Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 78:1-8

Maskili ti Asafu.

78 Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ mi;
    tẹ́tí rẹ sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
(A)Èmi ó la ẹnu mi ní òwe,
    èmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́;
Ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀,
    ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa.
Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́
    kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ,
ní fífi ìyìn Olúwa, àti ipa rẹ̀
    àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn
fún ìran tí ń bọ̀.
Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jakọbu
    o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Israẹli,
èyí tí ó pàṣẹ fún àwọn baba ńlá wa
    láti kọ́ àwọn ọmọ wọn,
Nítorí náà, àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́n
    bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí
    tí yóò dìde tí wọn yóò sọ fún àwọn ọmọ wọn
Nígbà náà ni wọ́n ò fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú Ọlọ́run
    wọn kò sì ní gbàgbé iṣẹ́ Ọlọ́run
    ṣùgbọ́n wọn ó pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
Kí wọn kí ó má ṣe dàbí àwọn baba ńlá wọn,
    ìran alágídí àti ọlọ́tẹ̀,
    ìran tí ọkàn wọn kò ṣọ òtítọ́ si olóore,
    àti ẹ̀mí ẹni tí kò bá Ọlọ́run dúró ṣinṣin.

Saamu 78:17-29

17 Wọ́n sì tún tẹ̀síwájú láti dẹ́ṣẹ̀ sí i
    ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo ní aginjù.
18 Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wò
    nípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún
19 Wọ́n sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, wí pé
    “Ọlọ́run ha lè tẹ́ tábìlì ní aginjù?
20 Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde,
    odò sì sàn lọ́pọ̀lọpọ̀
ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ
    ó ha le pèsè ẹran fún àwọn ènìyàn rẹ̀”
21 Nígbà tí Olúwa gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi;
iná rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jakọbu,
ìbínú rẹ̀ sì rú sí Israẹli,
22 Nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́,
    wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé ìgbàlà rẹ̀.
23 Síbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀run,
    ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀;
24 (A)Ó rọ manna fún àwọn ènìyàn láti jẹ,
    ó fún wọn ní ọkà láti ọ̀run.
25 Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn angẹli;
    Ó fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó,
26 Ó mú afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn láti ọ̀run wá
    ó mú afẹ́fẹ́ gúúsù wá nípa agbára rẹ̀.
27 Ó rọ òjò ẹran sílẹ̀ sórí wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀,
    àti ẹyẹ abìyẹ́ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí Òkun
28 Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn,
    yíká àgọ́ wọn.
29 Wọ́n jẹ, wọ́n sì yó jọjọ
    nítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún

Eksodu 16:2-15

Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli sì ń kùn sí Mose àti Aaroni ní ijù náà. (A)Àwọn ọmọ Israẹli wí fún wọn pé, “Àwa ìbá ti ọwọ́ Olúwa kú ni Ejibiti! Níbi tí àwa ti jókòó ti ìkòkò ẹran ti a sì ń jẹ ohun gbogbo tí a fẹ́ ni àjẹyó, ṣùgbọ́n ẹ̀yin mú wa wá sí inú ijù yìí láti fi ebi pa wá tí a ó fi kú.”

(B)Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Èmi yóò rọ òjò oúnjẹ láti ọ̀run wá fún yín. Àwọn ènìyàn yóò sì máa jáde lọ ni ọjọ́ kọ̀ọ̀kan láti kó ìwọ̀nba oúnjẹ ti ó tó fún oúnjẹ òòjọ́ wọn. Ní ọ̀nà yìí ni, èmi yóò fi dán wọn wò láti mọ bóyá wọn yóò máa tẹ̀lé ìlànà mi. Ní ọjọ́ kẹfà, ki wọn kó ìlọ́po méjì èyí tiwọn ń ko ni ojoojúmọ́ tẹ́lẹ̀.”

Mose àti Aaroni sọ fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ní ìrọ̀lẹ́, ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Olúwa ni ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá. Ní òwúrọ̀, ẹ̀yin yóò ri ògo Olúwa, nítorí òun ti gbọ́ kíkùn tí ẹ kùn sí i. Ta ni àwa ti ẹ̀yin yóò máa kùn sí wa?” Mose tún wí pé, “Ẹ̀yin yóò mọ pé Olúwa ni, nígbà ti ó bá fún un yín ni ẹran ni ìrọ̀lẹ́ àti gbogbo oúnjẹ ti ẹ̀yin ń fẹ́ ni òwúrọ̀, nítorí kíkùn ti ẹ̀yin ń kùn sí i. Ta ni àwa? Ẹ̀yin kò kùn sí àwa, Olúwa ni ẹ̀yin kùn sí i.”

