Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 17

Àdúrà ti Dafidi

17 Gbọ́, Olúwa, ẹ̀bẹ̀ òtítọ́ mi;
    fi etí sí igbe mi.
Tẹ́tí sí àdúrà mi
    tí kò ti ètè ẹ̀tàn jáde.
Kí ìdáláre mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ;
    kí ojú rẹ kí ó rí ohun tí ó tọ́.

Ìwọ ti dán àyà mi wò,
    ìwọ sì bẹ̀ mí wò ní òru, o sì ti wádìí mi,
ìwọ kì yóò rí ohunkóhun èmi ti pinnu pé,
    ẹnu mi kì yóò ṣẹ̀.
Bí ó ṣe ti iṣẹ́ ènìyàn nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ,
    èmi ti pa ara mi mọ́
    kúrò ní ọ̀nà àwọn ìkà.
Ìrìn mí ti jẹ mọ́ ọ̀nà rẹ;
    ẹsẹ̀ mi kì yóò yọ̀.

Èmi ké pè ọ́, Ọlọ́run, nítorí tí ìwọ yóò dá mi lóhùn
    dẹ etí rẹ sí mi kí o sì gbọ́ àdúrà mi.
Fi ìṣeun ìyanu ìfẹ́ ńlá rẹ hàn
    ìwọ tí ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là
    lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn.
Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú rẹ;
    fi mí pamọ́ sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ,
lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú tí ń fóròó mi,
    kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká.

10 Wọ́n pa ọkàn aláìláàánú wọn mọ́,
    wọ́n sì fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ ìgbéraga.
11 Wọ́n sì mú mi mọ́lẹ̀, wọ́n sì yí mi ká,
    pẹ̀lú ojú ìṣọ́ra láti ṣọ́ mi sílẹ̀.
12 Wọn dàbí i kìnnìún tí ebi ń pa fún ìjẹ,
    àní bí kìnnìún ńlá tí ó ń ba níbi ìkọ̀kọ̀.

13 Dìde, Olúwa, dojúkọ wọ́n, rẹ̀ wọ́n sílẹ̀;
    gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹni búburú nípa idà rẹ.
14 Olúwa, nípa ọwọ́ rẹ, gbà mí kúrò lọ́wọ́ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀,
    kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ayé yìí, tí èrè wọn wà nínú ayé yìí.
Ìwọ ń pa ebi àwọn tí ìwọ fẹ́ràn lẹ́nu mọ́;
    àwọn ọmọ wọn sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀,
    wọ́n sì kó ọrọ̀ jọ fún àwọn ọmọ wọn.

15 Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò máa wo ojú rẹ ní òdodo;
    nígbà tí èmi bá jí, èmi yóò ní ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí èmi bá rí àwòrán rẹ.

Jeremiah 17:5-18

Báyìí ni Olúwa wí:

“Ègbé ni fún àwọn tí ó fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú ènìyàn,
    tí ó fi agbára rẹ̀ sínú ẹran-ara,
    àti tí ọkàn rẹ̀ kò sí lọ́dọ̀ Olúwa
Yóò dàbí igbó tí ó wà ní ilẹ̀ aláìlọ́ràá,
    kò ní rí ìre, nígbà tí ó bá dé,
yóò máa gbé ní ibi ìyàngbẹ ilẹ̀ aginjù,
    ní ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé.

(A)“Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ọkùnrin
    náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, tí ó sì fi
    Olúwa ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀.
Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadò
    tí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odò
kò sí ìbẹ̀rù fún un nígbà ooru,
    gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutù
kò sí ìjayà fún un ní ọdún ọ̀dá
    bẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.”

Ọkàn ènìyàn kún fún ẹ̀tàn ju ohun
    gbogbo lọ, ó kọjá ohun tí a lè
    wòsàn, ta ni èyí lè yé?

10 (B)“Èmi Olúwa ń wo ọkàn àti èrò
    inú ọmọ ènìyàn láti san èrè
iṣẹ́ rẹ̀ fún un, gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ̀
    àti gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.”

11 Bí àparò tó pa ẹyin tí kò yé ni
    ọmọ ènìyàn tí ó kó ọrọ̀ jọ ni
ọ̀nà àìṣòdodo. Yóò di ẹni ìkọ̀sílẹ̀
    ní agbede-méjì ayé rẹ̀, àti ní
    òpin rẹ̀ yóò wá di aṣiwèrè.

