Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 78:1-8

Maskili ti Asafu.

78 Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ mi;
    tẹ́tí rẹ sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
(A)Èmi ó la ẹnu mi ní òwe,
    èmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́;
Ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀,
    ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa.
Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́
    kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ,
ní fífi ìyìn Olúwa, àti ipa rẹ̀
    àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn
fún ìran tí ń bọ̀.
Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jakọbu
    o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Israẹli,
èyí tí ó pàṣẹ fún àwọn baba ńlá wa
    láti kọ́ àwọn ọmọ wọn,
Nítorí náà, àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́n
    bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí
    tí yóò dìde tí wọn yóò sọ fún àwọn ọmọ wọn
Nígbà náà ni wọ́n ò fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú Ọlọ́run
    wọn kò sì ní gbàgbé iṣẹ́ Ọlọ́run
    ṣùgbọ́n wọn ó pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
Kí wọn kí ó má ṣe dàbí àwọn baba ńlá wọn,
    ìran alágídí àti ọlọ́tẹ̀,
    ìran tí ọkàn wọn kò ṣọ òtítọ́ si olóore,
    àti ẹ̀mí ẹni tí kò bá Ọlọ́run dúró ṣinṣin.

Saamu 78:17-29

17 Wọ́n sì tún tẹ̀síwájú láti dẹ́ṣẹ̀ sí i
    ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo ní aginjù.
18 Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wò
    nípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún
19 Wọ́n sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, wí pé
    “Ọlọ́run ha lè tẹ́ tábìlì ní aginjù?
20 Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde,
    odò sì sàn lọ́pọ̀lọpọ̀
ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ
    ó ha le pèsè ẹran fún àwọn ènìyàn rẹ̀”
21 Nígbà tí Olúwa gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi;
iná rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí Jakọbu,
ìbínú rẹ̀ sì rú sí Israẹli,
22 Nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́,
    wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé ìgbàlà rẹ̀.
23 Síbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀run,
    ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀;
24 (A)Ó rọ manna fún àwọn ènìyàn láti jẹ,
    ó fún wọn ní ọkà láti ọ̀run.
25 Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn angẹli;
    Ó fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó,
26 Ó mú afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn láti ọ̀run wá
    ó mú afẹ́fẹ́ gúúsù wá nípa agbára rẹ̀.
27 Ó rọ òjò ẹran sílẹ̀ sórí wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀,
    àti ẹyẹ abìyẹ́ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí Òkun
28 Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn,
    yíká àgọ́ wọn.
29 Wọ́n jẹ, wọ́n sì yó jọjọ
    nítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún

Deuteronomi 26:1-15

Àkọ́so àti ìdámẹ́wàá

26 (A)Nígbà tí ìwọ bá wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní tí ìwọ sì ti jogún, tí ìwọ sì ti ń gbé níbẹ̀, mú díẹ̀ nínú ohun tí o pèsè láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ, kó wọn sínú agbọ̀n. Nígbà náà kí o lọ sí ibi tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibi tí orúkọ rẹ̀ yóò máa gbé. Kí o sì sọ fun àlùfáà tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní àsìkò náà, pé “Mo sọ ọ́ di mí mọ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pé mo ti wá sí ilẹ̀ tí Olúwa búra fún àwọn baba wa.” Àlùfáà yóò gbé agbọ̀n náà kúrò ní ọwọ́ rẹ, yóò sì gbé e kalẹ̀ níwájú pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní iwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ pé, “Baba mi jẹ́ alárìnkiri ará Aramu, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Ejibiti pẹ̀lú ènìyàn díẹ̀, ó sì ń gbé níbẹ̀, ó sì wá di orílẹ̀-èdè olókìkí, alágbára, tí ó kún fún ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ṣùgbọ́n àwọn ará Ejibiti ṣe àìdára sí wa, wọ́n jẹ wá ní yà, wọ́n fún wa ní iṣẹ́ líle ṣe. Nígbà náà ni a kégbe pe Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wa, Olúwa sì gbọ́ ohùn wa, ó sì rí ìrora, làálàá àti ìnira wa. Nígbà náà ni Olúwa mú wa jáde wá láti Ejibiti pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà, pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá àti iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu. Ó mú wa wá síbí, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; 10 àti pé ní báyìí, mo mú àkọ́so ilẹ̀ tí ìwọ Olúwa ti fún mi wá.” Ìwọ yóò gbé agbọ̀n náà síwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì wólẹ̀ níwájú u rẹ̀. 11 Ìwọ àti àwọn ọmọ Lefi àti àjèjì láàrín yín yóò máa yọ̀ nínú gbogbo oore tí Olúwa ti fi fún ọ àti fún àwọn ará ilé rẹ.

