Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 25:1-9

Ẹ yin Olúwa

25 Olúwa, ìwọ ni Ọlọ́run mi;
    Èmi yóò gbé ọ ga èmi ó sì
fi ìyìn fún orúkọ rẹ
    nítorí nínú òtítọ́ aláìlẹ́gbẹ́
o ti ṣe ohun ńlá,
    àwọn ohun tí o ti gbèrò o rẹ̀ lọ́jọ́ pípẹ́.
Ìwọ ti sọ ìlú di àkójọ àlàpà,
    ìlú olódi ti di ààtàn,
ìlú olódi fún àwọn àjèjì ni kò sí mọ́;
    a kì yóò tún un kọ́ mọ́.
Nítorí náà àwọn ènìyàn alágbára yóò
    bọ̀wọ̀ fún ọ;
àwọn ìlú orílẹ̀-èdè aláìláàánú
    yóò bu ọlá fún ọ.
Ìwọ ti jẹ́ ààbò fún àwọn òtòṣì
    ààbò fún aláìní nínú ìpọ́njú rẹ̀
ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì
    bòòji kúrò lọ́wọ́ ooru.
Nítorí pé èémí àwọn ìkà
    dàbí ìjì tí ó bì lu ògiri
àti gẹ́gẹ́ bí ooru ní aginjù.
    O mú ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ bá rògbòdìyàn àwọn àjèjì,
gẹ́gẹ́ bí òjìji kurukuru ṣe ń dín ooru kù,
    bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni orin àwọn ìkà yóò dákẹ́.

Ní orí òkè yìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun
    yóò ti pèsè
àsè oúnjẹ àdídùn kan fún gbogbo ènìyàn
    àpèjẹ ti ọtí wáìnì àtijọ́
ti ẹran tí ó dára jù àti ti ọtí wáìnì
    tí ó gbámúṣé.
Ní orí òkè yìí ni yóò pa
    aṣọ òkú tí ó ti ń di gbogbo ènìyàn,
    abala tí ó bo gbogbo orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀;
(A)Òun yóò sì gbé ikú mì títí láé.
    Olúwa Olódùmarè yóò sì nu gbogbo omijé nù,
kúrò ní ojú gbogbo wọn;
    Òun yóò sì mú ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò
ní gbogbo ilẹ̀ ayé.
    Olúwa ni ó ti sọ ọ́.

Ní ọjọ́ náà wọn yóò sọ pé,

    “Nítòótọ́ eléyìí ni Ọlọ́run wa;
àwa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀, òun sì gbà wá là.
    Èyí ni Olúwa, àwa gbẹ́kẹ̀lé e,
    ẹ jẹ́ kí a yọ̀ kí inú wa sì dùn nínú ìgbàlà rẹ̀.”

Saamu 23

Saamu ti Dafidi.

23 Olúwa ni Olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní.
    (A)Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù
Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́;
    Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò
Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo
    nítorí orúkọ rẹ̀.
Bí mo tilẹ̀ ń rìn
    Láàrín àfonífojì òjìji ikú,
èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan;
    nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi;
ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ
    wọ́n ń tù mí nínú.

Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi
    ní ojú àwọn ọ̀tá à mi;
ìwọ ta òróró sí mi ní orí;
    ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀.
Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn
    ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo,
èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwa
    títí láéláé.

Filipi 4:1-9

Nítorí náà ẹ̀yin ará mi olùfẹ́, ti mo sì ń ṣàfẹ́rí gidigidi, ayọ̀ àti adé mi, ẹ dúró ṣinṣin bẹ́ẹ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin olùfẹ́ mi.

Àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú

Èmi ń bẹ̀ Euodia, mo sì ń bẹ Sintike, kí wọn ní inú kan náà nínú Olúwa. (A)Mo sì bẹ̀ yin pẹ̀lú bí alájọru àjàgà mi tòótọ́, ran àwọn obìnrin wọ̀nyí lọ́wọ́, nítorí wọn bá mi ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìfẹ̀gbẹ́-kẹ̀gbẹ́ nínú ìhìnrere, àti Klementi pẹ̀lú, àti àwọn olùbáṣiṣẹ́ mi yòókù pẹ̀lú, orúkọ àwọn tí ń bẹ nínú ìwé ìyè.

