Revised Common Lectionary (Complementary)
7 “Ọmọ ènìyàn, èmi fi ọ ṣe alóre fún ilé Israẹli; nítorí náà gbọ́ ọ̀rọ̀ tí mo sọ, kí o sì fún wọn ni ìkìlọ̀ láti ọ̀dọ̀ mi. 8 Nígbà ti mo bá sọ fún ẹni búburú pé, ‘A! Ẹni búburú, ìwọ yóò kú dandan,’ ti ìwọ kò sì sọ̀rọ̀ síta láti yí i lọ́kàn padà kúrò ni ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, ẹni búburú náà yóò kú nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, èmi yóò sì béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ. 9 Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá kìlọ̀ fún ẹni búburú láti yí padà kúrò ni ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, tí òun kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, òun yóò kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìwọ ti gba ọkàn rẹ̀ là.
10 “Ọmọ ènìyàn; sọ fún ilé Israẹli, ‘Èyí yìí ní ìwọ sọ: “Àwọn ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ wa tẹ orí wa ba, àwa sì ń ṣòfò dànù nítorí wọn. Bá wó wa ni a ṣe lè yè?” ’ 11 Sọ fún wọn pé, ‘Níwọ́n ìgbà tí mo wà láààyè ni Olúwa Olódùmarè wí, èmi kò ní inú dídùn sí ikú ènìyàn búburú, ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, kí wọ̀nyí padà kúrò ní ọ̀nà wọn gbogbo kì wọn kì ó sì yè. Yí! Yípadà kúrò ni ọ̀nà búburú gbogbo! Kí ló dé tí ìwọ yóò kú Háà! Israẹli?’
Ìlérí Ọlọ́run fún aláforítì
33 Kọ́ mi, Olúwa, láti tẹ̀lé àṣẹ rẹ;
nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin.
34 Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́
èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi.
35 Fi ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ hàn mí,
nítorí nínú rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn.
36 Yí ọkàn mi padà sí òfin rẹ
kí ó má ṣe sí ojúkòkòrò mọ́.
37 Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán:
pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.
38 Mú ìlérí rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ rẹ,
nítorí òfin rẹ dára.
39 Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rù
nítorí tí ìdájọ́ rẹ dára.
40 Kíyèsi i, ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ rẹ!
Pa ayé mi mọ́ nínú òdodo rẹ.
Ẹ jẹ gbèsè ìfẹ́
8 (A)Ẹ má ṣe jẹ ẹnikẹ́ni nígbésè ohun kan, bí kò ṣe pé kí a fẹ́ ọmọ ẹnìkejì ẹni, nítorí ẹni tí ó bá fẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀, ó kó òfin já. 9 (B)Àwọn òfin, “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké,” “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò,” bí òfin mìíràn bá sì wà, ni a papọ̀ ṣọ̀kan nínú òfin kan yìí: “Fẹ́ ẹnìkéjì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀.” 10 (C)Ìfẹ́ kì í ṣe ohun búburú sí ọmọnìkejì rẹ̀: nítorí náà ìfẹ́ ni àkójá òfin.
Ọjọ́ Olúwa fẹ́rẹ dé
11 (D)Àti èyí, bí ẹ̀yin ti mọ àkókò pé, ó ti tó wákàtí nísinsin yìí fún yín láti jí lójú orun: nítorí nísinsin yìí ni ìgbàlà wa súnmọ́ etílé ju ìgbà tí àwa ti gbàgbọ́ lọ. 12 (E)Òru bù kọjá tan, ilẹ̀ sì fẹ́rẹ mọ́: nítorí náà ẹ jẹ́ kí a bọ́ ara iṣẹ́ òkùnkùn sílẹ̀, kí a sì gbé ìhámọ́ra ìmọ́lẹ̀ wọ̀. 13 (F)Jẹ́ kí a má rin ìrìn títọ́, bí ní ọ̀sán; kì í ṣe ní ìréde òru àti ní ìmutípara, kì í ṣe ni ìwà èérí àti wọ̀bìà, kì í ṣe ní ìjà àti ìlara. 14 (G)Ṣùgbọ́n ẹ gbé Jesu Kristi Olúwa wọ̀, kí ẹ má sì pèsè fún ara, láti máa mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀ ṣẹ.
Arákùnrin tí ó ṣẹ̀ sí ọ
15 (A)“Bí arákùnrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, lọ ní ìkọ̀kọ̀ kí o sì sọ ẹ̀bi rẹ̀ fún un. Bí ó bá gbọ́ tìrẹ, ìwọ ti mú arákùnrin kan bọ̀ sí ipò. 16 Ṣùgbọ́n bí òun kò bá tẹ́tí sí ọ, nígbà náà mú ẹnìkan tàbí ẹni méjì pẹ̀lú rẹ, kí ẹ sì tún padà sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, kí ọ̀rọ̀ náà bá le fi ìdí múlẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta náà. 17 Bí òun bá sì tún kọ̀ láti tẹ́tí sí wọn, nígbà náà sọ fún ìjọ ènìyàn Ọlọ́run. Bí o bá kọ̀ láti gbọ́ ti ìjọ ènìyàn Ọlọ́run, jẹ́ kí ó dàbí kèfèrí sí ọ tàbí agbowó òde.
18 (B)“Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ohunkóhun tí ẹ̀yin bá dè ní ayé, ni a dè ní ọ̀run. Ohunkóhun ti ẹ̀yin bá sì ti tú ni ayé, á ò tú u ní ọ̀run.
19 (C)“Mo tún sọ èyí fún yín, bí ẹ̀yin méjì bá fi ohùn ṣọ̀kan ní ayé yìí, nípa ohunkóhun tí ẹ béèrè, Baba mi ti ń bẹ ní ọ̀run yóò sì ṣe é fún yín. 20 Nítorí níbi ti ènìyàn méjì tàbí mẹ́ta bá kó ara jọ ni orúkọ mi, èmi yóò wà láàrín wọn níbẹ̀.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.