12 Ìtẹ́ ògo; ibi gíga láti ìpilẹ̀ṣẹ̀
    ní ibi ilé mímọ́ wa.
13 Olúwa ìwọ ni ìrètí Israẹli;
    gbogbo àwọn tí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ni ojú ó tì.
Àwọn tí ó padà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ
ni a ó kọ orúkọ wọn sínú ekuru,
    nítorí wọ́n ti kọ Olúwa,
    orísun omi ìyè sílẹ̀.

14 Wò mí sàn Olúwa, èmi yóò di ẹni ìwòsàn,
    gbà mí là, èmi yóò di ẹni ìgbàlà,
    nítorí ìwọ ni ìyìn mi.
15 Wọ́n sọ fún mi wí pé:
    “Níbo ni ọ̀rọ̀ Olúwa wà?
    Jẹ́ kí ó di ìmúṣẹ báyìí.”
    Ni Olúwa wí.
16 Èmi kò sá kúrò láti máa jẹ́ olùṣọ àgùntàn rẹ,
    ìwọ mọ̀ wí pé èmi kò kẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ ìpọ́njú.
Ohun tí ó jáde ní ètè mi jẹ́ èyí tí ó hàn sí ọ.
17 Má ṣe di ìbẹ̀rù fún mi,
    ìwọ ni ààbò mi ní ọjọ́ ìpọ́njú.
18 Jẹ́ kí ojú ti àwọn ẹni tí ń lépa mi,
    ṣùgbọ́n pa mí mọ́ kúrò nínú ìtìjú,
jẹ́ kí wọn kí ó dààmú.
    Mú ọjọ́ ibi wá sórí wọn,
    fi ìparun ìlọ́po méjì pa wọ́n run.

Matiu 12:22-32

Jesu àti Beelsebulu

22 (A)(B) Nígbà náà ni wọ́n mú ọkùnrin kan tó ni ẹ̀mí èṣù tọ̀ ọ́ wá, tí ó afọ́jú, tí ó tún ya odi. Jesu sì mú un láradá kí ó le sọ̀rọ̀, ó sì ríran. 23 Ẹnu sì ya gbogbo àwọn ènìyàn. Wọ́n wí pé, “Èyí ha lè jẹ́ Ọmọ Dafidi bí?”

24 (C)Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Farisi gbọ́ èyí, wọ́n wí pé, “Nípa Beelsebulu nìkan, tí í ṣe ọba ẹ̀mí èṣù ni ọkùnrin yìí fi lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”

25 Jesu tí ó mọ èrò wọn, ó wí fún wọn pé, “Ìjọbakíjọba tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ yóò parun, ìlúkílùú tàbí ilékílé tí ó bá yapa sí ara rẹ̀ kì yóò dúró. 26 Bí èṣù bá sì ń lé èṣù jáde, a jẹ́ wí pé, ó ń yapa sí ara rẹ̀. Ìjọba rẹ yóò ha ṣe le dúró? 27 Àti pé, bi èmi bá ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde nípa Beelsebulu, nípa ta ni àwọn ènìyàn yín fi ń lé wọn jáde? Nítorí náà ni wọn yóò ṣe má ṣe ìdájọ́ yín. 28 Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé nípa Ẹ̀mí Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, a jẹ́ pé ìjọba Ọlọ́run ti dé bá yín.

29 “Tàbí, báwo ni ẹnikẹ́ni ṣe lè wọ ilé alágbára lọ kí ó sì kó ẹrù rẹ̀, bí kò ṣe pé ó kọ́kọ́ di alágbára náà? Nígbà náà ni ó tó lè kó ẹrù rẹ̀ lọ.

30 (D)“Ẹni tí kò bá wà pẹ̀lú mi, òun lòdì sí mi, ẹni tí kò bá mi kójọpọ̀ ń fọ́nká. 31 Nítorí èyí, mo wí fún yín, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti ọ̀rọ̀-òdì ni a yóò dárí rẹ̀ jí ènìyàn, ṣùgbọ́n ìṣọ̀rọ̀-òdì-sí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ní ìdáríjì. 32 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí Ọmọ ènìyàn, a ó dáríjì í, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀-òdì sí ẹ̀mí mímọ́, a kì yóò dáríjì í, ìbá à ṣe ní ayé yìí tàbí ní ayé tí ń bọ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.