Revised Common Lectionary (Complementary)
5 Ní Gibeoni, Olúwa fi ara han Solomoni lójú àlá ní òru, Ọlọ́run sì wí pé, “Béèrè fún ohunkóhun tí o bá ń fẹ́ kí èmi ó fi fún ọ.”
6 Solomoni sì dáhùn wí pé, “O ti fi inú rere oore ńlá hàn sí ìránṣẹ́ rẹ, Dafidi baba mi, nítorí ó jẹ́ olóòtítọ́ sí ọ àti olódodo àti ẹni tí ó ní ọkàn ìdúró ṣinṣin. Ìwọ sì tẹ̀síwájú nínú oore ńlá yìí fún un, ìwọ sì ti fún un ní ọmọkùnrin láti jókòó lórí ìtẹ́ rẹ ní gbogbo ọjọ́.
7 “Nísinsin yìí, Olúwa Ọlọ́run mi, o ti mú ìránṣẹ́ rẹ jẹ ọba ní ipò Dafidi baba mi. Ṣùgbọ́n ọmọ kékeré ni mí, èmi kò sì mọ jíjáde àti wíwọlé mi. 8 Ìránṣẹ́ rẹ nìyí láàrín àwọn ènìyàn tí o ti yàn, àwọn ènìyàn ńlá, wọ́n pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí a kò sì lè kà wọ́n tàbí mọye wọn. 9 Nítorí náà fi ọkàn ìmòye fún ìránṣẹ́ rẹ láti le ṣàkóso àwọn ènìyàn rẹ àti láti mọ ìyàtọ̀ láàrín rere àti búburú. Nítorí ta ni ó lè ṣe àkóso àwọn ènìyàn ńlá rẹ yìí?”
10 Inú Olúwa sì dùn pé Solomoni béèrè nǹkan yìí. 11 Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ ti béèrè fún èyí, tí kì í ṣe ẹ̀mí gígùn tàbí ọrọ̀ fún ara rẹ, tàbí béèrè fún ikú àwọn ọ̀tá rẹ, ṣùgbọ́n fún òye láti mọ ẹjọ́ dá, 12 èmi yóò ṣe ohun tí ìwọ ti béèrè. Èmi yóò fún ọ ní ọgbọ́n àti ọkàn ìmòye, tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí ẹnìkan tí ó dàbí rẹ ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kì yóò dìde tí yóò dàbí rẹ lẹ́yìn rẹ.
Àdúrà láti lè pa òfin Olúwa mọ́
129 Òfin rẹ̀ ìyanu ni:
nítorí náà èmi gbà wọ́n gbọ́.
130 Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá;
ó fi òye fún àwọn òpè.
131 Èmi ya ẹnu mi mo sì mí hẹlẹ,
nítorí èmi fojú ṣọ́nà sí àṣẹ rẹ.
132 Yí padà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi,
bí ìwọ ṣe máa ń ṣe nígbà gbogbo sí àwọn
tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ.
133 Fi ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ,
má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ borí mi.
134 Rà mí padà lọ́wọ́ aninilára ènìyàn,
kí èmi lè gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ.
135 Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tàn sí ìránṣẹ́ rẹ lára
kí ó sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
136 Omijé sàn jáde ní ojú mi,
nítorí wọn kò gba pé òfin rẹ̀ jẹ́ òtítọ́.
26 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ẹ̀mí pẹ̀lú sì ń ran àìlera wa lọ́wọ́: nítorí a kò mọ bí a ti ń gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ: ṣùgbọ́n ẹ̀mí tìkára rẹ̀ ń fi ìrora tí a kò le fi ẹnu sọ bẹ̀bẹ̀ fún wa. 27 (A)Ẹni tí ó sì ń wá inú ọkàn wò, ó mọ ohun ti ẹ̀mí, nítorí tí ó ń bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ènìyàn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run.
28 Àwa sì mọ̀ pé ohun gbogbo ni ó ń ṣiṣẹ́ pọ̀ sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ Ọlọ́run, àní fún àwọn ẹni tí a pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀. 29 (B)Nítorí àwọn ẹni tí ó mọ̀ tẹ́lẹ̀, ni ó sì yàn tẹ́lẹ̀ láti rí bí àwòrán ọmọ rẹ̀, kí òun lè jẹ́ àkọ́bí láàrín àwọn arákùnrin púpọ̀ 30 Àti pé lẹ́yìn tí òun ti pè wá wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sọ wá di “aláìjẹ̀bi” lẹ́yìn èyí, ó fi rere Kristi kún inú ọkàn wa. Lékè gbogbo rẹ̀, ó fún wa ní ìdúró rere pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pinu ògo rẹ̀ fún wa.