Nígbà náà ni Mose sọ fún Aaroni pe, “Sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pe, ‘Ẹ wá sí iwájú Olúwa, nítorí òun ti gbọ́ kíkùn yín.’ ”

10 Ó sì ṣe bí Aaroni ti ń bá gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, wọn si bojú wo ìhà ijù, sì kíyèsi ògo Olúwa si farahàn ni àwọsánmọ̀.

11 Olúwa sọ fún Mose pé, 12 “Èmi ti gbọ́ kíkùn àwọn ọmọ Israẹli. Sọ fun wọn, ‘Ní àṣálẹ́, ẹ̀yin yóò jẹ ẹran, àti ni òwúrọ̀ ni ẹ̀yin yóò jẹ oúnjẹ. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”

13 Ní àṣálẹ́ ọjọ́ náà ni àwọn àparò fò dé, wọ́n sì bo àgọ́ mọ́lẹ̀, ní òwúrọ̀ ìrì sì sẹ̀ yí gbogbo àgọ́ náà ká. 14 Nígbà tí ìrì tí ó sẹ̀ bo ilẹ̀ ti lọ, kíyèsi i, ohun tí ó dì, tí ó sì ń yooru bí i yìnyín wà lórí ilẹ̀. 15 (C)Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli rí i, wọ́n bi ara wọn léèrè pé, “Kí ni èyí?” Nítorí pé wọn kò mọ ohun tí i ṣe.

Mose sì wí fún wọn pé, “Èyí ni oúnjẹ tí Olúwa fi fún un yín láti jẹ.

Eksodu 16:31-35

31 (A)Àwọn ènìyàn Israẹli sì pe oúnjẹ náà ní manna. Ó funfun bí irúgbìn korianderi, ó sì dùn bí àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ ti a fi oyin ṣe. 32 Mose wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: ‘Ẹ mú òṣùwọ̀n omeri manna kí ẹ sì pa á mọ́ de àwọn ìran ti ń bọ̀, kí wọn kí ó lè rí oúnjẹ ti èmi fi fún un yín jẹ ní ijù, nígbà tí mo mú un yín jáde ni ilẹ̀ Ejibiti.’ ”

33 Nígbà náà ni Mose sọ fún Aaroni pe, “Mú ìkòkò kan, kí o sì kó manna tí ó kún òṣùwọ̀n omeri kan sí inú rẹ̀, kí o sì gbé e kalẹ̀ ni iwájú Olúwa láti tọ́jú rẹ̀ pamọ́ de àwọn ìran ti ń bọ̀.”

34 Olúwa ti pàṣẹ fún Mose, Aaroni gbé manna sí iwájú ẹ̀rí láti pa á mọ́. 35 Àwọn ará Israẹli jẹ manna fún ogójì ọdún títí wọ́n fi dé ilẹ̀ Kenaani ni ibi ti èso ti wà fún wọn láti jẹ; Wọ́n jẹ manna títí tí wọ́n fi dé ilẹ̀ agbègbè Kenaani.

Matiu 15:32-39

32 (A)(B) Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀, ó wí pé, “Àánú àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe mí; nítorí wọ́n ti wà níhìn-ín pẹ̀lú mi fún ọjọ́ mẹ́ta gbáko báyìí. Wọn kò sì tún ní oúnjẹ mọ́. Èmi kò fẹ́ kí wọn padà lébi, nítorí òyì lè kọ́ wọn lójú ọ̀nà.”

33 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì dá a lóhùn pé, “Níbo ni àwa yóò ti rí oúnjẹ ní ijù níhìn-ín yìí láti fi bọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn yìí?”

34 Jesu sì béèrè pé, “ìṣù àkàrà mélòó ni ẹ̀yin ní?”

Wọ́n sì dáhùn pé, “Àwa ní ìṣù àkàrà méje pẹ̀lú àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀.”

35 Jesu sì sọ fún gbogbo ènìyàn kí wọn jókòó lórí ilẹ̀. 36 Òun sì mú ìṣù àkàrà méje náà àti ẹja náà. Ó sì fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run, ó bù wọ́n sì wẹ́wẹ́, ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n sì pín in fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn náà. 37 Gbogbo wọn jẹ, wọ́n sì yó. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì ṣa èyí tókù, ẹ̀kún agbọ̀n méje ni èyí tó ṣẹ́kù jẹ́ 38 Gbogbo wọn sì jẹ́ ẹgbàajì (4,000) ọkùnrin láì kan àwọn obìnrin àti ọmọdé. 39 Lẹ́yìn náà, Jesu rán àwọn ènìyàn náà lọ sí ilé wọn, ó sì bọ́ sínú ọkọ̀, ó rékọjá lọ sí ẹkùn Magadani.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.