Ẹ máa yọ̀ nínú Olúwa nígbà gbogbo: mo sì tún wí pé. Ẹ máa yọ̀. Ẹ jẹ́ ki ìpamọ́ra yín di mímọ́ fún gbogbo ènìyàn, Olúwa ń bẹ nítòsí. (B)Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run. Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín mọ nínú Kristi Jesu.

Ní àkótán, ará, ohunkóhun tí í ṣe òtítọ́, ohunkóhun tí í ṣe ọ̀wọ̀, ohunkóhun tí í ṣe títọ́ ohunkóhun tí í ṣe mímọ́, ohunkóhun tí í ṣe fífẹ́, ohunkóhun tí ó ni ìròyìn rere, bí ìwà títọ́ kan bá wà, bí ìyìn kan bá sì wà, ẹ máa gba nǹkan wọ̀nyí rò. (C)Àwọn nǹkan tí ẹ̀yin ti kọ́, tí ẹ̀yin sì ti gbà, tí ẹ̀yin sì ti gbọ́, tí ẹ̀yin sì ti rí lọ́wọ́ mi, ẹ máa ṣe wọ́n: Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.

Matiu 22:1-14

Òwe àsè ìgbéyàwó

22 (A)Jesu tún fi òwe sọ̀rọ̀ fún wọn wí pé: “Ìjọba ọ̀run dàbí ọba kan ti ó múra àsè ìgbéyàwó ńlá fún ọmọ rẹ̀ ọkùnrin. Ó rán àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ lọ pe àwọn tí a ti pè tẹ́lẹ̀ sí ibi àsè ìgbéyàwó. Ṣùgbọ́n wọn kò fẹ́ wá.

“Lẹ́yìn náà ó tún rán àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn pé, ‘Ẹ sọ fún àwọn tí mo ti pè wí pé, mo ti ṣe àsè náà tán. A pa màlúù àti ẹran àbọ́pa mi, a ti ṣe ohun gbogbo tán, ẹ wa sí ibi àsè ìgbéyàwó.’

“Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀n-ọn-nì tí ó ránṣẹ́ lọ pè kò kà á si. Wọ́n ń bá iṣẹ́ wọn lọ, ọ̀kan sí ọ̀nà oko rẹ̀, òmíràn sí ibi òwò rẹ̀.” Àwọn ìyókù sì mú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ṣe àbùkù sí wọn, wọ́n lù wọ́n pa. Ọba yìí bínú gidigidi, ó sì rán àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, ó sì pa àwọn apànìyàn náà run, ó sì jó ìlú wọn.

“Nígbà náà ni ó wí fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé, ‘Àsè ìgbéyàwó ti ṣe tàn, ṣùgbọ́n àwọn tí a pè kò yẹ fún ọlá náà. Ẹ lọ sí ìgboro àti òpópónà kí ẹ sì pe ẹnikẹ́ni tí ẹ bá lè rí wá àsè ìgbéyàwó náà.’ 10 Nítorí náà, àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ náà sì jáde lọ sí òpópónà. Wọ́n sì mú oríṣìíríṣìí ènìyàn tí wọ́n lè rí wá, àwọn tí ò dára àti àwọn tí kò dára, ilé àsè ìyàwó sì kún fún àlejò.

11 “Ṣùgbọ́n nígbà tí ọba sì wọlé wá láti wo àwọn àlejò tí a pè, ó sì rí ọkùnrin kan nínú wọn tí kò wọ aṣọ ìgbéyàwó. 12 Ọba sì bi í pé, ‘Ọ̀rẹ́, báwo ni ìwọ ṣe wà níhìn-ín yìí láìní aṣọ ìgbéyàwó?’ Ṣùgbọ́n ọkùnrin náà kò ní ìdáhùn kankan.

13 (B)“Nígbà náà ni ọba wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ dì í tọwọ́ tẹsẹ̀, kí ẹ sì sọ ọ́ sínú òkùnkùn lóde níbi tí ẹkún àti ìpayínkeke wà.’

14 “Nítorí ọ̀pọ̀ ni a pè ṣùgbọ́n díẹ̀ ni a yàn.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.