Revised Common Lectionary (Complementary)
Àdúrà láti lè pa òfin Olúwa mọ́
129 Òfin rẹ̀ ìyanu ni:
nítorí náà èmi gbà wọ́n gbọ́.
130 Ìṣípayá ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú ìmọ́lẹ̀ wá;
ó fi òye fún àwọn òpè.
131 Èmi ya ẹnu mi mo sì mí hẹlẹ,
nítorí èmi fojú ṣọ́nà sí àṣẹ rẹ.
132 Yí padà sí mi kí o sì ṣàánú fún mi,
bí ìwọ ṣe máa ń ṣe nígbà gbogbo sí àwọn
tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ.
133 Fi ìṣísẹ̀ mi múlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ rẹ,
má ṣe jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ borí mi.
134 Rà mí padà lọ́wọ́ aninilára ènìyàn,
kí èmi lè gbọ́ ẹ̀kọ́ rẹ.
135 Jẹ́ kí ojú rẹ kí ó tàn sí ìránṣẹ́ rẹ lára
kí ó sì kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.
136 Omijé sàn jáde ní ojú mi,
nítorí wọn kò gba pé òfin rẹ̀ jẹ́ òtítọ́.
38 Nígbà náà ni Sadoku àlùfáà, Natani wòlíì, Benaiah ọmọ Jehoiada, àwọn ará Kereti àti Peleti sì sọ̀kalẹ̀ wá wọ́n sì gbé Solomoni gun ìbáaka Dafidi ọba wá sí Gihoni. 39 Sadoku àlùfáà sì mú ìwo òróró láti inú àgọ́, ó sì dà á sí Solomoni lórí. Nígbà náà ni wọ́n sì fọn fèrè, gbogbo àwọn ènìyàn sì ké pé, “Kí Solomoni ọba kí ó pẹ́!” 40 Gbogbo ènìyàn sì gòkè tọ̀ ọ́ lẹ́yìn wọ́n ń fọn ìpè, wọ́n sì ń yọ ayọ̀ ńlá, tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ mì fún ìró wọn.
41 Adonijah àti gbogbo àwọn àlejò tí ó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ gbọ́ ọ́ bí wọ́n ti ń jẹun tán, wọ́n ń gbọ́ ìpè, Joabu sì wí pé, “Kí ní ìtumọ̀ gbogbo ariwo nínú ìlú yìí?”
42 Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Jonatani ọmọ Abiatari àlùfáà sì dé, Adonijah sì wí pé, “Wọlé wá, ọkùnrin yíyẹ ìwọ gbọdọ̀ mú ìròyìn rere wá.”
43 Jonatani sì dáhùn, ó sì wí fún Adonijah pé, “Lóòótọ́ ni olúwa wa Dafidi ọba, fi Solomoni jẹ ọba. 44 Ọba sì ti rán Sadoku àlùfáà, Natani wòlíì, Benaiah ọmọ Jehoiada àti àwọn ará Kereti àti Peleti pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì ti gbé e gun ìbáaka ọba, 45 Sadoku àlùfáà àti Natani wòlíì ti fi òróró yàn án ní ọba ní Gihoni. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti gòkè wá pẹ̀lú ayọ̀, ìlú sì ń hó pẹ̀lú rẹ̀. Èyí ni ariwo tí ẹ̀yin ń gbọ́. 46 Solomoni sì ti jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀. 47 Àwọn ìránṣẹ́ ọba sì ti tún wá láti bá olúwa wa Dafidi ọba yọ̀, wí pé, ‘Kí Ọlọ́run rẹ̀ mú orúkọ Solomoni lókìkí ju tirẹ̀ lọ àti kí ìtẹ́ rẹ̀ kí ó pọ̀ ju tirẹ̀ lọ!’ Ọba sì tẹ ara rẹ̀ ba lórí ibùsùn rẹ̀, 48 ọba sì wí pé, ‘Ògo ni fún Olúwa Ọlọ́run Israẹli, ẹni tí ó ti jẹ́ kí ojú mi rí ẹnìkan tí ó jókòó lórí ìtẹ́ mi lónìí.’ ”
44 (A)“Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí pẹ̀lú wọn ní ijù. Èyí tí a ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó ba Mose sọ̀rọ̀ pé kí ó ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí ó ti rí. 45 (B)Ti àwọn baba wa tí ó tẹ̀lé wọn sí mú bá Joṣua wá sí ilẹ̀ ìní àwọn aláìkọlà, tí Ọlọ́run lè jáde kúrò níwájú àwọn baba wa, títí dí àkókò Dafidi. 46 (C)Ẹni tí ó rí ojúrere níwájú Ọlọ́run, tí ó sì tọrọ láti rí ibùgbé fún Ọlọ́run Jakọbu. 47 (D)Ṣùgbọ́n Solomoni ni ó kọ́ ilé fún un.
48 “Ṣùgbọ́n Ọ̀gá-ògo kì í gbé ilé ti a fi ọwọ́ kọ́: gẹ́gẹ́ bí wòlíì ti wí pé:
49 (E)“ ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,
ayé ni àpótí ìtìsẹ̀ mi.
Irú ilé kín ní ẹ̀yin yóò kọ́ fún mi?
ni Olúwa wí.
Tàbí níbo ni yóò jẹ́ ibi ìsinmi mi?
50 Ọwọ́ mi kò ha ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.’
51 (F)“Ẹ̀yin ọlọ́rùn líle àti aláìkọlà àyà àti etí! Bí àwọn baba yín gẹ́lẹ́ ni ẹ̀yin rí: Nígbà gbogbo ni ẹ̀yin máa ń dènà Ẹ̀mí Mímọ́! 52 Ǹjẹ́ ọ̀kan tilẹ̀ wà nínú àwọn wòlíì tí àwọn baba yín kò ṣe inúnibíni sí? Wọn sì ti pa àwọn ti ó ti ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa wíwá Ẹni Olódodo náà. Nísinsin yìí ẹ̀yin ti dalẹ̀ rẹ̀ ẹ̀yin sí ti pa. 53 Ẹ̀yin tí ó gba òfin, gẹ́gẹ́ bí àwọn angẹli ti fi fún ni, tí ẹ kò sì pa á mọ́.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.