12 Nígbà tí ìwọ bá ṣetán láti ya ìdámẹ́wàá gbogbo ohun tí o ti mú jáde ní ọdún kẹta sọ́tọ̀ sí apá kan. Ọdún ìdámẹ́wàá, ìwọ yóò fi fún ọmọ Lefi, àjèjì, aláìní baba àti opó, kí wọn kí ó lè jẹ ní àwọn ìlú rẹ, kí wọn sì yó. 13 Nígbà náà ní kí o wí fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pé, “Èmi ti mú ohun mímọ́ kúrò nínú ilé mi, èmi sì ti fi fún àwọn Lefi, àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba àti àwọn opó, gẹ́gẹ́ bí ohun gbogbo tí ìwọ ti pàṣẹ. Èmi kò yípadà kúrò nínú àṣẹ rẹ bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gbàgbé ọ̀kankan nínú wọn. 14 Èmi kò jẹ lára ohun mímọ́ ní ìgbà tí mo ń ṣọ̀fọ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mu nínú wọn ní ìgbà tí mo wà ní àìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi nínú wọn fún òkú. Èmi ti ṣe ìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run mi, èmi sì ti ṣe gbogbo ohun tí ó pàṣẹ fún mi. 15 Wo ilẹ̀ láti ọ̀run wá, ibùgbé mímọ́ rẹ, kí o sì bùkún fún àwọn ènìyàn Israẹli, àti fún ilẹ̀ náà tí ìwọ ti fi fún wa, bí ìwọ ti búra fún àwọn baba ńlá wa, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti fún oyin.”

Ìṣe àwọn Aposteli 2:37-47

37 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, ọkàn wọn gbọgbẹ́, wọn sì wí fún Peteru àti àwọn aposteli yòókù pé, “Ará, kín ni àwa yóò ṣe?”

38 Peteru sì wí fún wọn pé, “Ẹ ronúpìwàdà, kí a sì bamitiisi olúkúlùkù yín ní orúkọ Jesu Kristi fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹ̀yin yóò sì gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ 39 (A)Nítorí fún yín ni ìlérí náà, àti fún àwọn ọmọ yín, àti fún gbogbo àwọn tí ó jìnnà réré, àní gbogbo àwọn tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò pè.”

40 Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ púpọ̀ mìíràn ni ó fi ń kìlọ̀ tí ó sì ń fi ń rọ̀ wọ́n wí pé, “Ẹ gba ara yín là lọ́wọ́ ìran àrékérekè yìí.” 41 Nítorí náà àwọn tí ó fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ a bamitiisi wọn, lọ́jọ́ náà a sì kà ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọkàn kún wọn.

Ìsọ̀kan àwọn ará tí o gbàgbọ́

42 Wọ́n sì dúró ṣinṣin nínú ẹ̀kọ́ àwọn aposteli, àti ní ìdàpọ̀, ní bíbu àkàrà àti nínú àdúrà. 43 Ẹ̀rù sí ba gbogbo ọkàn; iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ ààmì púpọ̀ ni a ti ọwọ́ àwọn aposteli ṣe. 44 (B)Gbogbo àwọn tí ó sì gbàgbọ́ wà ni ibìkan, wọn ní ohun gbogbo sọ́kàn; 45 Wọn si ń ta ohun ìní àti ẹrù wọn, wọn sì ń pín wọn fún olúkúlùkù, gẹ́gẹ́ bí ẹnikẹ́ni tí í ṣe aláìní sí. 46 Wọ́n fi ọkàn kan dúró lójoojúmọ́ nínú tẹmpili. Wọ́n ń bu àkàrà ní ilé wọn, wọn ń fi inú dídùn àti ọkàn òtítọ́ jẹ oúnjẹ wọn. 47 Wọ́n yín Ọlọ́run, wọn sì rí ojúrere lọ́dọ̀ ènìyàn gbogbo, Olúwa sí ń yàn kún wọn lójoojúmọ́, àwọn tí à ń gbàlà.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.