Revised Common Lectionary (Complementary)
5 Báyìí ni Olúwa wí:
“Ní ti àwọn Wòlíì
tí ń ṣi àwọn ènìyàn mi lọ́nà,
tí ẹnìkan bá fún wọn ní oúnjẹ,
wọn yóò kéde àlàáfíà;
Ṣùgbọ́n tí kò bá fi nǹkan sí wọn ní ẹnu,
wọn yóò múra ogun sí i.
6 Nítorí náà òru yóò wá sórí yín,
tí ẹ̀yin kì yóò sì rí ìran kankan,
òkùnkùn yóò sì kùn fún yín,
tí ẹ̀yin kì yóò sì lè sọtẹ́lẹ̀
Oòrùn yóò sì wọ lórí àwọn wòlíì
ọjọ́ yóò sì ṣókùnkùn lórí wọn.
7 Ojú yóò sì ti àwọn Wòlíì
àwọn alásọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú yóò sì gba ìtìjú.
Gbogbo wọn ni yóò bo ojú wọn,
nítorí kò sí ìdáhùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”
8 Ṣùgbọ́n ní tèmi,
èmi kún fún agbára pẹ̀lú ẹ̀mí Olúwa,
láti sọ ìré-òfin-kọjá Jakọbu fún un,
àti láti sọ ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli fún un.
9 Gbọ́ ẹ̀yin olórí ilé Jakọbu,
àti ẹ̀yin alákòóso ilé Israẹli,
tí ó kórìíra òdodo
tí ó sì yí òtítọ́ padà;
10 Tí ó kọ́ Sioni pẹ̀lú ìtàjẹ̀ sílẹ̀,
àti Jerusalẹmu pẹ̀lú ìwà búburú.
11 Àwọn olórí rẹ̀ ń ṣe ìdájọ́ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀,
àwọn àlùfáà rẹ̀ sì ń kọ́ni nítorí owó ọ̀yà
àwọn wòlíì rẹ̀ pẹ̀lú sì ń sọtẹ́lẹ̀ nítorí owó.
Síbẹ̀, wọn gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, wọ́n sì wí pé,
“Nítòótọ́, Olúwa wà pẹ̀lú wa!
Ibi kan kì yóò bá wa.”
12 Nítorí náà, nítorí tiyín,
ni a ó ṣe ro Sioni bí oko,
Jerusalẹmu yóò sì di ebè
àti òkè tẹmpili bí i ibi gíga igbó.
43 Dá mi láre, Ọlọ́run mi,
kí o sì gba ọ̀rọ̀ mi rò lọ́dọ̀ àwọn aláìláàánú orílẹ̀-èdè:
yọ mí kúrò lọ́wọ́ ẹlẹ́tàn àti àwọn ènìyàn búburú.
2 Ìwọ ni Ọlọ́run ibi agbára mi.
Èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mi sílẹ̀?
Èéṣe tí èmi yóò máa rìn nínú ìbìnújẹ́,
nítorí ìnilára lọ́dọ̀ àwọn ọ̀tá?
3 Rán ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́ rẹ jáde,
jẹ́ kí wọn ó máa dáàbò bò mí;
jẹ́ kí wọn mú mi wá sí òkè mímọ́ rẹ,
sí ibi tí ìwọ ń gbé.
4 Nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi pẹpẹ Ọlọ́run,
sí Ọlọ́run ayọ̀ mi àti ìdùnnú mi,
èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú dùùrù,
ìwọ Ọlọ́run, Ọlọ́run mi.
5 Èéṣe tí o fi ń rẹ̀wẹ̀sì, ìwọ ọkàn mí?
Èéṣe tí ó fi ń ru sókè nínú mi?
Fi ìrètí rẹ sínú Ọlọ́run,
nítorí èmi yóò máa yìn ín, Òun ni
Olùgbàlà mi àti Ọlọ́run mi.
9 Nítòótọ́ ẹ rántí, ará, iṣẹ́ àti làálàá wa; lọ́sàn án àti lóru ni àwa ń ṣiṣẹ́ kí ìnáwó wa má bà á di ìṣòro fún ẹnikẹ́ni bí a ti ń wàásù ìhìnrere Ọlọ́run fún un yín. 10 Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí wà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ọlọ́run pẹ̀lú, bí a ṣe gbé ìgbé ayé mímọ́, òdodo àti àìlẹ́gàn láàrín ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́. 11 (A)Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin sì ti mọ̀ bí àwa tí ń ba olúkúlùkù yín lò gẹ́gẹ́ bí baba ti ń bá àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ 12 (B)ìyànjú, ìtùnú àti tí a ń bẹ̀ yín láti gbé ìgbésí ayé tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ń pè yín sínú ìjọba àti ògo òun tìkára rẹ̀.
13 (C)Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà nítorí pé, ẹ kò ka ọ̀rọ̀ ìwàásù wa sí ọ̀rọ̀ ti ara wa. Pẹ̀lú ayọ̀ ni ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a wí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òtítọ́ sì ni pé, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni, èyí tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́.
Ìdí méje fún ìdájọ́
23 Nígbà náà ni Jesu wí fún ọ̀pọ̀ ènìyàn àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé: 2 “Àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn Farisi jókòó ní ipò Mose, 3 Nítorí náà, ẹ gbọdọ̀ gbọ́ tiwọn, kí ẹ sì ṣe ohun gbogbo tí wọ́n bá sọ fún yín. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ohun tí wọ́n ṣe, nítorí àwọn pàápàá kì í ṣe ohun tí wọn kọ́ yín láti ṣe. 4 Wọ́n á di ẹrù wúwo tí ó sì ṣòro láti rù, wọ́n a sì gbé e le àwọn ènìyàn léjìká, ṣùgbọ́n àwọn tìkára wọn kò jẹ́ fi ìka wọn kan an.
5 (A)“Ohun gbogbo tí wọ́n ń ṣe, wọ́n ń ṣe é kí àwọn ènìyàn ba à lè rí wọn ni: Wọ́n ń sọ filakteri wọn di gbígbòòrò. Wọ́n tilẹ̀ ń bùkún ìṣẹ́tí aṣọ oyè wọn nígbà gbogbo kí ó ba à lè máa tóbi sí i. 6 Wọ́n fẹ́ ipò ọlá ní ibi àsè, àti níbi ìjókòó ìyàsọ́tọ̀ ni Sinagọgu. 7 Wọ́n fẹ́ kí ènìyàn máa kí wọn ní ọjà, kí àwọn ènìyàn máa pè wọ́n ní ‘Rabbi.’
8 (B)“Ṣùgbọ́n kí a má ṣe pè yín ni Rabbi, nítorí pé ẹnìkan ni Olùkọ́ yín, àní Kristi, ará sì ni gbogbo yín. 9 Ẹ má ṣe pe ẹnikẹ́ni ní baba yín ni ayé yìí, nítorí baba kan náà ni ẹ ní tí ó ń bẹ ní ọ̀run. 10 Kí a má sì ṣe pè yín ní Olùkọ́ nítorí Olùkọ́ kan ṣoṣo ni ẹ̀yin ní, òun náà ni Kristi. 11 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá pọ̀jù nínú yín, ni yóò jẹ́ ìránṣẹ́ yín. 12 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a ó sì rẹ̀ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara wọn sílẹ̀ ni a ó gbéga.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.