Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 5

Fún adarí orin. Fún ohun èlò orin fífọn. Saamu ti Dafidi.

Fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, Olúwa,
    kíyèsi àròyé mi.
Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́,
    ọba mi àti Ọlọ́run mi,
    nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí.

Ní òwúrọ̀, Olúwa, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi;
    ní òwúrọ̀, èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú rẹ̀
    èmi yóò sì dúró ní ìrètí.
Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ní inú dídùn sí búburú;
    bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi kò le è bá ọ gbé.
Àwọn agbéraga kò le è dúró
    níwájú rẹ̀.
Ìwọ kórìíra gbogbo àwọn aṣebi;
    ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run.
Apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyàn
    ni Olúwa yóò kórìíra.
Ṣùgbọ́n èmi, nípa títóbi àánú rẹ̀,
    èmi yóò wá sínú ilé rẹ̀;
ní tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni èmi yóò tẹríba
    sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀.

Tọ́ mi, Olúwa, nínú òdodo rẹ,
    nítorí àwọn ọ̀tá mi,
    mú ọ̀nà rẹ tọ́ níwájú mi.
(A)Kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ẹnu wọn tí a lè gbàgbọ́;
    ọkàn wọn kún fún ìparun.
Ọ̀nà ọ̀fun wọn ni isà òkú tí ó ṣí sílẹ̀;
    pẹ̀lú ahọ́n wọn ni wọ́n ń sọ ẹ̀tàn.
10 Dá wọn lẹ́bi Ọlọ́run!
    Jẹ́ kí rìkíṣí wọn jẹ́ ìṣubú wọn.
Lé wọn jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
    nítorí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ.
11 Ṣùgbọ́n, jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó sádi ọ́ kí ó yọ̀;
    jẹ kí wọn máa kọrin fún ayọ̀ títí.
Tan ààbò rẹ sórí wọn,
    àti àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ yóò máa yọ̀ nínú rẹ.

12 Dájúdájú, Olúwa, ìwọ bùkún olódodo;
    ìwọ fi ojúrere rẹ yí wọn ká bí asà.

Jeremiah 5:18-31

18 “Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì,” ni Olúwa wí, “Èmi kì yóò pa yín run pátápátá. 19 Àti pé, nígbà tí àwọn ènìyàn bá sì béèrè wí pé, ‘Kí ni ìdí rẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run wa fi ṣe gbogbo èyí sí wa?’ Ìwọ yóò sì sọ fún wọn wí pé, ‘Ẹ̀yin ti kọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sì ń sin ọlọ́run àjèjì ní ilẹ̀ yín. Nísinsin yìí, ẹ̀yin yóò máa sin àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiyín.’

20 “Kéde èyí fún ilé Jakọbu,
    kí ẹ sì polongo rẹ̀ ní Juda.
21 (A)Gbọ́ èyí, ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n ènìyàn,
    tí ó lójú ti kò fi ríran
    tí ó létí ti kò fi gbọ́rọ̀.
22 Kò ha yẹ kí ẹ bẹ̀rù mi?” ni Olúwa wí.
    “Kò ha yẹ kí ẹ̀yin ó wárìrì níwájú mi bí?
Mo fi yanrìn pààlà Òkun,
    èyí tí kò le è rékọjá rẹ̀ láéláé.
Ìjì lè jà, kò le è borí rẹ̀;
    wọ́n le è bú, wọn kò le è rékọjá rẹ̀.
23 Ṣùgbọ́n, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ní ọkàn líle àti ọkàn ọ̀tẹ̀,
    wọ́n ti yípadà, wọ́n sì ti lọ.
24 Wọn kò sọ fún ara wọn pé,
    ‘Ẹ jẹ́ ká a bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa,
ẹni tí ó fún wa ní òjò àkọ́rọ̀ àti àrọ̀kúrò òjò ní ìgbà rẹ̀,
    tí ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípa ìkórè ọ̀sẹ̀ déédé.’
25 Àìṣedéédéé yín mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí kúrò,
    ẹ̀ṣẹ̀ yín sì mú kí a fi nǹkan rere dù yín.

