Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Jona 3:10-4:11

10 Ọlọ́run sì rí ìṣe wọn pé wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀nà ibi wọn: Ọlọ́run sì ronúpìwàdà ibi tí òun ti wí pé òun yóò ṣe sí wọn, òun kò sì ṣe e mọ́.

Jona bínú sí àánú tí Olúwa fihàn

Ṣùgbọ́n ó ba Jona nínú jẹ́ gidigidi, ó sì bínú púpọ̀. (A)Ó sì gbàdúrà sí Olúwa, ó sì wí pé, “Èmí bẹ̀ ọ́, Olúwa, ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ti mo sọ kọ́ ni èyí nígbà tí mo wà ní ilẹ̀ mi? Nítorí èyí ni mo ṣé sálọ sí Tarṣiṣi ní ìṣáájú: nítorí èmi mọ̀ pé, Ọlọ́run olóore-ọ̀fẹ́ ní ìwọ, àti aláàánú, O lọ́ra láti bínú, O sì ṣeun púpọ̀, O sì ronúpìwàdà ibi náà. Ǹjẹ́ báyìí, Olúwa, èmi bẹ̀ ọ, gba ẹ̀mí mi kúrò lọ́wọ́ mi nítorí ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láààyè lọ.”

Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Ìwọ́ ha ni ẹ̀tọ́ láti bínú bí?”

Jona sì jáde kúrò ní ìlú náà, ó sì jókòó níhà ìlà-oòrùn ìlú náà. Ó sì pa àgọ́ kan níbẹ̀ fún ara rẹ̀, ó sì jókòó ni òjìji ní abẹ́ rẹ̀ títí yóò fi rí ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ìlú náà. Olúwa Ọlọ́run sì pèsè ìtàkùn kan, ó ṣe é kí ó gòkè wá sórí Jona; kí ó lè ṣe ìji bò ó lórí; láti gbà á kúrò nínú ìbànújẹ́ rẹ̀. Jona sì yọ ayọ̀ ńlá nítorí ìtàkùn náà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run pèsè kòkòrò kan nígbà tí ilẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kejì, ó sì jẹ ìtàkùn náà ó sì rọ. Ó sì ṣe, nígbà tí oòrùn yọ, Ọlọ́run pèsè ẹ̀fúùfù gbígbóná tí ìlà-oòrùn; oòrùn sì pa Jona lórí tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi rẹ̀ ẹ́. Ó sì fẹ́ nínú ara rẹ̀ láti kú, ó sì wí pé, “Ó sàn fún mi láti kú ju àti wà láààyè lọ.”

Ọlọ́run sì wí fún Jona pé, “O ha tọ́ fún ọ láti bínú nítorí ìtàkùn náà?”

Òun sì wí pé, “Mo ni ẹ̀tọ́, o tọ́ fún mi láti bínú títí dé ikú.”

10 Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Ìwọ kẹ́dùn ìtàkùn náà, nítorí èyí tí ìwọ kò ṣiṣẹ́ fun, tí ìwọ kò mu dàgbà; tí ó hù jáde ní òru kan tí ó sì kú ni òru kan. 11 Ṣùgbọ́n Ninefe ní jù ọ̀kẹ́ mẹ́fà (12,000) ènìyàn nínú rẹ̀, tí wọn kò mọ ọwọ́ ọ̀tún wọn yàtọ̀ sí ti òsì, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọ̀sìn pẹ̀lú. Ṣé èmí kò ha ní kẹ́dùn nípa ìlú ńlá náà?”

Saamu 145:1-8

Saamu ìyìn. Ti Dafidi.

145 Èmi yóò gbé ọ ga, Ọlọ́run ọba mi;
    Èmi yóò yin orúkọ rẹ̀ láé àti láéláé
Ní ojoojúmọ́ èmi yóò yìn ọ́
    èmi yóò sì pòkìkí orúkọ rẹ láé àti láéláé.

Títóbi ni Olúwa. Òun sì ni ó yẹ láti fi ìyìn fún púpọ̀púpọ̀:
    kò sí ẹni tí ó lè wọn títóbi rẹ̀.
Ìran kan yóò máa yin iṣẹ́ rẹ dé ìran mìíràn;
    wọn yóò máa sọ iṣẹ́ agbára rẹ
Wọn yóò máa sọ ìyìn ọláńlá rẹ tí ó lógo,
    èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú iṣẹ́ ìyanu rẹ.
Wọn yóò sọ iṣẹ́ agbára rẹ tí ó ní ẹ̀rù
    èmi yóò kéde iṣẹ́ ńlá rẹ̀.
Wọn yóò ṣe ìrántí ọ̀pọ̀lọpọ̀
    ìwà rere rẹ àti orin ayọ̀ òdodo rẹ.

Olóore-ọ̀fẹ́ ni Olúwa àti aláàánú
    ó lọ́ra láti bínú ó sì ní ìfẹ́ púpọ̀.

Filipi 1:21-30

21 (A)Nítorí, ní ti èmi, láti wa láààyè jẹ́ Kristi, láti kú pẹ̀lú sì jẹ́ èrè fún mi. 22 Ṣùgbọ́n bí èmi bá le è ṣe iṣẹ́ ti ó ni àpẹẹrẹ nípa wíwà láààyè nínú ara, ṣùgbọ́n ohun ti èmi ó yàn, èmi kò mọ̀. 23 Ṣùgbọ́n èmi n ṣiyèméjì, nítorí ti èmi fẹ́ láti lọ kúrò nínú ayé yìí, láti wà lọ́dọ̀ Kristi; nítorí ó dára púpọ̀ jù: 24 Síbẹ̀ láti wà láààyè jẹ́ àǹfààní nítorí tiyín. 25 Bí èyí sì ti dá mi lójú, mo mọ̀ pé èmi ó dúró, èmi ó sì máa wà pẹ̀lú yín fún ìtẹ̀síwájú àti ayọ̀ yín nínú ìgbàgbọ́, 26 kí ìṣògo yín kí ó lè di púpọ̀ gidigidi nínú Jesu Kristi, àti nínú mi nípa ìpadà wá mi sọ́dọ̀ yín.