Jíju aṣẹ́gun lọ
31 (C)Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa? 32 (D)Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti fi Ọmọ rẹ̀ fún wa, ǹjẹ́ ó ha tún le ṣòro fún un láti fún wa ní ohunkóhun bí? 33 (E)Ta ni ẹni náà tí ó lè dá wa lẹ́bi, àwa ẹni tí Ọlọ́run ti yàn fún ara rẹ̀. Ǹjẹ́ Ọlọ́run yóò dá wa lẹ́bi? Bẹ́ẹ̀ kọ́! Òun ni ẹni tí ó dáríjì wá, tí ó sì fi wá sípò tí ó dára lọ́dọ̀ rẹ̀. 34 (F)Ta ni ẹni náà tí yóò dá wa lẹ́bi? Kò sí. Kristi Jesu tí ó kú, kí a sá à kúkú wí pé tí a ti jí dìde kúrò nínú òkú, ẹni tí ó sì wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, tó sì ń bẹ̀bẹ̀ fún wa? 35 Ta ni yóò ha yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Kristi? Ìpọ́njú ni, tàbí wàhálà tàbí inúnibíni tàbí ìyàn, tàbí ìhòhò, tàbí ewu tàbí idà? 36 (G)Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé:
“Nítorí rẹ̀ ni a ṣe ń pa wá kú ní gbogbo ọjọ́;
À ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.”
37 (H)Ṣùgbọ́n nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí, àwa ju ẹni tí ó ṣẹ́gun lọ nípasẹ̀ Kristi ẹni tí ó fẹ́ wa. 38 Nítorí pé ó dá mi lójú gbangba pé, kì í ṣe ikú tàbí ìyè, kì í ṣe àwọn angẹli tàbí ẹ̀mí èṣù, kì í ṣe ohun ìgbà ìsinsin yìí tàbí ohun tí ó ń bọ̀, tàbí àwọn agbára, 39 tàbí òkè, tàbí ọ̀gbun, tàbí ohunkóhun nínú ìṣẹ̀dá ni yóò le yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó ń bẹ nínú Kristi Jesu, Olúwa wa.
Òwe hóró musitadi àti ìwúkàrà
31 (A)Jesu tún pa òwe mìíràn fún wọn: “Ìjọba ọ̀run dàbí èso hóró musitadi, èyí tí ọkùnrin kan mú tí ó gbìn sínú oko rẹ̀. 32 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ èso tí ó kéré púpọ̀ láàrín èso rẹ̀, síbẹ̀ ó wá di ohun ọ̀gbìn tí ó tóbi jọjọ. Ó sì wá di igi tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì wá, wọ́n sì fi ẹ̀ka rẹ ṣe ibùgbé.”
33 (B)Ó tún pa òwe mìíràn fún wọn: “Ìjọba ọ̀run dàbí ìwúkàrà tí obìnrin kan mú tí ó pò mọ́ ìyẹ̀fun púpọ̀ títí tí gbogbo rẹ fi di wíwú.”
Òwe ìṣúra tí a fi pamọ́ sínú ilẹ̀ àti ohun ẹ̀ṣọ́ olówó iyebíye
44 “Ìjọba ọ̀run sì dàbí ìṣúra kan tí a fi pamọ́ sínú oko. Nígbà tí ọkùnrin kan rí i ó tún fi í pamọ́. Nítorí ayọ̀ rẹ̀, ó ta gbogbo ohun ìní rẹ̀, ó ra oko náà.
45 “Bákan náà ni ìjọba ọ̀run dàbí oníṣòwò kan tí ó ń wá òkúta olówó iyebíye láti rà. 46 Nígbà tí ó rí ọ̀kan tí ó ni iye lórí, ó lọ láti ta gbogbo ohun ìní rẹ̀ láti le rà á.
Òwe ti àwọ̀n ẹja
47 (A)“Bákan náà, a sì tún lè fi ìjọba ọ̀run wé àwọ̀n kan tí a jù sínú odò, ó sì kó onírúurú ẹja. 48 Nígbà tí àwọ̀n náà sì kún, àwọn apẹja fà á sókè sí etí bèbè Òkun, wọ́n jókòó, wọ́n sì ṣa àwọn èyí tí ó dára sínú apẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n da àwọn tí kò dára nù. 49 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò rí ní ìgbẹ̀yìn ayé. Àwọn angẹli yóò wá láti ya àwọn ènìyàn búburú kúrò lára àwọn olódodo. 50 Wọn ó sì ju àwọn ènìyàn búburú sínú iná ìléru náà, ní ibi ti ẹkún àti ìpayínkeke yóò gbé wà.”
51 Jesu bí wọn léèrè pé, “Ǹjẹ́ gbogbo nǹkan wọ̀nyí yé yín.”
Wọ́n dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ó yé wa.”
52 Ó wí fún wọn pé, “Nítorí náà ni olúkúlùkù olùkọ́ òfin tí ó ti di ọmọ-ẹ̀yìn ní ìjọba ọ̀run ṣe dàbí ọkùnrin kan tí í ṣe baálé ilé, tí ó mú ìṣúra tuntun àti èyí tí ó ti gbó jáde láti inú yàrá ìṣúra rẹ̀.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.