Revised Common Lectionary (Complementary)
Ti Dafidi
138 Èmi yóò yìn ọ́ tinútinú mi gbogbo;
níwájú àwọn òrìṣà ni èmi ó kọrin ìyìn sí ọ.
2 Èmi ó máa gbàdúrà sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀
èmi ó sì máa yin orúkọ rẹ
nítorí ìṣeun ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ;
nítorí ìwọ gbé ọ̀rọ̀ rẹ ga ju orúkọ rẹ lọ.
3 Ní ọjọ́ tí mo ké pè é ọ́, ìwọ dá mi lóhùn,
ìwọ sì fi ipa mú mi lára le ní ọkàn mi.
4 Gbogbo àwọn ọba ayé yóò yìn ọ́,
Olúwa, ní ìgbà tí wọn bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ
5 Nítòótọ́, wọn ó máa kọrin ní ipa ọ̀nà Olúwa;
nítorí pé ńlá ni ògo Olúwa.
6 Bí Olúwa tilẹ̀ ga, síbẹ̀ ó júbà àwọn onírẹ̀lẹ̀;
ṣùgbọ́n agbéraga ni ó mọ̀ ní òkèrè réré.
7 Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di ààyè;
ìwọ ó na ọwọ́ rẹ sí àwọn ọ̀tá mi,
ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò sì gbà mí.
8 Olúwa yóò ṣe ohun tí ń ṣe tèmi láṣepé;
Olúwa, àánú rẹ dúró láéláé;
Má ṣe kọ iṣẹ́ ọwọ́ ara rẹ sílẹ̀.
33 “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ tí mo wẹ̀ yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo, èmi yóò ṣe àtúnṣe àwọn ìlú yín, wọn yóò sì ṣe àtúnkọ́ ìwólulẹ̀. 34 Ilẹ̀ ahoro náà ní àwa yóò tún kọ́ ti kì yóò wà ní ahoro lójú àwọn tí ó ń gba ibẹ̀ kọjá mọ́. 35 Wọn yóò sọ wí pé, “Ilẹ̀ yìí tí ó ti wà ní ahoro tẹ́lẹ̀ ti dàbí ọgbà Edeni; àwọn ìlú tí ó wà ní wíwó lulẹ̀, ahoro tí a ti parun, ni àwa yóò mọdi sí tí yóò sì wà fún gbígbé ni ìsinsin yìí.” 36 Nígbà náà àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní àyíká yín tí ó kù yóò mọ̀ pé èmi Olúwa ti tún àwọn ohun tí ó bàjẹ́ kọ́, mo sì ti tún ohun tí ó di ìṣòfo gbìn. Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀, èmi yóò sì ṣe e?’
37 “Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè sọ: Lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò yí sí ilé Israẹli, èmi yóò sì ṣe èyí fún wọn. Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn yín pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ bí àgùntàn, 38 Kí ó pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ bí ọ̀wọ́ ẹran fún ìrúbọ ní Jerusalẹmu ní àsìkò àjọ̀dún tí a yàn. Ìlú ti a parun yóò wá kún fún agbo àwọn ènìyàn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”
Ìwúkàrà Farisi àti Sadusi
5 (A)Nígbà tí wọ́n dé apá kejì adágún, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ṣàkíyèsí pé wọ́n ti gbàgbé láti mú àkàrà kankan lọ́wọ́. 6 (B)Jesu sì kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ kíyèsára, ẹ sì ṣọ́ra, ní ti ìwúkàrà àwọn Farisi àti àwọn Sadusi.”
7 Wọ́n ń sọ eléyìí ni àárín ara wọn wí pé, “Nítorí tí àwa kò mú àkàrà lọ́wọ́ ni.”
8 (C)Nígbà tí ó gbọ́ ohun ti wọ́n ń sọ, Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré, èéṣe tí ẹ̀yin ń dààmú ara yín pé ẹ̀yin kò mú oúnjẹ lọ́wọ́? 9 Tàbí ọ̀rọ̀ kò yé yín di ìsinsin yìí? Ẹ̀yin kò rántí pé mo bọ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (5,000) ènìyàn pẹ̀lú ìṣù àkàrà márùn-ún àti iye agbọ̀n tí ẹ kójọ bí àjẹkù? 10 Ẹ kò sì tún rántí ìṣù méje tí mo fi bọ́ ẹgbàajì (4,000) ènìyàn àti iye agbọ̀n tí ẹ̀yín kójọ? 11 Èéha ṣe tí kò fi yé yín pé èmi kò sọ̀rọ̀ nípa ti àkàrà? Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo wí fún yín, ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisi àti ti Sadusi.” 12 Nígbà náà ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wáyé wọn pé, kì í ṣe nípa ti ìwúkàrà ní ó sọ wí pé kí wọ́n kíyèsára, bí kò ṣe tí ẹ̀kọ́ àwọn Farisi àti Sadusi.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.