Revised Common Lectionary (Complementary)
7 Tún wa yípadà, ìwọ, Ọlọ́run alágbára;
jẹ́ kí ojú rẹ tàn sí wa,
kí a ba à lè gbà wá là.
8 Ìwọ mú àjàrà jáde láti Ejibiti;
ìwọ lé àwọn kèfèrí jáde, o sì gbìn ín.
9 Ìwọ ṣí ààyè sílẹ̀ fún un,
ìwọ sì mu ta gbòǹgbò jinlẹ̀
ó sì kún ilẹ̀ náà.
10 A bò àwọn òkè mọ́lẹ̀ òkè pẹ̀lú òjìji rẹ̀,
ẹ̀ka rẹ̀ dàbí kedari Ọlọ́run.
11 O yọ ẹ̀ka rẹ̀ sínú Òkun,
ọwọ́ rẹ̀ sí odò ńlá nì.
12 Èéṣe tí ìwọ fi wó odi rẹ̀
tí àwọn ènìyàn tí ó ń kọjá fi ń ṣa èso rẹ̀?
13 Ìmàdò láti inú igbó ń bá a jẹ́
àti ẹranko igbó ń jẹ ẹ́ run.
14 Yípadà sí wa, àwa ń bẹ̀ ọ́, Ọlọ́run alágbára!
Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run kí o sì wò ó!
Kí o sì bẹ àjàrà yìí wò,
15 Gbòǹgbò èyí tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ti gbìn,
àti ẹ̀ka tí ìwọ ti mú lágbára fún ara rẹ.
14 Israẹli ha á jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀
ẹrú nípa ìbí? Kí ló ha a
dé tí ó fi di ìkógun?
15 Àwọn kìnnìún ké ramúramù
wọ́n sì ń bú mọ́ wọn
wọ́n ti fi ilẹ̀ rẹ̀ ṣòfò
Ìlú rẹ̀ ti di jíjóná, ó sì
ti di ìkọ̀sílẹ̀.
16 Bákan náà, àwọn ọkùnrin
Memfisi àti Tafanesi
wọ́n ti fa adé orí rẹ yọ.
17 Ẹ̀yin kò ha a ti fa èyí sórí
ara yín nípa kíkọ Ọlọ́run sílẹ̀
nígbà tí ó tọ́ ọ lójú ọ̀nà?
18 Kí ló dé tí o ṣe wá lọ Ejibiti
láti lọ mu omi ní Ṣihori?
Kí ló dé tí o sì fi lọ sí Asiria
láti lọ mú omi ni odò Eufurate náà?
19 Iṣẹ́ búburú yín yóò fìyà jẹ yín
ìpadàsẹ́yìn rẹ yóò sì bá ọ wí
mọ̀ kí o sì rí i wí pé ibi àti
ohun búburú yóò sì jẹ́ tìrẹ
nígbà tí o ti kọ Olúwa Ọlọ́run sílẹ̀,
ẹ kò sì ní ìbẹ̀rù fún mi,”
ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.
20 “Nígbà àtijọ́, o ti fọ́ àjàgà
rẹ sọnù, ìwọ sì já ìdè rẹ
ìwọ wí pé, ‘Èmi kì yóò sìn ọ́!’
Lóòtítọ́, lórí gbogbo òkè gíga ni
àti lábẹ́ igi tí ó tànkálẹ̀
ni ìwọ dùbúlẹ̀ sí gẹ́gẹ́ bí panṣágà.
21 Èmi ti gbìn ọ́ gẹ́gẹ́ bí
àjàrà ọ̀tọ̀, gẹ́gẹ́ bí ìṣúra ọlọ́lá,
Báwo wá ni ìwọ ṣe yípadà sí mi
di àjàrà búburú àti aláìmọ́?
22 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o wẹ ara rẹ pẹ̀lú sódà
tí o sì lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọṣẹ
síbẹ̀síbẹ̀ èérí ni ẹ̀ṣẹ̀ rẹ níwájú,”
ni Olúwa Olódùmarè wí.
16 (A)Nítorí náà ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣe ìdájọ́ yín ní ti jíjẹ, tàbí ní ti mímu, tàbí ní ti ọjọ́ àsè, tàbí oṣù tuntun, àti ọjọ́ ìsinmi: 17 (B)Àwọn tí í ṣe òjìji ohun tí ń bọ̀; ṣùgbọ́n ní ti òtítọ́, nínú Kristi ni àti mu wọn ṣẹ. 18 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí ó ní inú dídùn nínú ìrẹ̀lẹ̀ èké àti bíbọ àwọn angẹli lọ́ èrè yín gbà lọ́wọ́ yín, ẹni tí ń dúró lórí nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí ó ti rí, tí ó ń ṣe féfé asán nípa èrò ti ọkàn ara rẹ̀. 19 (C)Wọn ti sọ ìdàpọ̀ wọn pẹ̀lú ẹni tí i ṣe orí nu, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí a ń ti ipa oríkèé àti iṣan pèsè fún gbogbo ara, ti a sì ń so ó ṣọ̀kan pọ̀, tí ó sì ń dàgbà nípa ìmísí Ọlọ́run.
20 (D)Bí ẹ̀yin bá ti kú pẹ̀lú Kristi si àwọn agbára ìlànà ayé yìí, kín ló dé tí ẹ̀yin ń tẹríba fún òfin bí ẹni pé ẹ̀yin wà nínú ayé, 21 Má ṣe dìímú, má ṣe tọ́ ọ wò, má ṣe fi ọwọ́ bà á, 22 (E)Gbogbo èyí tí yóò ti ipa lílo run, gẹ́gẹ́ bí òfin àti ẹ̀kọ́ ènìyàn? 23 Àwọn nǹkan tí ó ní àfarawé ọgbọ́n nítòótọ́, nípasẹ̀ àdábọwọ́ ìsìn, àti ìrẹ̀lẹ̀, àti ìpọ́nra-ẹni-lójú, ṣùgbọ́n tí kò ni èrè láti di ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ku.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.