27 Ohun yówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ kí ìgbé ayé yín ri gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere Kristi: pé yálà bi mo tilẹ̀ wá wò yín, tàbí bí èmi kò wá, kí èmi kí ó lè máa gbúròó bí ẹ ti ń ṣe, pé ẹ̀yin dúró ṣinṣin nínú Ẹ̀mí kan, ẹ̀yin jùmọ̀ jìjàkadì nítorí ìgbàgbọ́ ìhìnrere, pẹ̀lú ọkàn kan; 28 (B)Kí ẹ má sì jẹ́ ki àwọn ọ̀tá dẹ́rùbà yin ni ohunkóhun: èyí tí í ṣe ààmì tí ó dájú pé a ó pa wọ́n run, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ni yóò gbà yin là. 29 Nítorí tí a ti fún yin ni àǹfààní, kì í ṣe láti gba Kristi gbọ́ nìkan, ṣùgbọ́n láti jìyà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú: 30 (C)Ẹ sì máa ja ìjà kan náà, èyí ti ẹ̀yin ti ri, ti ẹ sì ti gbọ́ pé èmi n jà pẹ̀lú.

Matiu 20:1-16

Òwe àwọn òṣìṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà

20 (A)“Nítorí ìjọba ọ̀run dàbí ọkùnrin tí ó jẹ́ baálé kan, tí ó jíjáde lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, tí ó gba àwọn alágbàṣe sínú ọgbà àjàrà rẹ̀. Òun pinnu láti san dínárì kan fún iṣẹ́ òòjọ́ kan. Lẹ́yìn èyí ó sì rán wọn lọ sínú ọgbà àjàrà rẹ̀.

“Ní wákàtí kẹta ọjọ́ bí ó ti ń kọjá níwájú ilé ìgbanisíṣẹ́, ó rí díẹ̀ nínú àwọn aláìríṣẹ́ tí wọ́n dúró ní ọjà. Ó wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin pàápàá, ẹ lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà mi, bí ó bá sì di òpin ọjọ́, èmi yóò san iye ti ó bá yẹ fún yín.’ Wọ́n sì lọ.

“Ó tún jáde lọ́sàn án ní nǹkan bí wákàtí kẹfà àti wákàtí kẹsànán, ó túnṣe bákan náà. Lọ́jọ́ kan náà ní wákàtí kọkànlá ọjọ́, ó tún jáde sí àárín ìlú, ó sì rí àwọn aláìríṣẹ́ mìíràn tí wọ́n dúró. Ó bi wọ́n pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin kì í ṣiṣẹ́ ní gbogbo ọjọ́?’

“Wọ́n sì dáhùn pé, ‘Nítorí pé kò sí ẹni tí yóò fún wa ní iṣẹ́ ṣe.’

“Ó tún sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà ẹ jáde lọ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú nínú ọgbà àjàrà mi.’

(B)“Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ẹni tó ni ọgbà àjàrà sọ fún aṣojú rẹ̀ pé, ‘Pe àwọn òṣìṣẹ́ náà, kí ó san owó iṣẹ́ wọn fún wọn, bẹ̀rẹ̀ láti ẹni ìkẹyìn lọ sí ti ìṣáájú.’

“Nígbà tí àwọn ti a pè ní wákàtí kọkànlá ọjọ́ dé, ẹnìkọ̀ọ̀kan gba owó dínárì kan. 10 Nígbà tí àwọn tí a gbà ṣiṣẹ́ lákọ̀ọ́kọ́ fẹ́ gba owó tiwọn, èrò wọn ni pé àwọn yóò gba jù bẹ́ẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gba owó dínárì kan. 11 Bí wọ́n ti ń gbà á, wọ́n ń kùn sí onílẹ̀ náà, 12 pé, ‘Wákàtí kan péré ni àwọn tí a gbà kẹ́yìn fi ṣiṣẹ́, ìwọ sì san iye kan náà fún wọn àti àwa náà ti a fi gbogbo ọjọ́ ṣiṣẹ́ nínú oòrùn gangan.’

13 (C)“Ṣùgbọ́n ó dá ọ̀kan nínú wọn lóhùn pé, ‘Ọ̀rẹ́, kò sí aburú nínú nǹkan tí èmi ṣe sí yín. Kì í ha ṣe pé ẹ̀yin gbà láti ṣiṣẹ́ fún owó dínárì kan. 14 Ó ní, Gba èyí tí í ṣé tìrẹ, ki ó sì máa lọ. Èmi fẹ́ láti fún ẹni ìkẹyìn gẹ́gẹ́ bí mo ti fi fún ọ. 15 Àbí ó lòdì sí òfin pé kí èmi fún ẹnikẹ́ni ní owó mi bí mo bá yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ni ìdí tí ìwọ ní láti bínú nítorí èmi ṣe ohun rere?’

16 (D)“Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹni ìkẹyìn yóò di ẹni ìṣáájú, ẹni ìṣáájú yóò sì di ẹni ìkẹyìn.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.