojú.
9 Ọlọ́run fi i ìbínú rẹ̀ fà mí ya, ó sì gbóguntì mí;
ó pa eyín rẹ̀ keke sí mi,
ọ̀tá mi sì gbójú rẹ̀ sí mi.
10 Wọ́n ti fi ẹnu wọn yẹ̀yẹ́ mi;
Wọ́n gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ìgbá ẹ̀gàn;
Wọ́n kó ara wọn pọ̀ sí mi.
11 Ọlọ́run ti fi mí lé ọwọ́ ẹni
búburú, ó sì mú mi ṣubú sí ọwọ́ ènìyàn ìkà.
12 Mo ti jókòó jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n ó fà mí já;
ó sì dì mí ni ọrùn mú, ó sì gbọ̀n mí túútúú,
ó sì gbé mi kalẹ̀ láti ṣe ààmì ìtafàsí rẹ̀;
13 àwọn tafàtafà rẹ̀ dúró yí mi káàkiri.
Ó là mí láyà pẹ̀rẹ̀, kò si dá sí,
ó sì tú òróòro ara mi dà sílẹ̀.
14 Ìbàjẹ́ lórí ìbàjẹ́ ní ó fi bà mí jẹ́;
ó súré kọlù mi bí jagunjagun.
15 “Mo rán aṣọ ọ̀fọ̀ bò ara mi,
mo sì rẹ̀ ìwo mi sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.
16 Ojú mi ti pọ́n fún ẹkún,
òjìji ikú sì ṣẹ́ sí ìpéǹpéjú mi.
17 Kì í ṣe nítorí àìṣòótọ́ kan ní ọwọ́
mi; àdúrà mi sì mọ́ pẹ̀lú.
18 “Háà! Ilẹ̀ ayé, ìwọ má ṣe bò ẹ̀jẹ̀ mi,
kí ẹkún mi má ṣe wà ní ipò kan.
19 Ǹjẹ́ nísinsin yìí kíyèsi i, ẹlẹ́rìí mi ń bẹ ní ọ̀run,
ẹ̀rí mi sì ń bẹ lókè ọ̀run.
20 Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣẹ̀sín,
ṣùgbọ́n ojú mi ń da omijé sọ́dọ̀ Ọlọ́run;
21 Ìbá ṣe pé ẹnìkan le è máa ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọ́run,
bí ènìyàn kan ti í ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì rẹ̀.
45 (A)“Ǹjẹ́ olóòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n ọmọ ọ̀dọ̀ wo ni olúwa rẹ̀ lè fi ṣe olùbojútó ilé rẹ̀ láti bọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ lójoojúmọ́? 46 Alábùkún fún ni ọmọ ọ̀dọ̀ ti olúwa rẹ̀ dé tí ó sì bá a lórí iṣẹ́ ṣíṣe. 47 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi yóò sì fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe alákòóso gbogbo ohun tí mo ní. 48 Ṣùgbọ́n bí ọmọ ọ̀dọ̀ náà bá jẹ́ ènìyàn búburú náà bá wí ní ọkàn rẹ̀ pé, ‘olúwa mi kì yóò tètè dé.’ 49 Tí ó sì bẹ̀rẹ̀ si í fi ìyà jẹ́ àwọn ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó ń jẹ, tí ó sì ń mu àmupara. 50 Nígbà náà ni olúwa ọmọ ọ̀dọ̀ yóò wá ní ọjọ́ àti wákàtí tí kò retí. 51 Yóò sì jẹ ẹ́ ní ìyà gidigidi, yóò sì rán an sí ibùgbé àwọn àgàbàgebè, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò wà.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.