Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 119:41-48

Ìgbàlà láti inú òfin Ọlọ́run

41 Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, Olúwa,
    ìgbàlà rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ;
42 Nígbà náà ni èmi yóò dá
    ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn,
    nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.
43 Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu mi
    nítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ rẹ
44 Èmi yóò máa gbọ́rọ̀ sí òfin rẹ nígbà gbogbo
    láé àti láéláé.
45 Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira,
    nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ rẹ jáde.
46 Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba
    ojú kì yóò sì tì mí,
47 Nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ rẹ
    nítorí èmi ní ìfẹ́ wọn.
48 Èmi gbé ọwọ́ mi sókè nítorí àṣẹ rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn,
    èmi sì ń ṣe àṣàrò òfin rẹ̀.

Òwe 16:1-20

16 Ti ènìyàn ni ìgbèrò inú ọkàn
    ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìdáhùn ahọ́n ti ń wá.

Gbogbo ọ̀nà ènìyàn ni ó dàbí i pé ó dára lójú ara rẹ̀
    ṣùgbọ́n Olúwa ló ń díwọ̀n èrò inú ọkàn.

Fi ohun gbogbo tí o bá ṣe lé Olúwa lọ́wọ́
    Èrò rẹ yóò sì ṣe é ṣe.

Olúwa ti ṣe ohun gbogbo láti mú kí ó rí bí ó ṣe fẹ́
    kódà ènìyàn búburú fún ọjọ́ ìpọ́njú.

Olúwa kórìíra gbogbo ẹni tí ń gbéraga lọ́kàn rẹ̀
    mọ èyí dájú pé wọn kò ní lọ láìjìyà.

Nípasẹ̀ ìfẹ́ àti òtítọ́ a ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀
    nípasẹ̀ ìbẹ̀rù Olúwa ènìyàn sá fún ibi.

Nígbà tí ọ̀nà ènìyàn bá tẹ́ Olúwa lọ́rùn,
    yóò mú kí àwọn ọ̀tá rẹ̀ gàn án bá a gbé ní àlàáfíà.

Ó sàn kí ó kéré pẹ̀lú òdodo
    ju èrè púpọ̀ pẹ̀lú èrú lọ.

Ènìyàn a máa pète ọ̀nà ara rẹ̀ lọ́kàn an rẹ̀
    ṣùgbọ́n Olúwa ní í pinnu ìgbésẹ̀ rẹ̀.

10 Ètè ọba a máa sọ̀rọ̀ nípa àṣẹ sí i
    ẹnu rẹ̀ kò gbọdọ̀ ṣèké.

11 Òdínwọ̀n àti òṣùwọ̀n òtítọ́ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa;
    gbogbo wíwúwo àpò jẹ́ láti ọwọ́ rẹ̀.

12 Àwọn ọba kórìíra ìwà àìtọ́
    nítorí òdodo ní í fi ìdí ìtẹ́ múlẹ̀.

13 Àwọn ọba ní inú dídùn sí ètè tí ń ṣọ òtítọ́,
    wọ́n sì fẹ́ ẹni tí ń sọ̀rọ̀ òtítọ́.

14 Ìránṣẹ́ ikú ni ìbínú ọba jẹ́
    ṣùgbọ́n ọlọ́gbọ́n ènìyàn yóò tù ú nínú.

15 Nígbà tí ojú ọba bá túká, ó túmọ̀ sí ìyè;
    ojúrere rẹ̀ dàbí i ṣíṣú òjò ní ìgbà òjò.

16 Ó ti dára tó láti ní ọgbọ́n ju wúrà lọ
    àti láti yan òye dípò o fàdákà!

17 Òpópó ọ̀nà àwọn ẹni dídúró ṣinṣin yàgò fún ibi,
    ẹni tí ó ṣọ́ ọ̀nà rẹ̀, ṣọ́ ẹnu ara rẹ̀.

18 Ìgbéraga ní í ṣáájú ìparun,
    agídí ọkàn ní í ṣáájú ìṣubú.

19 Ó sàn láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn láàrín àwọn olùpọ́njú
    jù láti máa pín ìpín pẹ̀lú àwọn agbéraga.

20 Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé ẹ̀kọ́ yóò rí ìre,
    ìbùkún sì ni fún ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa.

Matiu 19:16-22

Ọ̀dọ́mọkùnrin ọlọ́rọ̀

16 (A)(B) Ẹnìkan sì wá ó bí Jesu pé, “Olùkọ́, ohun rere kí ni èmi yóò ṣe, kí èmi kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun?”

17 Jesu dá a lóhùn pé, “Èéṣe tí ìwọ fi ń béèrè nípa ohun rere lọ́wọ́ mi. Ẹni kan ṣoṣo ni ó wà tí í ṣe Ẹni rere. Bí ìwọ bá fẹ́ dé ibi ìyè, pa àwọn òfin mọ́.”

18 (C)Ọkùnrin náà béèrè pé, “Àwọn wo ni òfin wọ̀nyí?”

Jesu dáhùn pé, “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn; Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà; Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè; Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké’, 19 bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ. ‘Kí o sì fẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’ ”

20 Ọmọdékùnrin náà tún wí pé, “Gbogbo òfin wọ̀nyí ni èmi ti ń pamọ́, kí ni nǹkan mìíràn tí èmi ní láti ṣe?”

21 (D)Jesu wí fún un pé, “Bí ìwọ bá fẹ́ di ẹni pípé, lọ ta ohun gbogbo tí ìwọ ní, kí o sì fi owó rẹ̀ tọrẹ fún àwọn aláìní. Ìwọ yóò ní ọrọ̀ ńlá ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, wá láti máa tọ̀ mi lẹ́yìn.”

22 Ṣùgbọ́n nígbà tí ọ̀dọ́mọkùnrin náà gbọ́ èyí, ó kúrò níbẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́, nítorí ó ní ọrọ̀ púpọ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.