26 “Láàrín ènìyàn mi ni ìkà ènìyàn wà
    tí ó wà ní ibùba bí ẹni tí ó ń dẹ ẹyẹ,
    àti bí àwọn tí ó ń dẹ pàkúté láti mú ènìyàn.
27 Bí àgò tí ó kún fún ẹyẹ,
    ilé wọn sì kún fún ẹ̀tàn.
Wọ́n ti di ọlọ́lá àti alágbára,
28     Wọ́n sanra wọ́n sì ń dán.
Ìwà búburú wọn kò sì lópin;
    wọn kò bẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ àwọn aláìní baba láti borí rẹ̀.
    Wọn kò jà fún ẹ̀tọ́ àwọn tálákà.
29 Èmi kì yóò ha fi ìyà jẹ wọ́n fún èyí bí?”
    ni Olúwa wí.
“Èmi kì yóò wá gbẹ̀san ara mi
    lára orílẹ̀-èdè bí èyí bí?

30 “Nǹkan ìbànújẹ́ àti ohun ìtara
    ti ṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ náà.
31 Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké,
    àwọn àlùfáà sì ń ṣe àkóso pẹ̀lú àṣẹ ara wọn,
àwọn ènìyàn mi sì ní ìfẹ́ sí èyí,
    kí ni ẹ̀yin yóò ṣe ní òpin?

1 Tẹsalonika 2:13-20

13 (A)Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà nítorí pé, ẹ kò ka ọ̀rọ̀ ìwàásù wa sí ọ̀rọ̀ ti ara wa. Pẹ̀lú ayọ̀ ni ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a wí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òtítọ́ sì ni pé, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni, èyí tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́. 14 Nítorí, ẹ̀yin ara, ẹ jẹ́ àwòkọ́ṣe àwọn ìjọ Ọlọ́run tí o wà ní Judea nínú Kristi Jesu. Nítorí pé ẹ̀yin pẹ̀lú jìyà irú ohun kan náà lọ́wọ́ àwọn ará ìlú yín, gẹ́gẹ́ bí àwọn pẹ̀lú ti jìyà lọ́wọ́ àwọn Júù, 15 (B)àwọn tí wọ́n pa Jesu Olúwa àti àwọn wòlíì, tí wọ́n sì tì wa jáde. Wọn kò ṣe èyí tí ó wu Ọlọ́run, wọ́n sì ṣe lòdì sí gbogbo ènìyàn 16 (C)nínú ìgbìyànjú wọn láti dá ìwàásù ìhìnrere dúró láàrín àwọn aláìkọlà kí wọn kí ó lè rí gbàlà. Ẹ̀ṣẹ̀ wọn ń di púpọ̀ sí i lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, ìbínú Ọlọ́run ti wá sórí wọn ní ìgbẹ̀yìn.

Paulu n fẹ́ láti rí àwọn ìjọ Tẹsalonika

17 (D)Ẹ̀yin ará olùfẹ́, lẹ́yìn ìgbà tí a ti kúrò lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀ (nínú ara, kì í ṣe ọkàn), pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtara ni àwa ṣe àníyàn tí a sì fẹ́ gidigidi láti fi rí i yín. 18 Nítorí àwa fẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ yín—àní èmi, Paulu, gbìyànjú ní ọ̀pọ̀ ìgbà láti wá, ṣùgbọ́n èṣù ú dè wá lọ́nà. 19 (E)Kí ni ìrètí wa, ayọ̀ wa, tàbí adé wa nínú èyí tí a ó ṣògo níwájú Jesu Olúwa nígbà tí òun bá dé? Ṣé ẹ̀yin kọ́ ni? 20 (F)Nítòótọ́, ẹ̀yin ni ògo àti ayọ̀ wa.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.